Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 11 nínú 21

Bí Ìfẹ́ Tí Mo Ní fún Ọlọ́run Ṣe Máa Pọ̀ Síi

Nínú Lúùkù 10:25-37, Jésù sọ̀rọ̀ lórí kókó méjì. Kì í ṣe pé ó kàn gbé gbogbo òfin àti àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ nǹkan méjì, Kí ìwọ sì fi gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, àti gbogbo èrò inú rẹ, fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì fẹ́ràn aládùúgbò rẹ bí ara rẹ., ó tún so ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti ìfẹ́ fún àwọn èèyàn pọ̀. Jésù sọ ohun tí Bíbélì ti ń sọ fún wa látọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn fún ẹni tó béèrè ìbéèrè náà pé: bá a bá ṣe túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ náà la ó ṣe túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó. Bá a bá ṣe ń fi àánú hàn sí àwọn èèyàn tó, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó. A kò lè kún fún Èmí Mímọ́ kí a má sì máa rìn nínú ìfẹ́.

Bí a bá kórìíra àwọn ènìyàn nítorí ìran wọn, ẹ̀yà wọn, ohun tí wọ́n ti ṣe sí wa, tàbí ohun tí wọ́n ti sọ nípa wa, Bíbélì sọ fún wa pé apànìyàn ni wá. A mọ̀ pé àwọn apànìyàn kò ní àyè kankan nínú Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá fẹ́ máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú Ẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ máa rìn nínú ìfẹ́. Rántí, gbogbo àwọn òfin ni ó dá lórí ìfẹ́.

Ẹ jẹ́ ká tún wo 1 Jòhánù 2:15-17, tá a ti kà ṣáájú nínú ìwé yìí. Ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ayé. Ṣ'àkíyèsí pé àwọn ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó wà. Ẹsẹ̀ Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ ayé àti adùn ayé tó ń kọjá lọ kò nífẹ̀ẹ́ Baba.

Níkẹyìn, a kọ Jòhánù 14:21 láti kọ́ wa bí a ṣe lè fi ìfẹ́ wa hàn sí Ọlọ́run – nípa pípa àwọn àṣẹ Rẹ̀ mọ́. Tí a bá ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, ńṣe là ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún-Un, a bẹ̀rù Rẹ̀, a sì nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọsìn ṣe pàtàkì, síbẹ̀ níní ìfẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kọjá kí éèyàn kàn máa yin orúkọ Rẹ̀ ní òwúrọ̀ ọjọ́ ìsinmi. A gbọ́dọ̀ máa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́, kí a máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun t'Ó nífẹ̀ẹ́, kí a sì máa fi ìfẹ́ hàn sí ara wa.

Day 10Day 12

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/