Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Ìpòǹgbẹ ti Ẹ̀mí
Kò ṣòro láti mọ̀ nígbà tí ǹkan tí ẹnìkan kúndùn bá yí padà, nítorí àwọn ǹkan ọ̀tọ̀ ló máa ń t'ẹ̀yìn rẹ̀ yọ. Bí ǹkan tí a kúndùn bá yí padà láti àwọn ǹkan tó nííṣe pẹ̀lú Ọlọ́run sí afẹ́ ayé, ìkúndùn yí ma mú àwọn èso ohun ayé lọ́wọ́. Ní ìdàkejì, tí ìkúndùn wa bá yí padà látorí àwọn afẹ́ ayé sórí àwọn ǹkan ti Ọlọ́run, ebi yìí ma mú kí àwọn ǹkan ti Ọlọ́run ṣú yọ.
Kíni ó ń ṣú yọ nínú ayé tìrẹ lónìí? Kíni àwọn ǹkan tó ń jẹyọ nínú ìṣíṣẹ rẹ lọ́jọọjọ́, nínú ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, ìhùwàsí rẹ, ìwúrí rẹ, àti àwọn ìtara rẹ? Tó bá jẹ́ wípé àwọn ohun ti ayé ló ń ṣú yọ látinú ìṣẹ̀dá rẹ, ìpòǹgbẹ rẹ ti yí padà kúrò ní ti Ẹ̀mí sí àwọn afẹ́ ayé. Bí o bá sì jẹ́ ohun ti Ẹ̀mí ló ń ṣú yọ látinú ìṣẹ̀dá rẹ, a jẹ́ pé ìpòǹgbẹ rẹ tí yí padà kúrò nínú ohun afẹ́ ayé sí ti Ẹ̀mí.
Tí ìpòǹgbẹ mi bá dá lórí àwọn ǹkan bíi kíka Bíbélì, àdúrà, àti ìjọsìn, ní ìkọ̀kọ̀ àti ní gbangba, a jẹ́ pé ìpòǹgbẹ tó dára ni mo ní. Àmọ́, tí n kò bá ní ìpòǹgbẹ fún àwọn ǹkan wọ̀nyí, àwọn ǹkan tí kò yẹ ni mò ń pòǹgbẹ fún.
Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ìpòǹgbẹ. Ní Jòhánù 6:25-70, Jésù pe ara Rẹ̀ ní Oúnjẹ Ìyè. Kí ni èyí túmọ̀ sí? Ó fẹ́ rújú fún àwọn ọmọlẹ́yìn Rẹ̀ náà díẹ̀. Jésù ń pe ara Rẹ̀ ní orísun oúnjẹ ẹ̀mí. Ó ń fi yé wa wípé nígbàtí òùngbẹ tàbí ebi bá dé bá wa, nípa ti ẹ̀mí, a lè lọ sọ́dọ̀ Rẹ̀ láti ní ànító àti àní-ṣẹ́kù.
Ní Aísáyà 55:1-2, a rí àmúlò àpèjúwe yìí lẹ́ẹ̀kan si. Àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ tí ebi sì ń pa àmọ́ tí wọn kò l'ówó ni a sọ fún wípé wọn lè jẹ wọ́n sì lè mu. Bí wọn kò bá l'ówó, báwo ni èyí ti ṣeé ṣe? Ebi àti ìpòǹgbẹ wọn jẹ́ ti ẹ̀mí - ìjọba Ọlọ́run kì í sì í gbowó fún èyí!
A ní láti ṣàwárí ìpòǹgbẹ wa fún oúnjẹ ẹ̀mí padà. A nílò ìpòǹgbẹ fún àwọn ǹkan ti Ọlọ́run. A ní láti yẹ̀bá fún níní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ǹkan tí kò nítumọ̀. A nílò láti máa pòǹgbẹ fún àdídùn Ọ̀rọ̀ náà, fún àdúrà, àti ìjọsìn. Àwọn aràn inú wa ní láti máa ké rárá nípasẹ̀ ìpòǹgbẹ fún ìwàláàyè Rẹ̀. Nígbà tí a bá ṣèyí, a óò tẹ́ ọkàn wa lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ni ayé wa yóò ní ìyípadà pẹ̀lú.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More