Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 16 nínú 21

Ìfàmì Òróró Yàn Ti Ẹ̀mí Mímọ́

A bẹ̀rẹ̀ nípa fífa ara wa lọ́wọ́ àwọn ohun tó ń sọ ìgbésí ayé wa di ẹlẹ́gbin àti bíbá Ọlọ́run rìn. Lẹ́yìn náà, a fi Ẹni àti Ìwàláàyè Ẹ̀mí Mímọ́ kún àwọn àyè tí ó ṣ'ófo wọ̀nyíí. Ní báyìí, a ti ń kọ́ bí a ó ṣe máa gbé ìgbé ayé tí ó kún fún èso, tí ó kún fún Èmí Mímọ́. Èyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú mímọ̀, tàbí mímọ̀ l'ọ́tun, pé Ẹ̀mí Mímọ́ ń fẹ́ láti máa bá wa ṣe àjọṣepọ̀ déédéé. Lónìí, a ó lọ síbi tó jinlẹ̀.

Lóòrèkóòrè nínú Májẹ̀mú Láéláé, omi dúró fún ìwàláàyè àti iṣẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́. Bá a ṣe ń lo àpèjúwe àsọtẹ́lẹ̀ yìí nínú ìgbésí ayé wa, a lè rí i pé a lè yàn láti ṣ'iṣẹ́ ní onírúurú ìpele ti ìfàmì òróró yàn ti Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn òmíràn nínú wa máa ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀mí ìfòrórógbó tí kò ju ìgbáròkó lọ. Àwọn kan lára wa máa ṣe bí ẹni pé wọ́n ti wọ ìgbáròkó, àwọn míì sì máa ń ṣe bí ẹni pé wọ́n ti wọ ọrùn. Àmọ́ ṣá o, àwọn ìyípo tó l'ágbára wà nínú odò Ọlọ́run tó ń mú ká wà ní ipò tí a kò ti ní láti dá dúró fún ara wa mọ́; kàkà bẹ́ẹ̀, a lè máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìdarí Ọlọ́run.

Nínú 1 Johannu 2:27, a rí ìtọ́kasí sí ìfòróróyàn ti Ẹ̀mí.

A tún rí ìtọ́kasí sí àmì òróró nínú Aísáyà 10:27, láàárín àsọtẹ́lẹ̀ àwọn àṣẹ́kù Ísírẹ́lì. Láti inú àyọkà yìí, a lè rí i pé ìfàmì òróró èmí yàn ní agbára ńlá, àti pé, gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ náà ti wí, ó lè "pa àjàgà àti ẹrù ìnira náà".

A gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ níwájú Ọlọ́run pé ó wù wá láti bọ́ lọ́wọ́ ipò tí kò bára dé tí a ti ń ṣiṣẹ́. A nílò láti bẹ Ọlọ́run fún irú ìdàgbàsókè bẹ́ẹ̀ tí a ó fi lè máa lúwẹ̀ẹ́ nínú rẹ̀ – fún ìfàmì òróró yàn kíkún ti Ẹ̀mí Mímọ́.

Ìwé mímọ́

Day 15Day 17

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/