Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 4 nínú 10

Ǹkankan nù nínú ìṣẹ̀dá kí a tó dá ọ. Àìmọ̀ ẹ́ ka Ọlọ́run láyà tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi wá padà dá ọ sáyé! Tẹ̀ù-tẹ̀rù tìyanu-tìyanu ni Ó fi dá ọ. Tẹ̀ù-tẹ̀rù bíi òbí tó ń rán ọmọ rẹ̀ lọ sínú ayé, àti tìyanu-tìyanu pẹ̀lú ìmọ̀ wípé ìṣẹ̀dá tí ó lẹ́wà ni Òhun gbé sí inú rẹ. 

Ó dá ọ fún ìdí tó dára àti èyí tó ní ìmúṣẹ. Éfésù 2:10 sọ ọ́ báyìí “‭Nítorí àwa ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ tí a ti dá nínú Kristi Jesu fún àwọn iṣẹ́ rere, èyí tí Ọlọ́run ti pèsè tẹ́lẹ̀, fún wa láti ṣe.” #Wobí! Nínú ìtumọ̀ Bíbélì míràn, dípò “iṣẹ́ ọwọ́”, ọ̀rọ̀ náà “iṣẹ́ àkànṣe ńlá” ni wọ́n lò. Iṣẹ́ àkànṣe ńlá kìí ní àbùkù. Bí Ó ṣe fẹ́ kí o rí gẹ́lẹ́ lo rí. Kìkìdá ǹkan tí Ó fẹ́ láti ọ̀dọ̀ rẹ ni fún ọ láti fà súnmọ́ ọ, Òhun pẹ̀lú yò sì fà súnmọ́ ẹ. Nígbà tí a bá ń ronú nípa wíwà nínú ìbáṣepò, bákan méjì ni. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ló ti rí pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó ti mọ̀ wá tipẹ́ kí a tó ní ìmọ̀lára nípa ìwàláàyè Rẹ̀, ní báyìí Ó wá fẹ́ kí o fà súnmọ́ Òhun—láti mọ̀ si nípa Rẹ̀. Bí o bá ṣe súnmọ́ Ọ sí, ni ó máa dígbà bí o ti máa mọ̀ Ọ́ sí. Bí ìwọ sì ti ń mọ̀ Ọlọ́run sí, ni o ma ṣe àwárí ara à rẹ sí—ìwọ iṣẹ́ àkànṣe ńlá.

Ìgbàkugbà ti ọkàn rẹ bá fà sẹ́yìn, tí ó bá dàbí wípé a ti dá ọ dáa, tí èrèdí ìwàláàyè rẹ kò yé ọ mọ́, tí o kò tilẹ̀ ní ìdánilójú nípa ìdánimọ̀ rẹ, tàbí tí a kò mọ rírì ǹkan tí ò ń ṣe, ṣáà rántí wípé iṣẹ́ àkànṣe ńlá Rẹ̀ ni ìwọ í ṣe. Ènìyàn tí Ọlọ́run mọ̀, tí a fẹ́ràn, tí kò sì ṣe àìní ohun kan ni ìwọ í ṣe. Ǹkankan ma nù nínú ìṣẹ̀dá kání a kò dá ọ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 3Ọjọ́ 5

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church