Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ
Ninu ẹsẹ ìwé yii, Paulu sọ fun wa nipa iru imọ méjì tí ó wà. Ọkàn nínú wọn ni irú ìmọ̀ tí Ọlọ́run ti mọ pẹlu wa; èkejì ni bí a ṣe lè lo ìmọ̀ láti bá ara wa jẹ́ jẹ́ kí ó sì gbé ìgbéraga wọ̀ wa. Eléyìí wáyé nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sì ìjọ Kọ́ríńtì nígbàtí ó ń sọ̀rọ̀ lórí oúnjẹ tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà.
Nínú ẹsẹ iwé yí, Pọ́ọ̀lù sọ fún wa nípa oríṣi ìmọ̀ méjì tí ó wà. Ọ̀kan nínú wọn ni ìmọ̀ eléyìí tí Ọlọ́run mọ pẹ̀lú wa; ọ̀kan tó kù ní bí a ṣe lè lò ìmọ̀ láti bá ara wa Pọ́ọ̀lù kò sọ wípé ó dára tàbí bẹ́ẹ̀ kọ̀, ṣùgbọ́n bóyá ṣíṣe àkóso lórí pípa àṣẹ bí ó ṣe yẹ́ ká jẹ. Àwọn kan nínú ìjọ ní ìmọ̀ tó ( pé) láti lè jẹ́ oúnjẹ tí a fi rúbọ si òrìṣà níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ wípé òrìṣà kò ní agbára kánkán lórí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ìmọ̀ pípé yẹn náà, mú wá yapa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì rú àwọn ènìyàn sókè pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbéraga.
Ẹ jẹ́kí a jọ wo Kọ́ríńtì kíni 8:1-3 láti gbọ ọ̀nà tí ó dára jù láti ẹnu Pọ́ọ̀lù
- Ó wá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí a fi rúbọ fún oriṣa. A mọ̀ pé, “Gbogbo wa ni a ní ìmọ̀,” "Ìmọ̀" eléyìí a máa mú kí eniyan gbéraga, ṣugbọn ìfẹ́ ní ń mú kí eniyan dàgbà.
- Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun mọ nǹkankan, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò tíì ní mọ̀ tó bí ó ti yẹ.
- Ṣugbọn bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn Ọlọrun, òun ni Ọlọrun mọ̀ ní ẹni tirẹ̀.
Pọ́ọ̀lù ń sọ wípé irú ìmọ̀ tí ó mú ìgbéraga àti ìpalára ènìyàn dání kí ì ṣe ìmọ̀ tòótọ́ rara(kò ì tí mọ ohun tí ó yẹ kí o mọ). Ṣùgbọ́n oríṣi ìmọ̀ kejì wá ti o yàtọ̀ sí ti àkọ́kọ́. Ìdáhùn Pọ́ọ̀lù sì ayédèrú ìmọ̀ yí ni ìfẹ́. Ìmọ̀ Ọlọ́run ti a lò lọ́nà tó bójú mú já sí ìfẹ́ fún Ọlọ́run, ati pé eléyìí ṣeé ṣe nítorí pé ó túmọ̀ sí bí a ṣe súnmọ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ sì. Ọlọ́run fẹ́ kí àjọsepọ́ wá pẹ̀lú Òun dá bí ọrẹ kòríkòsùn tí kò sì pé àjọpín àṣírí wa.
Orin Dáfídì 25:14 (ESV) "Àwọn tí ó bá bẹ̀rù OLUWA ni OLUWA ń mú ní ọ̀rẹ́, a sì máa fi majẹmu rẹ̀ hàn WỌ́N"
.Ọ̀rọ̀ yi ni èdè Hébérù tí à ló fún ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ni "Sod" tí ó sọ nípa irú ìmọ̀ràn àtàtà tí ó wà láti ọ̀dọ̀ ọrẹ tímọ́tímọ́ kan sì ìkejì. Bí Ọlọ́run ṣe mọ̀ wá sí nìyẹn. Ó ń bá wa sọ̀rọ̀ láti inú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú tí ó ní àfọkàn-tán àti ìgbẹ́kẹ̀lé.Nítoríná dípò wíwà ìmọ̀ láti jẹ́ gàba lórí àwọn ènìyàn, Ọlọ́run fẹ́ kí a wá ìmọ̀ Òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́. Nígbàtí ó bá ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ó jinlẹ̀ pẹ̀lú ẹnìkan, ìwọ yíò rántí ohun tí wọn sọ, ohun tí wọn fẹ́ràn, ohun tí ó ń mú inú wọn dùn, àti ohun tí ó ń bá wọn lọ́kàn jẹ́. Bí Ó ṣe mọ̀ wá sí nìyẹn nísinsìnyí, àti pé Ó fẹ́ kí a túbọ̀ mò Òun síwájú sí kí a sì súnmọ́ Òun pẹ́típẹ́tí àti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ lójoojúmọ́ nítorípé Òun kò kan fẹ jẹ́ Olùgbàlà, Bàbá, àti olùrànlọ́wọ́ nìkan. Òun pẹ̀lú tun fẹ́ bá wà dọ́rẹ́.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.
More