Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 3 nínú 10

Ohun gbogbo tí Ọlọ́run dá—àní ohun gbogbo—ni Ó dá fún ète kan. Iṣẹ́ tí àgbọ́n ń ṣe ni pé kí ó máa mú kí àwọn ohun ọ̀gbìn d'àgbà, kí ó máa mú kí wọ́n pọ̀ sí i, kí ó sì máa mú oúnjẹ wà. Ìdí tí ààrá fi ń sán ni láti yọ́ nitrogen tí kò wúlò nínú omi, èyí tí yíò di ajílẹ̀ tí àwọn ohun ọ̀gbìn lè fà nípasẹ̀ gbòǹgbò wọn. Ohun tí igi aspen wà fún ni láti pèsè ibùgbé fún onírúurú ẹranko inú igbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun gbogbo ní àwọn ète àrà ọ̀tọ̀, gbogbo wọn ní ète kan náà—láti ṣe ohun ńlá fún Ọlọ́run nípa fífi ẹwà àti ògo Rẹ̀ hàn. Ṣùgbọ́n kò sí nǹkan mìíràn lórí ilẹ̀ ayé tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run bíi ìwọ àti èmi. O fi hàn ní ọ̀nà tí ohun mìíràn lórí ilẹ̀ ayé kó leè fi hàn. Kò dà bí àwọn ìràwọ̀, ìwọ àti èmi nìkan ni a lè fi ìdáríjì Rẹ̀ hàn, oore Rẹ̀, àti ìfẹ́ Rẹ̀ sí àwọn tí ó yí wa ká.

Ní ìgbà tí o bá lo àkókò àti agbára rẹ láti ṣe ètò bí àwọn ẹlòmíràn ṣe ń wò ọ, kì í ṣe pé o kàn dá àwòràn ara rẹ tí ó jẹ́ irọ́ àti èyí tí a mọ̀ dáadáa nìkan, ṣùgbọ́n o tún pàdánù ète tí ó tóbi jùlọ tí Ọlọ́run ní fún ọ.

Àwòrán tí o fi ń wo àyíká rẹ kì í ṣe ìdí tí o fi wà lórí ilẹ̀ ayé yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe ìdí tí a fi ń pè ọ́ ní àwọn òkúta olówó iyebíye nínú adé Olúwa (Sekaráyà 9:16). Ní ìgbà tí Ọlọ́run dá àwọn ìràwọ̀ láti máa tàn bí àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí a gbé kalẹ̀ lókè ayé, Ó dá ọ láti fi ìṣúra ọ̀run sí inú ara rẹ. O gbé Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run alààyè nínú ọkàn rẹ. Ìdí pàtàkì rẹ lè jẹ́ láti di agbábọ́ọ̀lù baseball, tàbí ẹni tí ó ń ṣe àwòfín, tàbí ẹni tí ó ń tọ́jú aláìsàn, tàbí ẹni tí ó ń ṣe àwòrán ara ẹni. Àmọ́ ohun tí ó máa jẹ́ àfojúsùn rẹ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Ọlọ́run ni pé kí o máa fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn, kí o sì máa fi ìdáríjì Rẹ̀, oore Rẹ̀, àti inú rere Rẹ̀ hàn sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, ẹgbẹ́ rẹ, kíláàsì rẹ, àti ìdílé rẹ ní ọ̀nà tí ìwọ nìkan lè gbà ṣe é.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church