Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Ìgbéraga
A ti ṣẹ́ de ọjọ́ karùn-ún ti a tí jẹ́ òfìfo fún ará wà. Èyí kò rọrùn!
Ìgbà mélòó ni Ọlọ́run ti béèrè fún wa láti ṣe ohùn kan, tí a kò síi ṣé e, tàbí a ti ṣé e ní ààbò? Èyí ni ìgbéraga. Èyí ni a n sọ pé, "Ẹ̀mí ni Ọlọ́run, àti pé Mo mọ ohun tí ó dára jù lọ fún mi ní ipò yii."
Ìgbéraga ń lọ káàkiri ní ayé òde òní. Ìgbéraga ni ọlá ti ara ẹni, Ìgbéraga ni owó tí ó wọlé, Ìgbéraga ni agbára, Ìgbéraga nínú ẹbí, àti púpọ̀ diẹ sii. Ìgbéraga yíì ń yí wa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti pé ó mú gbé ojú lórí ara wa àti ohun tí a le ṣe.
Nínú James 4:6-8, James sọ pé Ọlọ́run lòdì sí àwọn agbéraga, ó sì ń fi ojú rere hàn sí àwọn onírẹ̀lẹ̀. A nílò láti rẹ ara wa sílẹ̀ ní ojú Olúwa láti gba ojú rere Rẹ̀. Nígbà tí a bá mọ̀ pé gbogbo ohun tí a ní àti gbogbo ohun tí a ti ṣe jẹ́ ìbùkún láti ọdọ Olúwa, a kò ní ààyè fún ìgbéraga.
Proverb 16:18 fi kún ewu ìgbéraga nípa sísọ pé ó jẹ́ ohun àkọ́kọ́ sí ìparun. Ìgbéraga ń yọrí sí ìparun! Bí a bá mọ̀ pé òótọ́ ni èyí, èé ṣe tí a fi ń bá a lọ láti máa gbéra ga lórí àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa?
Láti gbé ìgbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀, a gbọ́dọ̀ mú ara wa kúrò nínú ìgbéraga. Tí a bá fẹ́ kí a kún fún Ẹ̀mí, kò sí àyè fun. Gbàdúrà kí o sì béèrè lọwọ Olùwà láti ṣàfihàn ìgbéraga èyíkéyìí tí ó fara pamọ nínú ìgbésí ayé rẹ kí o le tẹ́le ni ẹkùn réré.
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More