Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 8 nínú 10

Jeremáyà 12:3a ń ṣe ìbánisọ̀rọ̀ mímọ bí Ọlọ́run ti mọ̀ wá. Ó ń rí wa, a lè bèèrè pé kí ó dán wa wò, a sì lè gbẹ́kẹ̀le nínú ohun tí ó lè ti ibẹ̀ jáde. Lẹ́yìn náà, Orin Dáfídì 139:23-24 ń ṣe àpèjúwe àdúrà ti onkọ̀wé kan fún Ọlọ́run láti MỌ gbogbo wíwà wọn: ọkàn, ẹ̀mí, àti ara.

Àkọ́kọ́, Ó jẹ́ àdúrà láti "mọ ọkàn mi". Ro gbogbo igbà tí ati ṣì ẹ́ gbọ́. O sọ ohun tí a ṣì gbọ́ tàbí o ṣe ohun kan pẹ̀lú èrò rere tí ẹnìkan gbà sí òdì. Nígbà tí Ọlọ́run tí ó mọ ọkàn rẹ bá mọ̀ ọ́, o lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé ní Ìdá ọgọ́rùn-ún pé ó ń rí dídára nínú ohun tí o sọ, ṣe, àti rò, nígbàgbogbo.

Èyí tókàn, Ó jẹ́ àdúrà pé Ọlọ́run yóò "mọ àwọn èrò àníyàn mi" O mo ohun tí mò ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àwọn tí ó tì ẹ́ lójú láti sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Àwọn ènìyàn tí ọ sọ fún bóyá lo tilẹ̀ sọ fún wọn ní TÒÓTỌ́. Jíjẹ́ mímọ̀ fún Ọlọ́run ni kí á ma gbọ́ wa yé. Ó jẹ́ jíjẹ́ àfọwọ́sí. Ó ń ṣe àníyàn nípa ohun tí ìwọ ń ṣe àníyàn rẹ̀, àwọn àníyàn rẹ múná dó ko síi!

Ní àkótán, ó jẹ́ àdúrà pé Ọlọ́run yóò mọ àwọn ìṣe wa, àní àwọn tí a kò lè mú yangàn ("àwọn ọ̀nà ìbàjẹ́ wa", tàbí àwọn ẹ̀ṣè). Ehn, ó ba ni lẹ́rù! Màá ṣe fẹ́ jẹ́ kí Ọlọ́run mọ̀ nípa bí mo ti ṣe sí ọ̀rẹ́ yẹn ní ibi ìjẹun tàbí ní ibi ayẹyẹ tí mo lọ ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá? Ṣé kò ní jẹ́ ohun tí ó kẹ́hìn tí mo fẹ́ kí Ọlọ́run mọ̀ nípa mi?

Ṣùgbọ́n ohun náà rèé: èyí kìí ṣe àdúrà fún Ọlọ́run láti dá ẹjọ́ àwọn ohun tí ó burújù tí o ti ṣe. Ó jẹ́ àdúrà pé Ọlọ́run á mọ ohun tí ó kéré jù nípaà rẹ: èyí tí ó dára, èyí tí ó burú, èyí tí kò bójúmu rárá. Síbẹ̀, kí Ọlọ́run mọ̀ ọ́ kìí sẹ ìdẹ́rùbani! Ka ilà tí ó kẹ́hìn yẹn ní ẹ̀kan si. Kíló dé tí afi ń yin Ọlọ́run pé ó mọ ohun tí ó kéré jù nípa wa? Nítoríwípé nígbàtí Ọlọ́run bá mọ̀ wá, Ó lè darí wa.

Àtiwípé níbo ni ó ń mú wa lọ? Ọ̀nà ayérayé—Nígbàtí Ọlọ́run bá mọ̀ wá, a máa darí wa sí ìgbé ayé tí ó dára, ìgbé ayé tí ó kún, ayé àínípẹ̀kun. Èyí ni ìtunmọ́ kí á jẹ́ mímọ̀ fún Olorun tí ó fẹ́ràn rẹ ju bí ó ti lè yé ọ lọ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 7Ọjọ́ 9

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church