Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 20 nínú 21

Ìgbàgbọ́ àti Ìgbésẹ̀

Ìbùkún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ máa ń ṣiṣẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú ìṣe-tó-tayọ-ojú-lásán. Èyí sì máa ń sọ ohun tí kò ṣeé ṣe di ṣíṣe. Ǹkan tó máa ń ṣẹlẹ̀ nìyí nígbàtí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tí a sì ń rìn nínú ìṣe-tó-tayọ-ojú-lásán.

Bí a kò bá ní ìgbàgbọ́, a kò lè wu Ọlọ́run. Ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run dúró lé orí ìgbàgbọ́. Nígbà tí a di àtúnbí, kò sí ẹnìkan tó lè jẹ́rìí sí ìgbàlà wa nípasẹ̀ ǹkan tí wọ́n lè fún wa. Bí wọ́n tilẹ̀ fún wa ní ìwé ẹ̀rí tó sọ wípé a ti di àtúnbí, kò já mọ́ ǹkankan. Ìjẹ́rìí sí ìgbàlà wa ni ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Jésù Kristi Olúwa láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì àti láti wẹ gbogbo àìṣòdodo wa nù. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe àmúlò ìgbàgbọ́ láti di àtúnbí, bákan náà la ó máa gbé fún Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́. Ó gba ìgbàgbọ́ láti ní ìbáṣepọ̀ ojojúmọ́ pẹ̀lú Jésù Kristi. Ó gba ìgbàgbọ́ láti gbàdúrà, jíhìn rere, fi fún ni, àti láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ohun gbogbo nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run ló dá lórí ìgbàgbọ́. Èyí ni ìdí rẹ̀ tí ó ṣe nira fún wa láti wù Ú láìní i.

Àbí o kò gbà mí gbọ́ pé a kò lè wu Ọlọ́run láìní ìgbàgbọ́? Bẹjú wo Hébérù 11:6. Ìgbàgbọ́ wa ni èròjà tó ṣe pàtàkì jù lọ fún wa láti wù Ú!

Hébérù 11, láti òkè dé ìsàlẹ̀, jẹ́ àyọkà tó yani lẹ́nu tó sì ṣe àtúpalẹ̀ ìgbàgbọ́ bí a ti ríi jálẹ̀ Ìwé Mímọ́ àti ìtumọ̀ rẹ̀ gan-gan. Bẹ̀rẹ̀ láti orí ìgbàgbọ́ Nóà àti Ábráhámù lọ sórí Mósè àti Jákọ́bù, ó ṣe àtúpalẹ̀ ìtàn inú Bíbélì mélòó kan àti bí wọ́n ti ṣe àfihàn ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.

Ìròyìn rere ibẹ̀ wá ni wípé, gbogbo wa la ní ìgbàgbọ́! Róòmù 12:3 ló ṣe àlàyé rẹ̀. Oníkálukú wa ní láti sa ipá fún àmúlò ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Ọlọ́run yìí kí a sì jẹ́rìí gbogbo ohun tí Ó ń gbé ṣe.

Púpọ̀ nínú àwọn ìgbà tí Jésù ṣe ìbáwí àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀, nítorí àìní ìgbàgbọ́ ni. Bí Ọlọ́run ti rí ìgbàgbọ́ sí nìyí. Àìní i a máa fa ìbáwí láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. A ní láti rìn nípa ìgbàgbọ́, ó sì ní láti máa gbèrú síi. Èyí ni ìdí tí onírúurú ìdánwò fi ma ń kọlù wá. Ètò Ọlọ́run ni láti mú àwọn ìpèníjà tí òhun nìkan lè yanjú kọlù wá. Àwọn ǹkan wọ̀nyí a máa ru ìgbàgbọ́ wa sókè. Èyí a sì mú kí agbára ìṣe-tó-tayọ-ojú-lásán farahàn nínú wa níọ̀nàtóga jùlọ.

Púpọ̀ nínú ìkọlù rẹ kò ní í ṣe pẹ̀lú ibi tí o ti ní ìkọlù. Kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú irú èyàn tí o jẹ́. Àmọ́, ó nííṣe pẹ̀lú irúfẹ́ ènìyàn tí à ń yí ọ padà sí. Fún ìdí yìí, Sátánì a máa kọlu òní, rẹ kí ọjọ́-ọ̀la rẹ pẹ̀lú lè ní ìkọlù. Ìdojúkọ ńlá sí ìgbàgbọ́ rẹ ni, láti dábùù ọ̀nà àti dé ibi àyànmọ́ rẹ. Tí a bá lè gba ìgbàgbọ́ wa láyè láti dàgbà kí a sì rú u sókè, a ó lè ta àwọn ìkọlù dànù pẹ̀lú ààbò fún ọjọ́-ọ̀la wa.

Ìwé mímọ́

Day 19Day 21

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/