Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Iná Ọ̀tun
Láì bìkítà onírúurú ìjọ, ìrìbọmi ti Ẹ̀mí Mímọ́ wà fún gbogbo àwọn onìgbàgbọ́.
Àti, pẹ̀lúpẹ̀lú, ìrìbọmi s'ínú Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ tìrẹ báyìí. Ó n fẹ́ kí o kún fún iná Rẹ̀. Ó fẹ́ sọ ẹ́ di alágbára nípa sẹ̀ ìwàláàyè Rẹ̀ tí ni ṣ'iṣẹ́ nínú rẹ àti nípasẹ̀ rẹ.
Ṣé o gbàgbọ́ pé Ó fẹ́ fi Ẹ̀mí Rẹ̀ kún ọ? Ṣe o gbàgbọ́ pé Ó fẹ́ làti fi iná titun kún ọ?
Ní inú ìwé Ìṣe Àwọn Àpóstélì 2:1-4, a ríi pé Ẹ̀mí Mímọ́ fi ara Rẹ̀ hàn ní àárín ìjọ bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ ní èdè míràn.
Nínú Ìṣe Àwọn Àpóstélì 4:1-8, a rí Pétérù, mọ́ Jòhánù, tí a fi sẹ́wọ̀n mọ́jú, tí a sì bi l'ẹ́jọ́ níwájú Ánásì, olórí àlùfáà, àti ìdílé rẹ̀. Nígbà tí ó d'ojú kọ ipò ìṣòro yìí, ó sọ pé Pétérù kún fún Èmí Mímọ́!
Ká ní pé Ọlọ́run fẹ́ kún wa fún Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi ògo Rẹ̀ hàn láàárin àwọn àkókò líle wa, ṣùgbọ́n a kò ṣí síi? Kí ni o nílò láti yí padà nínú ìgbésí ayé àti ọkàn rẹ láti ṣí ilẹ̀kùn fún iná titun ti Ẹ̀mí Mímọ́?
Ní Matiu 3: 11-17, ṣáájú kí ó tó sọ ìtàn ti ìrìbọmi Jésù nípasẹ̀ Jòhánù Onítẹ̀bọmi, Jòhánù s'ọ̀rọ̀ nípa ìrìbọmi tí ó lágbára jùlọ. Kì í ṣe ti omi, bí kò ṣe ti iná. Kìí ṣe nípa ọwọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nípa ọwọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́.
Ìgbàgbọ́ kannáà tí ó gbà fún ọ láti di àtúnbí ni ìgbàgbọ́ kannáà tí yóò gbà láti kún ọ fún Ẹ̀mí Mímọ́. Olúwa n fẹ́ láti baptísì rẹ pẹlu Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná Rẹ̀!
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More