Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 1 nínú 10

Njẹ́ o ti rí ara rẹ gẹ́gẹ́ bí àpò ọ̀rá tí afẹ́fẹ́ ń gbé káàkiri? Mò ń ṣeré ni. Ṣùgbọ́n kí á pa eré tì, n jẹ́ o ti fi ìgbà kan rí ara rẹ gẹ́gẹ́ bí amọ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹsẹ yì? Tí o kàn wà . . . níbẹ̀ ṣá. Láì sí ẹ̀yẹ tàbí ìdí kankan?

Amọ̀ fúnra rẹ̀ kò ní iye kankan lórí—erùpẹ̀ tútù láti ilẹ̀ẹ́lẹ̀ ni. Kò jọ nnkan kan. Kò ní àfiwé kankan. Amọ̀. Mo rò pé gbogbo wa lè ní ìmọ̀lárà báyìí lẹ́ẹ̀kọ̀kan. Ìnira àti àìní ìtẹ̀lọ́rùn bẹ̀rẹ̀ sí rákòrò wọ inú èrò wa nígbà tí a kò bá fi ọkàn sí bí a ṣe ń bá ìgbé ayé wa ojoojúmọ́ lọ ṣíṣe àwárí ààyè wa—à ń tiraka láti bá ẹgbẹ́ pé a sì ń sọ ìwà àti àmúyẹ nù kí á lè ba mọ̀ wá. Àwa ni amọ̀ náà.

Síbẹ̀síbẹ̀, amọ̀kòkò jẹ́ amòye oníṣẹ́ ọnà. Ó ní sùúrù àti ìran láti fi amọ̀ dá ohun kan tí ó lẹ́wà tí ó sì wúlò. Nígbà tí amọ̀kòkò bá jókòó lẹ́hìn kẹ̀kẹ́ rẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ sí mọ nnkan tuntun kan, níbi tí àwa ti rí òkítì erùpẹ̀ tútù, òun rí ohun gbogbo tí yóò fi ṣiṣẹ́. Ó mọ̀ pé nnkan tí ó lẹ́wà máa ti ibẹ̀ jáde, nítorínáà yíò lo àsìkò, yíò tẹ ọwọ́ mọ́ ọ, yíò sì mọ ohun tí ó yàtọ̀ tí ó sì jẹ́ ìyanu.

Kò lè jẹ́ èmi nìkan ni mò ń rò nígbà míràn pé, "Kí ló dé Ọlọ́run? Kí ló dé tí o fi lo àkókò lórí mi nígbà tí mò ń tẹ̀síwájú láti máa dá ẹ̀ṣẹ̀ ti mo sì ń ṣe àìgbọràn?” Síbẹ̀síbẹ̀, Ó ń ṣe è. Ó MỌ àlèébù rẹ. O MỌ ibi tí o ti wà ní àìlera. Ó MỌ̀ ọ́, Ó sì MỌ̀ mí. Nígbà tí ó bá ní ìdààmú, tàbí nígbà tí ǹkan bá le, rán ara rẹ létí pé Òun ni Amọ̀kòkò, Ó ń tẹ ọwọ́ mọ́ ọ fún ìsọdọ̀tun wa, fún ire wa àti fún Ògo Rẹ̀. Nígbà tí a jẹ́ amọ̀ tí kò wúlò, nípasẹ Jésù, Amọ̀kòkò náà mọ wá—ó sì tún ń tẹ̀síwájú láti mọ wá—sí ohun tí ó lẹ́wà! Ó ti pè ọ́ sí nnkan tí ó ga jù ọ́ lọ. Ìwọ kìí ṣe pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ lásán; o jẹ́ amọ̀ ní ọwọ́ Amọ̀kòkò náà.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church