Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 10 nínú 10

Ẹ̀YIN jẹ́ ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́. Àyọkà yìí mú kó ṣe kedere pé kò sí iyèméjì kankan nípa irú ẹni tí ìwọ jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi. A ti yà yín sọ́tọ̀! “Nígbà kan rí ẹ kì í ṣe ènìyàn, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ẹ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run. Nígbà kan rí ẹ kò rí àánú gbà, nísinsin yìí ẹ ti rí àánú gbà.” Nígbà kan rí o ti di afọ́jú, nísinsin yìí o ríran, ọpẹ́lọpẹ́ ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu rẹ̀. 

Ṣùgbọ́n kì í ṣe orúkọ nìkan ni a pè yín láti fi yà yín sọ́tọ̀. Má ṣe dúró síbẹ̀! Bí Ọlọ́run ṣe yà wá sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ máa ń ní àwọn ohun tá a máa ṣe. A pè ọ láti yẹra fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara— àwọn nǹkan ayé yìí tí o mọ̀ pé kò tọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n dùn mọ́— ọ ní àkókò yìí nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí ń bá ọkàn rẹ jagun. Nitorina igbagbogbo o jẹ awọn nkan wọnyẹn ti o n wa lati ṣalaye ọ ati ki o ṣe iyatọ laarin ẹni ti o jẹ gaan (ọmọkunrin ati ọmọbinrin Ọlọrun) ati sọ fun ọ pe o jẹ nkan ti o le fun ọ ni akoko kan ti ifọwọsi ṣugbọn a rii ni igba pipẹ lati jẹ awọn idanimọ iho nikan. Iṣẹ́ tó ju ìyẹn lọ ni Ọlọ́run ní kó o ṣe. Má ṣe fi àǹfààní tó o ní láti jẹ́ àlùfáà aládé du ara rẹ nítorí ohun tí kò ní pẹ́ dópin. 

Èmi àti ìwọ ni a pè láti máa gbé ìgbé ayé rere gẹ́gẹ́ bí ọmọlẹ́yìn Kristi—kì í ṣe kí àwọn ènìyàn lè rí ọ kí wọ́n sì rò pé o jẹ́ òmùgọ̀. ṣùgbọ́n kí wọ́n lè rí irú ẹni tí ọlọ́run jẹ́ nípasẹ̀ rẹ—nípasẹ̀ àwọn ìṣe rẹ, ọ̀rọ̀ rẹ, àti ọ̀nà tí o gbà ń hùwà, kì í ṣe nínú ìgbéraga, bí kò ṣe nínú ìrẹ̀lẹ̀. 

Torí náà, bó o bá ń jáde nílé lónìí, máa rántí ẹni tó o jẹ́. Nígbà tó o bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ, rántí ẹni tó o jẹ́. Ẹ̀yin ni ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹ̀yin ni ẹ̀yà àlùfáà ọba, ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè mímọ́—ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn fún ìní tirẹ̀. Láti inú irú ẹni bẹ́ẹ̀, ni kì o máa gbé. Fi àwọn èèyàn hàn án. Sọ ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ àti ohun tí Ó ti ṣe nínú ìgbésí ayé rẹ. Kí ẹ sì máa wò ó bí ó ti ń sọ yín di ẹni tí ó pè yín láti jẹ́. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 9

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church