Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 14 nínú 21

Níní Ìrírí Ìwàláàyè Ọlọ́run Pẹ̀lú Wa

Bí a ti ń parí ọ̀sẹ̀ kejì nínú ètò kíkà yí, ẹ jẹ́ ká fi níní ìrírí ìwàláàyè Ọlọ́run ṣe àfojúsùn.

Nígbà tí a bá ṣe ìpòǹgbẹ fún ìwàláàyè Ọlọ́run ju ohunkóhun lọ, ju ilé titun, ìgbéga, ọlá, tàbí ọkọ̀ titun, Òun tìkára Rẹ̀ ma wá ṣú yọ níbi gbogbo tí a ti ńṣe àwárí Rẹ̀.

A ti pè wá láti fi wíwá ìwàláàyè Ọlọ́run sí ìṣe. A ti pàdánù ojúṣe yìí nínú ìjọ lónìí. Ọ̀pọ̀ ni kò tilẹ̀ mọ bí a ti ń ní ìrírí ìwàláàyè Ọlọ́run, nítorí wọn kò mọ ohun tó jẹ́. Nínú àwọn ètò ìjọsìn wa, ìdíwọ̀n ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ìsìn ló ń darí wa lóde òní tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí a kì í fi àkókò sílẹ̀ mọ́ fún Ọlọ́run láti fi ìwàláàyè rẹ̀ hàn láàárín wa. Ọlọ́run kìí ṣú yọ nípasẹ̀ àwọn ètò àti ìlànà wa.

Ẹ jẹ́kí á padà lọ sí Jòhánù 14:21. Ní ẹsẹ̀ Bíbélì yí, Jésù sọ wípé ẹni tó fẹ́ràn Òhun ni Òhun (Jésù) àti Baba yóò fẹ́ràn bẹ́ẹ̀ni àwọn méjèèjì yóò farahan irúfẹ́ ènìyàn bẹ́ẹ̀!

Nínú Ẹ́kísódù 33:1-3 àti 12-16, Ọlọ́run fún Mósè ní ìtọ́ni bí yóò ti dárí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nígbàkúùgbà tí Mósè bá ríi wípé òun kò gbé ìwọ̀n tí ó sì sọ fún Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò wá fèsì wípé Òun yóò rán ìwàláàyè Rẹ̀ láti darí wọn. Bíi òpó òfurufú ni ìwàláàyè Ọlọ́run ṣe rí nínú Májẹ̀mú Láéláé èyí tí ń darí wọn lọ́sàn-án àti lóru, ní báyìí ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ ni Ó fi ń fara hàn sí wa. Nípasẹ̀ ìrúbọ Kristi àti nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí ń gbé inú wa, Ó lè fara Rẹ̀ hàn nínú wa báyìí.

A nílò ìfarahàn ìwàláàyè Ọlọ́run ní ojú méjèèjì. Tó bá jẹ́ wípé ìlérí nìkan ló kù wá kù, àwa ti pàdánù ǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kò yẹ kí òpin ọjọ́ kan mú ìtẹ́lọ́rùn wá láìṣe pé a ní ìrírí ìwàláàyè Ọlọ́run nínú rẹ̀. Ìtẹ́lọ́rùn wa kò gbúdọ̀ dá lóríi ìjọsìn inú ìjọ, ìpàdé àdúrà, tàbí àwọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ mìíràn láìsí ìfarahàn ìwàláàyè Ọlọ́run. Ìwàláàyè Rẹ̀ yí ni yóò mú wa dá yàtọ̀. Jésù sọ pé bí àwa bá ní ìfẹ́ Rẹ̀ tí a sì ń pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, Òun yóò farahàn sí wa. Ohun tí a dá wa fún nìyí.

Ọjọ́ 13Ọjọ́ 15

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/