Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 13 nínú 21

Sísúnmọ́ Ọlọ́run

Sísúnmọ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí pé kí a fi gbogbo ọkàn wa wá Ọlọ́run. Ohun tí àdúrà àti ààwẹ̀ gbígbà túmọ̀ sí gan-an nìyẹn. Kì í ṣe pé a fẹ́ f'ipá mú Ọlọ́run ṣe nǹkan kan ni a ṣe ń ṣe ìwọ́de ọ̀hún. Òmùgọ̀ la jẹ́ tí a bá rò pé a lè mú kí Ọlọ́run ṣe ohunkóhun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń rẹ ara wa sílẹ̀ nípa gbígbàdúrà àti gbígbààwẹ̀ kí Ọlọ́run lè yí wa padà, kí Ó sì mú kí a lè máa rìn ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀ pípé. A máa ń mú àwọn ohun tó lè ṣe ìdíwọ́ fún àdúrà wa kúrò. Ó jẹ́ nípa wíwá Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó wà nínú wa.

A ti ka apá kan Jákọ́bù 4:1-10 ní ìbẹ̀rẹ̀ ìwé yìí, àmọ́ ẹ jẹ́ ká tún wò ó. Gbogbo rẹ̀ ló dá l'órí ìgbéraga àti ìtẹríba. Ó ń béèrè pé kí a tẹ'rí ba fún Ọlọ́run kí a lè sún mọ́-Ọn, àti gbogbo ohun rere tí ìpinnu láti tẹ'rí ba yìí ń mú wá.

Nínú ìwé 2 Kíróníkà 15:1-2, a rí i tí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń bá Asaráyà ọmọ Óbédì sọ̀rọ̀. Ó sọ fún Asaráyà pé bí ó bá wá Òun àti àwọn nǹkan ti Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò wà pẹ̀lú rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí Asaráyà bá kọ̀ Ọ́ sílẹ̀, tí kò sì sún mọ́ Ọlọ́run, Ọlọ́run yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

Nígbà tí ọkàn wa bá di ẹlẹ́gbin, a máa ń sọ ara wa di aláyà líle fún àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ti Ọlọ́run. Nígbà tí ọkàn wa bá di èyí ti o le koko sí àwọn nǹkan ti Ọlọ́run, a ò lè sún mọ́ Ọlọ́run. Kí n tó lè sún mọ́ Ọlọ́run, mo gbọ́dọ̀ wẹ ara mi mọ́ (tú ara mi kúrò nínú ara mi), ní ìgbọràn sí òtítọ́ nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́, àti nínú ìfẹ́ tọkàntọkàn pẹ̀lú ọkàn tí ó mọ́.

Ọjọ́ 12Ọjọ́ 14

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/