Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 6 nínú 10

Ǹjẹ́ ẹnìkan tó ṣe pàtàkì sí ẹ ti rántí orúkọ rẹ rí níbi tí ẹ ti ń tàkùrọ̀sọ? Bóyá ọ̀rẹ́ titun kan ni, ẹni tí ma ń dá ọ lòún ní Starbucks, tàbí ẹni tí o fẹ́ràn ní ìkọ̀kọ̀ ní ilé ìwé rẹ. Ǹjẹ́ o rántí bí inú rẹ ti dùn sí nígbà tí o ríi dájú wípé wọ́n rántí orúkọ rẹ ní àkókò náà? Ǹjẹ́ o rántí bí ó ti dùn mọ́ọ tó láti gbọ́ ohùn ẹni tí ó bu ọlá fún bí wọ́n ti ń pe orúkọ rẹ, wípé wọn rántí, wọ́n kà ọ́ sí, àbí wípé wọ́n sọ̀rọ̀ ìwúrí sí ọ? Ó máa mú ọ rí ara rẹ̀ bí ènìyàn pàtàkì àti gbajúmọ̀. 

Bí àwọn ẹsẹ̀ Bíbélì wọ̀nyí nínú Jòhánù 10 ti rí. Jésù ń sọ fún wa wípé tí a bá fi ara wa fún Un tí a sì tẹ́tí sí ohùn Rẹ̀ wípé òhun yóò mọ̀ wá. Gbàá rò wípé Olùgbàlà gbogbo àgbáyé dá ohùn rẹ mọ̀! 

Kí ẹnìkan tó lè dá ohùn rẹ mọ̀, o ní láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú wọn. Gbàá rò báyìí; tí o bá gba ohùn tí àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ àti mọ̀lẹ́bí rẹ ká sílẹ̀, tí a sì wá ní kí o dá ohùn ẹnì kààkan mọ̀, ǹjẹ́ o ma lè ṣeé? Ó dá mi lójú wípé púpọ̀ nínú wọn ni o ma lè dámọ́. Kí ni ìdí? Nítorí ìgbà dé ìgbà, lójojúmọ́ ni o má ń bá wọn sọ̀rọ̀! Bákan náà ló ti rí pẹ̀lú Jésù; bí àkókò tí à ń lò pẹ̀lú Rẹ̀ bá ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò ti rọrùn fún wa tó láti dá ohùn Rẹ̀ mọ̀! Mo gbọ́ ọ̀rọ̀ kan nígbà kan tó mú àyípadà ńlá dé bá bí mo ti ń ronú nípa ohùn Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ náà sọ wípé: “O kò lè ṣe àròyé wípé o kò gbọ́ ohùn Ọlọ́run tí o bá jìnà sí Bíbélì rẹ.” YEEEEPA! Gbólóhùn yẹn wọ̀ mí ní akinyemi ara nígbà àkọ́kọ́ tí mo gbọ́ ọ. Báwo ni a ṣe fẹ́ gbọ́ ohùn Ọlọ́run tí a kò bá sí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí a kò bá ka ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti tí a kò bá wá àyè láti gbàdúrà àti jọ́sìn síi? A kò lè gbọ́ ọ, a ò sì lè gbọ́ ọ! 

Ìròyìn rere tó wà níbẹ̀ ni wípé Ọlọ́run fẹ́ mọ̀ ọ́! Ó fẹ́ mọ ohùn rẹ; Ó fẹ́ wà lára àwọn tí ò ń bá kọ́wọ̀ọ́ rìn. Ó fẹ́ kí o di ti òhun láì fi ǹkankan sílẹ̀—kìíṣe àwọn ibi tó rẹwà nìkan—gbogbo rẹ̀ ló fẹ́!

Jésù fẹ́ kí o mọ ohùn tí òhun ti dá sí inú rẹ, àmọ́ láti jẹ àǹfààní ohùn tó ma tọ́ ipasẹ̀ ìṣẹ̀dá rẹ o ní láti kọ́kọ́ mọ ohùn Rẹ̀. Di àgùntàn, kí o sì tẹ́lẹ̀ Olùṣọ́-àgùntàn rẹ. Tẹ̀lé Jésù, o kò sì ní fi ìgbà kankan mọ bí ó ti rí lára láti lọ sí ibi kan láìsí ẹnì kan ṣoṣo tí ó mọ ohùn rẹ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church