Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti Ọlọ́run
Ìgbàgbọ́ wa ní láti dé ipele tí yóò ti ní ìdánilójú wípé Ọlọ́run ní àwọn ìpinnu dáradára fún wa, àti wíwà ní ìmúrasílẹ̀ láti béèrè fún un. Láti lè dé ipele yìí a ní láti dẹkùn fífi ojú di ara ẹni. Gbogbo wa láti fi ìgbà kan j'ẹ̀bi èyí. Gbogbo láti j'ẹ̀bi ìgbìyànjú láti dígbà bí Ọlọ́run ti ń ṣiṣẹ́. Gbogbo wa la máa ń gbìyànjú láti sọ ọpọlọ kalẹ̀ nípa bí Ọlọ́run yóò ti ṣe ǹkan tí à ń tọrọ lọ́wọ́ Rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, Kìí tẹ̀lé àwọn ipa tí àwa lérò rárá. Nítorí a fojú di ara wa ni.
Éfésù 3:20, sọ ọ́ bó ti rí gẹ́lẹ́. “Ògo ni fún ẹni tí ó lè ṣe ju gbogbo nǹkan tí à ń bèèrè, ati ohun gbogbo tí a ní lọ́kàn lọ.” Ọlọ́run tó fún wa. Ohunkóhun tó lè máa ṣẹlẹ̀, kò sí bí ǹkan ṣe le tó, tàbí bí àìní wa ṣe le tó, Ó tó fún wa.
A ní láti mọ̀ wípé àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì ma bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún pẹ̀lú àjẹṣẹ́kù. A ní láti mọ̀ wípé sísọ àwọ̀n wa sí ègbẹ́ kejì ọkọ̀-ojú-omi ma mú àkóyawọ́ tí a ti ń tiraka fún látòní. A ní láti ronú lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ láti bèrè pé kí Ọlọ́run farahàn lọ́nà ọ̀tọ̀ nínú ǹkan tí à ń là kọjá kí a sì ma fojú di ǹkan tí Ó lè gbé ṣe. A ní láti já ara wa gbà kúrò lọ́wọ́ ìrònú wípé bí a ti fẹ́ ni ǹkan ṣe gbúdọ̀ rí. Ìṣe Rẹ̀ ga ju tiwa lọ; èrò Rẹ̀ ga ju tiwa lọ. Láti lè lúwẹ̀ẹ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, a ní láti pèsè ara wa láti lè gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ti Ọlọ́run. Mo ṣèlérí fún ọ, ó máa ju bí o ti gbà á lérò lọ.
Kólósè 2:8-10 kì wá nílọ̀ láti má bọ́ sínú páńpẹ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀tànjẹ̀. A kò lè gba ara wa láàyè láti gbàgbé wípé ẸNI tó ni ohun gbogbo, mọ ohun gbogbo, wà níbi gbogbo ni Olúwa gbogbo Àgbáyé tí àwa ń sìn. A kò gbọ́dọ̀ gba ìrònú yẹpẹrẹ láàyè bíkòṣe ìrètí ohun ńlá, àrà ọ̀tọ̀, àti àgbàyanu tí Ọlọ́run fẹ́ gbé ṣe nínú àti nípasẹ̀ wa!
Èyí ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. A kò nílò láti mọ ọ̀nà, ìgbà, ibi, tàbí ọwọ́ ẹni tí yóò gbe gbà. A kàn ní láti jẹ́rìí Ọlọ́run láti mu wá sí ìmúṣẹ fún ìṣerere wa àti fún ògo ti'Rẹ̀. Àkókò tó láti da àwọn ètò tiwa sí igbó. Nígbà tí a bá ṣe èyí, a óò rí iṣẹ́ ìyanu.
Àkókò ti tó láti ṣe ìdámọ̀ àti ìdìrọ̀mọ́ ìgbésí ayé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tó ní ìróni-lágbára ti Ẹ̀mí èyí tí Ọlọ́run fẹ́ kí o máa gbé. Àkókò náà tó láti wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún ògo Ọlọ́run!
Ìrìn-àjò rẹ kò pin síbí. Ọjọ́ mọ́kànlélógún tó ṣáájú ìrìn-àjò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tìrẹ ló jẹ́. Ní báyìí, ṣe àkójọpọ̀ àwọn ìlànà tó wà káàkiri nínú ètò yí kí o wá ṣe àmúlò wọn lójojúmọ́.
Àbí o fẹ́ síi? Bẹjú wo Ọjọ́ Mọ́kànlélógún sí Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ látọwọ́ Jeremiah Hosford. Ìwé yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọjọ́ mọ́kànlélógún inú ètò ní fínnífínní àti wípé fúnni ní ìtọ́ni fún ọjọ́ méjìlélógún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More