Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 19 nínú 21

Rírí Ohun tí Ọlọ́run Ń Rí

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a máa ń rò pé ǹkankan kò ṣẹlẹ̀ nítorí a kò ríi, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Gbà á rò báyìí. Tí iṣẹ́ bá ń lọ ní ìta ibi tí o wà, tí o kò sì ríi, ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí wípé iṣẹ́ náà kò ṣẹlẹ̀ rárá, nítorí o kò ní àǹfààní láti ríi? Tàbí tí o kò bá rí inú ilé ìtajà tí ń bẹ ní ìgboro, ṣé èyí wá túmọ̀ sí wípé kò sí ẹnikẹ́ni nínú rẹ̀ bí? Rárá o. Síbẹ̀, bí púpọ̀ nínú wa ṣe yàn láti máa gbé ìgbésí ayé wa nìyí. A ti ní ìgbàlà, ní ìfikúni Ẹ̀mí mímọ́, a sì jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run àti ìjọ Rẹ̀, àmọ́ a kò bìkítà àwọn iṣẹ́ Sátánì ní àyíká wa, bákan náà iṣẹ́ iṣẹ́ ogun ọ̀run pẹ̀lú.

Ojú òye wa gbúdọ̀ mọ́lẹ̀ kedere fún wa láti ní ìmọ̀ nípa ìrètí ìpè Rẹ̀. Pẹ̀lú èyí, òye tàbí ìmọ̀ wa nípa ìpè Rẹ̀ ma ré kọjá ti aròbó. Dípò èyí, a lè mọ bí ìpè Rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ sí. A máa ní àǹfààní láti mọ ǹkan tí Ó fẹ́ ṣe pẹ̀lú ìpè wa.

Nínú Éfésù 1:17-21, ó sọ̀rọ̀ nípa ìṣínilójú yìí. Pọ́ọ̀lù sọ wípé òun ń gbàdúrà kí “Ojú ọkàn wa ba lè mọ́lẹ̀ fún wa láti lè mọ ìrètí tí Ó ti pè wá sí.”

Síwájú síi ní Éfésù 6:12-17, Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìhámọ́ra Ọlọ́run. Ìhámọ́ra yìí – bí ẹ̀yà kàànkan tilẹ̀ yàtọ̀ – súyọ látinú òye tó jinlẹ̀ nípa Ọlọ́run, òtítọ́ Rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ìgbàlà, àti lílo ìwà mímọ́ Jésù – gẹ́gẹ́bí ìhámọ́ra igbáàyà wa. Ìhámọ́ra yìí gbà wá láyè láti kojú gbogbo ìhàlẹ̀ ọ̀tá àti láti “pa iná gbogbo” ọfà rẹ̀.

Wàyí o kìíṣe ìdáàbòbò nìkan ló yẹ kí a máa ṣe! Idà wá, èyí tí Pọ́ọ̀lù pè ní “idà ti Ẹ̀mí,” ni yóò fún wa ní àǹfààní láti gba àwọn ilẹ̀ tí ọ̀tá ti borí padà.

Ìrírí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tí o ní ìrírí rẹ̀ yìí jẹ́ ràlẹ̀rálẹ̀ ǹkan tí o ní àǹfààní sí. Nígbà tí a bá mú ojú òye rẹ mọ́lẹ̀ tán, o máa bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ọlọ́run lè ṣeé àti wípé ìfẹ́ Rẹ̀ ni láti ṣí fèrèsé tí kò ní òdiwọ̀n àkókò, ipò, tàbí ipá ènìyàn nínú.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 18Ọjọ́ 20

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/