Mọ: Ojọ́ Mẹ́wàá láti Mọ Ẹni Tí O Jẹ́Àpẹrẹ

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ọjọ́ 2 nínú 10

Ǹjẹ́ o ti wà nínú ìbẹ̀rù-bojo rí? Ǹjẹ́ o tilẹ̀ ní ìmọ̀lára pé ìwọ kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé kánkán? Ṣé o ní ìmọ̀lára pé tí o bá ṣiṣẹ́ takuntakun tó ìwọ yíò dà bíi enìkejì rẹ? Ṣé o rò pé tí o bá ní ọ̀rẹ́bìrìn tí ó rẹwà, ìwọ yíò bá ẹgbẹ́ pé? Ǹjẹ́ o ti rò ó rí pé bí o bá kàn lè tẹ̀lé àṣà tuntun kan, ní ìgbà náà bóyá ìwọ yíò ní ìgboyà nínú ara rẹ. Fún ìdí kan tàbí òmíràn, ó dà bíi pé o kò ní ìgboyà kò sí bí ìgbìyànjú rẹ ṣe tó.

Ẹsẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ Orin Dáfídì 23 sọ fún wa pé "Olúwa ni olùṣọ́-àgùntàn mi." Nínú àwọn ọ̀rọ̀ márùn-ún wọ̀nyẹn, ó lè ṣe àwárí ìdánimọ̀ àti ìgboyà fún ìdí ìsẹ̀dá rẹ. Àṣà òde òní lè fi mú ọ rò pé o nílò láti ṣe ẹ̀dá ìdánimọ̀ ara rẹ kí o sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara rẹ gbé ìgbésí ayé rẹ. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, a dá wa láti ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ kíkún nínú Ọlọ́run àti láti máa wo ojú Rẹ̀ fún ìgboyà, ìdí tí a fi wá, àti ìdánimọ̀.

Tí o bá ṣe àyẹ̀wò ohun tí ìgbẹ́kẹ̀lé túmọ̀ sí lórí ifá òyìnbó, ìyẹn Google, ìwọ yíò rí i pé ó túmọ̀ sí "láti ní ìmọ̀lára pé ẹnìkan lè fi ọkàn tán-ni àti kí ó ní ìgbàgbọ́ tí ó dúró ṣinṣin nínú ẹnìkan tàbí ń kankan." Dé ibi pé ìwọ yíò ní òye òtítọ́ yen, àti pé ìwọ yíò sì gbàgbọ́ pé "ẹnìkan náà tàbí nkankan náà" ni Jésù, ìwọ yíò sì lè rìn nínú ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún, ìfọkàntán, àti gbígbé gbogbo ara lè È, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Ó mọ̀ ọ́, Ó sì mọ àwọn àìní rẹ, ohun tí o nífẹ̀ sí, àti ohun tí ó wà nínú ọkàn rẹ pàápàá.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ni o lè rìn ní ìrètí pé ọ̀kan nínú wọn yíò mú ìgbẹ́kẹ̀lé, ayọ̀, tàbí ìdí tí o fi wà fún ọ. Ṣùgbọ́n ẹwà tí ó wà nínú títẹ̀lé Jésù ni wípé tí ìwọ bá ń wo Òun nìkan, o ti wà ní ọ̀nà tí ó tọ́. Àwọn àkókò kan sì lè wá tí ó ṣ'ókùnkùn sí wa, àti àwọn ọjọ́ tí ìyọlẹ́nu lè pọ̀ ju bí ó ti yẹ, ṣùgbọ́n ní àkókò wọ̀nyẹn ìwọ yíò ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run pé ní ọ̀nà Rẹ̀, yíò tọ́jú rẹ, yíò ní ìfẹ́ rẹ, o sì ní ìdí ìwàláàyè, gẹ́gẹ́ bí o ti rí.

Ọlọ́run tí Ó mọ̀ ọ́, tí Ó mọ ohun tí ó nílò, tí Ó sì jẹ́ Ẹníkan náà tí o lè gbẹ́kẹ̀lé ni ó dá ọ.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

Known: 10 Days to Discovering Your Identity

Ó lè rọrùn láti ṣìnà nínú ohun táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí, kó o sì pàdánù ẹni táwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tó pọ̀ nípa irú ẹni tó o jẹ́ àti irú ẹni tí Ọlọ́run dá ẹ láti jẹ́. Ìfọkànsìn ọlọ́jọ́ mẹ́wàá yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rìnrìn àjò lọ síbi tí wàá ti mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an.

More

A fẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Fresh Life.Church (Levi Lusko) fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé díẹ sí, jọwọ lọ sí: http://freshlife.church