Jer 18:1-6

Jer 18:1-6 YBCV

Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ̀ Oluwa wipe, Dide, sọkalẹ lọ si ile amọkoko, nibẹ li emi o mu ọ gbọ́ ọ̀rọ mi. Mo si sọkalẹ lọ si ile amọkoko, sa wò o, o mọ iṣẹ kan lori kẹ̀kẹ. Ati ohun-èlo, ti o fi amọ mọ, si bajẹ lọwọ amọkoko na: nigbana ni o si mọ ohun-elo miran, bi o ti ri li oju amọkoko lati mọ ọ. Ọrọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, Ẹnyin ile Israeli, emi kò ha le fi nyin ṣe gẹgẹ bi amọkoko yi ti ṣe, li Oluwa wi: sa wò o, gẹgẹ bi amọ̀ li ọwọ amọkoko, bẹ̃ni ẹnyin wà li ọwọ mi, ile Israeli.