Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Òùngbẹ Èmí
O ti ṣe é! O ti tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ kárakára láti tú ara re nù l'ọ́wọ́ ohun gbogbo tí ì bá dí ẹ l'ọ́wọ́ láti gba ohun gbogbo tí Ọlọ́run ní fún ẹ. Láti ọjọ́ méje sẹ́yìn, o ti tẹrí ara re ba, o ti yẹ ara re wò, o sí ti mú àwọn ohun tí ó n tẹ́ ara lọ́rùn kúrò. Kò dẹrùn, àmọ́ ó ní ànfàní.
Fún àwọn ọjọ́ méje tí ó n bọ̀, a máa yi ọkàn wa sí ìkúnnù ti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run ti ṣe tán láti kún ààyè tí a ti dá nínú ayé wa. Àwọn àyípadà tí a kò rò tẹ́lẹ̀ mbọ̀ sínú ayé rẹ. Gbàradì fún ayé ìyípadà.
Nínú Jòhánù 4:13-14, a ṣàlàyé òùngbẹ èmí. Àwọn ohun ayé yìí - omi tí Jésù kọ́kọ́ ṣe ìtọ́ka sí - yíò tán òùngbẹ wa, àmọ́ fún àkókò díẹ̀ ni, òùngbẹ á túnbọ̀ gbé wá. Ó tẹ̀síwájú láti sọ nípa omi tí kò ní jẹ́ kí òùngbẹ gbe wá mọ́. Omi yìí ni Èmí Mímọ́. Èyí ni omi tí ó yẹ kí a fẹ́.
Nínú Jòhánù 7:37-39, Jésù tẹ̀síwájú èyí nígbà tí Ó sọ wí pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnìkẹ́ni, kí ó wá kí ó mu.” Láti gba Ẹ̀mí, omi ayérayé yìí, a ní lò láti gba Jésù, kí a sì gbàgbọ́ nínú ohun tí Ó ti sọ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Kò ye kí a kọ̀ máa ṣe àwọn iṣẹ́ lásán. Ó yẹ kí a pòngbẹ fún omi ìyè titun tí Ẹ̀mí Mímọ́ nìkan lè ṣ'ètò.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More