Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 7 nínú 10

Ẹlẹ́dàá mọ ohun tó dá. Tí ó o bá fi àyè silẹ láti wo òdòdó kan, pàápàá èyíkéyìí, wàá rí i pé a fi ara balẹ̀ kíyè sí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àti ẹwà rẹ̀. Mo pè yín níjà nísinsìnyí láti jáde lọ wo oríṣiríṣi òdòdó, tàbí ó kéré tán ṣe ìwádìí lórí Google. Ìyanu gbáà ló jẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?! Nígbà tí Ọlọ́run ń ṣàkọsílẹ̀ ìṣẹ̀dá, Ọlọ́run mọ̀ pé àwọn òdòdó ṣe pàtàkì láti fi ṣe oko lọ́ṣọ̀ọ́—kì í ṣe ohun tí Ó rò nígbẹ̀yìn wá. A lè mọ̀ pé Ọlọ́run bìkítà fún wa nípa wíwo àwọn àlàyé fínnífínní tó wà nínú àwọn òdòdó. 

Ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni pé Jésù ń bá ọ sọ̀rọ̀, ó sì fẹ́ kí ọkàn rẹ tó ń dààmú balẹ̀. Ó ń sọ fún ọ pé bí Ọlọ́run bá ṣe àfiyèsí bẹ́ẹ̀ sí àwọn òdòdó inú igbó, tí wọn kì í ṣe ìpẹ̀kun ìṣẹ̀dá Rẹ̀ (ìránnilétí, bí o bá gbàgbé: ÌWỌ ni ìpẹ̀kun yẹn), ṣé o ò rò pé Òun kì yóò bójú tó ọ, fi ọ yangàn, tàbí ṣe ohun tó dára jù lọ fún ọ? Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ ẹ́ dáadáa, ọkàn rẹ̀ sì wà FÚN ọ. 

Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, o ní láti ṣaápọn láti má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù, àníyàn, àti iyèméjì wọlé wá. Níní ìgbàgbọ́ díẹ̀ wípé Ọlọ́run yóò jẹ́ olóòótọ́ sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kìí ṣe ìṣòro kékeré! Ṣé ẹnikẹ́ni kọ àh bí ẹ ṣe ń kà á ọ̀rọ̀ yen? Mo mọ̀ pé mo ṣe bẹ́ẹ̀. Ìgbàgbọ́ tí kò tó nǹkan jẹ́ àrífín sí Ọlọ́run, ó sì ń mú kí ìbẹ̀rù rẹ pọ̀ sí i. O ní láti gbé ìgbésẹ̀ láti sinmi nínú ìlérí tí Jésù fún ọ. Máa padà sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti àwọn ìgbà tí o ti rí ìdúróṣinṣin Rẹ̀ tí a fi hàn. Máa rìn nínú ìdánilójú pé a dá ọ pẹ̀lú ète, a mọ ọ dáadáa, a sì bìkítà fún ọ gidigidi. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 6Ọjọ́ 8

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church