Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ Ayé
À ń bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yí nípasẹ̀ dída t'ọwọ́ wa sílẹ̀. Bíbélì sọ fún wa wípé, gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́yìn Kristi, àwọn tí a ti fi ẹ̀jẹ̀ Jésù rà, tí a ti fi Ẹ̀mí náà kún inú wọn, wípé a kò gbúdọ̀ fẹ́ràn àwọn afẹ́ ayé yìí. Mo mọ̀ wípé èyí yàtọ̀ gedegbe sí púpọ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí à ń gbọ́ lónìí, àmọ́ a gbọ́dọ̀ mọ̀ wípé, gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́yìn Kristi, a ní láti ṣé ara wa, kí a gbé àgbélébùú wa, kí a sì máa tẹle Jésù.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa ní Róòmù 12 wípé a kò gbọ́dọ̀ da ara wa pọ̀ mọ́ ayé yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí a para dà, kí ọkàn wa di titun, kí á lè mòye ohun tí ó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó dára, tí ó yẹ, tí ó sì pé. Ọ̀rọ̀ yí, ìsọdọ̀tun, jẹyọ látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì, anakainosis, èyí tó túmọ̀ sí ṣíṣe àtúnṣe. Tí a bá ma wòó báyìí, ó túmọ̀ sí wípé a gbọ́dọ̀ da gbogbo ọ̀nà tí a ń gbà ronú, hùwà, gbé ìgbésí ayé wa ní àtijọ́ nù, kí a wá bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ́pò ǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ǹkan ti Ọlọ́run.
Nínú Jòhánù Kínní 2:15-20, ó kì wá nílọ̀ nípa àwọn tó wonkoko mọ́ ayé yìí, ǹkan tí èyí ma dá sílẹ̀, àti ìtumọ̀ ìkìlọ̀ náà. Ó ní tí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé yìí, ìfẹ́ Baba kò sí nínú rẹ̀. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìmúlẹ̀mófo ayé yìí àti àwọn afẹ́ inú rẹ̀. Àmọ́ àwọn tó bá ńṣe ìfẹ́ Ọlọ́run yóò wà títí láé.
Bí a ti ń bẹ̀rẹ̀ ètò ọlọ́jọ́ mọ́kànlélógún yìí, a gbọ́dọ̀ tiraka láti já ara gbà kúrò lọ́wọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé yìí. A kò lè sin ọ̀gá méjì – a gbọ́dọ̀ yàn láàárín Ọlọ́run àti ayé yìí. Lọ́gán tí a bá yan Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ yàgò fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó sì lè fara ṣoko sínú ọkàn wa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More