Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 12 nínú 21

Gbígbé nínú ìfẹ́ Ọlọ́run

Lánàá, a béèrè l'ọ́wọ́ Ọlọ́run wí pé kí Ó bù sí ìfẹ́ wa fún-Un àti àwọn ẹlòmíràn. Lónìí, a máa kọ́ bí a ṣe lè gbé nínú ìfẹ́ ọ̀pọ̀ yìí.

Láti gbé túnmọ̀ sí ibùdó ni ibi kan, bíi ìgbà tí a bá wà nínú ilé wa. Ibẹ̀ ni à n dúró sí. Gbígbé nínú ìfẹ́ túnmọ̀ sí wí pé a dúró nínú ìfẹ́ Nígbà tí a bá rí wa, nínú ìfẹ́ ni a máa wà, tí a bá gbé nínú ìfẹ́. Ẹsẹ̀ kíkà wa nínú orí kẹrìndínlógun ìwé Ìhìnrere ti Jòhánù fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ tí ó l'ágbára hàn wá, èyí tí a máa rí nígbà tí a bá gbé nínú ìfẹ́.

Jòhánù 15:7-9 sọ nípa agbára tí ó wà nínú gbígbé nínú ìfẹ́ Ọlọ́run. Ó sọ wí pé nígbà tí a bá gbé nínú Rẹ, tí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sì gbé nínú wa, a lè béèrè ohunkóhun tí ó bá wùn wà, a o sì fi fún wa. Ó ṣe èyí fún ògo Rẹ̀! Ó fẹ́ràn láti rí pé àwọn ọmọ Rẹ̀ ṣe oríire gẹ́gẹ́ bíi ìjẹ́rìí agbára, ore-ọ̀fẹ́ àti àánù Rẹ̀.

Nínú Jòhánù 15:26, ó sọ nípa iṣẹ́ Èmí Mímọ́. Nípa àwọn ìkùnà àti kùdìẹ̀ kùdìẹ̀ wa, Èmí Mímọ́ n jẹ́rí sí oore Ọlọ́run. Nípa ìmúsípípé wa láti ọwọ́ Ọlọ́run, àti ìtẹ́wọ́gbà wa nígbà tí a sì jẹ́ aláìpe, à n fi ògo fún-Un.

Nígbà tí a bá gbé nínú ìfẹ́ Rẹ̀, Èmí Mímọ́ á jẹ́ alàbárìn wa, yíó sì kún inú wa ní àkúnwọ́sílè. Kí a tó mọ̀, ìfẹ́ Ọlọ́run á ṣiṣẹ́ nínú wa àti nípasẹ̀ wa títí tí àwọn ohun tí ó n kọ́ wa l'ẹ́sẹ̀, tí ó n fà wá sẹ́yìn, tí ó n mú wa kóríra, ò lè ṣe ohunkóhun mọ́. Á máa di asẹ́gun nígbà tí a bá gbé nínú ìfẹ́.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 11Ọjọ́ 13

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/