Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Fífi Ayé Àdánù Sílẹ̀
A gbà wá níyànjú láti gbé ìgbésí ayé wa ní ìṣọra kí ó má jẹ́ ayé àdánù. Ìgbésí ayé àdánù jẹ́ ìgbésí ayé tí a gbé láti fi ògo fún ara wa, àwọn ìfẹ́ wa, àti àwọn èrò wa láì sì fi ìdí Ọlọ́run ṣe. Ìgbésí ayé ìṣọ́ra jẹ́ ìgbésí ayé tí a gbé láti yin Ọlọ́run lógo, láti jẹ́ ohun tí Ó fẹ́, láti ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, àti láti rí ìmúṣẹ ìpinnu Rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa.
Nígbà tí a bá kún fún Ẹ̀mí, ìgbésí ayé wa yóò hàn gbangba sí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe àkíyèsí wí pé ó yàtọ̀. Nígbà tí a kò bá gbé ayé wa lórí ọgbọ́n ènìyàn tí ó ní òpin, àti ayé àdánù tí ènìyàn, ó hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn pé a gbẹ́ ní ọ̀nà tí ó yàtọ̀ sí gbogbo ènìyàn mìíràn.
Ẹ́fẹ́sù 5:5-18 fún wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan láti ronú lé lórí. Ó ń sọ̀rọ̀ òdì kejì nípa “àwọn iṣẹ́ òkùnkùn tí kò ní èso” ó sì gbà wá níyànjú pé kí a wá ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí ká sì máa lépa rẹ̀. Kíni o rò pé ó wu Olúwa ní ìgbésí ayé rẹ? Ṣé o ń lépa rẹ̀ tọkàntọkàn?
1 Jòhánù 2:16 tèsíwájú láti sọ pé àwọn ìfẹ́ ti ayé kìí ṣe láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Tí a bá mọ èyí, kílódé tí a fí tèsíwájú láti lépa wọn? Kíni ìdí tí a fi n tèsíwájú láti fi wọ́n sí ààyè pàtàkì jù ohun tí a mọ̀ tí ó wù Ọlọ́run?
Láti bẹ̀rẹ̀ síí mú ìwà ayé àdánù kúrò, a ní láti bẹ Ọlọ́run pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti dẹ́kun gbígbé ìgbésí ayé asán. A nílò kí ó ṣ'àfihàn àwọn ohun tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run àti àwọn ohun rere lásán, nítorí àwọn ohun kán wà tí a rí bí ohun tí ó dára, tí kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ dandan, ṣùgbọ́n wọ́n kò wúlò, nítorí wọ́n kìí ṣe ìpinnu Ọlọ́run nínú ìgbésí ayé wa.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More