Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Àwọn Àlá àti Ìran
Báwo la ṣe lè mọ ohùn Ọlọ́run? Lákọ̀ọ́kọ́ àti jù lọ, ó ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Nígbàkigbà tó bá ń sọ̀rọ̀ lọ́nà èyíkéyìí mìíràn, yóò máa bá Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mu.
Ó ń bá wa sọ̀rọ̀ nínú àdúrà.
Ó ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn onígbàgbọ́ mìíràn, àwọn aṣáájú wa, àti àwọn wòlíì.
Ó ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ìran àti àlá.
Nínú ìwé Jóéèlì 2:28-29, láàárín àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa Ọjọ́ Olúwa, ó kọ nípa ìtàjáde Ẹ̀mí Mímọ́ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ó sọ pé "àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọn yóò sọ tẹ́lẹ̀, àwọn arúgbó wọn yóò lá àlá, àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn yóò sì rí ìran.”
A lè má mọ ìgbà tí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yóò wáyé, ṣùgbọ́n mímọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ó yẹ kí a wà ní ìmúrasílẹ̀ láti ní ìrírí àwọn àlá àti ìran wọ̀nyí kí a sì fetí sí wọn nígbà tí wọ́n bá wáyé.
Nínú Númérì 12:6, a rí i pé Olúwa fìdí òtítọ́ àwọn àlá àti ìran tí àwọn wolii tí ó rán jáde ní múlẹ̀.
Nígbà tí a bá lá àlá tàbí tí a rí ìran kan, ohun àkọ́kọ́ tí a ní láti ṣe ni pé ká béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Ṣé èyí wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ? ”Nígbà tí a bá ti pinnu nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ àti wíwà níhìn-ín Rẹ̀ tí a fi hàn pé ó ti ọ̀dọ̀ Rẹ̀ wá, a ní láti béèrè níkẹyìn, "Kí ni ma ṣe pẹ̀lú èyí?” Ó nídìí tó fi fún wa ní ìwé náà, torí náà a gbọ́dọ̀ mọ ìdí náà.
Mo gbà gbọ́ pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí, Ọlọ́run sì ti ṣèlérí pé òun yóò bá wa sọ̀rọ̀ nínú àlá àti ìran ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Ó yẹ ká máa retí pé kó máa bá wa sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí, ká sì máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tó bá ń bá wa sọ̀rọ̀.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More