Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Àìní Ìdáríjì
Ìwà ọ̀dájú ni àìlèdáríjini. Ó nííṣe pẹ̀lú ǹkan ti ẹ̀mí, ìmọ̀lára, a sì máa pa ẹran ara lára pẹ̀lú. A máa gbà yóò sì máa gbà si, láì fún ni ní ohunkóhun ní ìrọ́po. Ní àfikún, a ríi nínú Ìwé Mímọ́ wípé ìdáríjì tí a rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run dá lórí ìpinnu láti dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. Ayérayé, àní párádísè àti ọ̀run-àpáàdì ló wà nínú òṣùwọ̀n tó rọ́pò bí a ti ṣetán sí láti dárí jì. Àyànmọ́ ọkàn wa dá lórí ìpinnu wa láti dárí jì, tàbí ṣe àìdáríjì, ọmọlàkejì wa.
Mátíù 6:14-15 ṣàlàyé ìlànà yí lọ́nà tó yé'ni. Nígbàtí a bá dárí ji àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó ti ṣẹ̀ wá, Ọlọ́run ma dárí ji àwa náà pẹ̀lú. Àmọ́ bí àwa kò bá dárí jì, Ọlọ́run kò ní dárí jì wá.
Éfésù 4:32 tẹ̀síwájú láti sọ wípé a ní láti ṣe àfihàn ìdáríjì tí Kristi ti kọ́kọ́ fihàn sí wa. A nílò láti fi àánú hàn sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. Èé ṣe tí a kò fi ní ṣe èyí? A kò yẹ fún ìdáríjì tí Ọlọ́run fi hàn sí wa. Èé ṣe tí a fi máa sọ wípé ẹlòmíràn kò yẹ fún ìdáríjì látọ̀dọ̀ wa.
Jẹ́kí èyí yé ẹ: a kò dárí ji ẹnikẹ́ni nítorí tiwọn. Fún àǹfààní ara wa ni a ṣe ń dárí jì wọ́n. Àìlèdáríji ẹnìkan kò leè dè wọ́n mọ́lẹ̀. Dípò èyí, àwa ni àìní ìdáríjì máa dè wá bí ẹ̀wọ̀n. Ó ní òmìnira tó máa ń wọlé tọ̀wá nígbà tí a bá dárí jì. Bí a ti ń gbàdúrà lónìí, àwọn ẹ̀wọ̀n yóò máa já kúrò lára wa. Bí àwọn ènìyàn tilẹ̀ kọ̀ láti dárí jì wá, ìyẹn kò já mọ́ ǹkankan. A máa di òmìnira. A sì máa mú wa bọ̀ sípò pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More