Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Ìkọ̀sẹ̀
Ǹjẹ́ a ti ṣẹ̀ ọ́ rí?
Ìkọ̀sẹ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn irinṣé tó múnád'óko jù tí Sátánì ma ń lò fii ṣe ète rẹ̀ láti ṣe ìdíwọ́ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ó ma ń mú kódà àwọn alágbára balẹ̀. Ó ma ń lo Ìkọ̀sẹ̀ láti mú kí ìjọba Ọlọ́run dínkù ní ipa. Ó ma ń lo Ìkọ̀sẹ̀ láti wó ìjọ palẹ̀. Ó ma ń lo Ìkọ̀sẹ̀ láti fa ìdílé ya. Ó ma ń lo Ìkọ̀sẹ̀ láti mú ìyapa wà láàrin àwọn onígbàgbọ́. Ó ma ń lo Ìkọ̀sẹ̀ láti ṣe atọ́kùn àìsàn ọkàn, ọpọlọ àti ti àgọ́ ará nínú ènìyàn.
Òwe 17:9 sọpé ẹni tí ó fojú fo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ ẹ́ mú kí ìfẹ́ gbòòrò sí i, sùgbọ́n ẹni tí ń tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ yóò pín ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ní yà. Pé a fagilé ìkọ̀sẹ̀ lára ẹni kò túmọ̀ sí pé o kò rántí, pé o ti gbàgbé ẹ̀ pátápátá. Ó túmọ̀sí pé o kọ̀ láti tún sọ nípa rẹ̀ àti pé o kò bá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ yan'dì. Ó túmọ̀sí pé oó tẹ̀síwájú nígbàtí òún ṣe irúfẹ́ ìdáríjì tí Ọlọ́run ti fi hàn ọ́ sí àwọn tó yí ọ ká.
Nínú Hébérù 12:15, ó sọpé kí oníkálukú ríi pé ó gba ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. Ore-ọ̀fẹ́ yìí, tí a kọ́kọ́ rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún ẹ̀sẹ̀ wa, gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí a fún ẹlòmíràn. A gbọ́dọ̀ yára láti dáríjì àwọn tó ṣẹ̀ wá! Ó tẹ̀síwájú láti sọ nípa gbòǹgbò ìkorò tí ó ma ń fa wàhálà. Gbòǹgbò yìí lè túmọ̀sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ńkan, ṣùgbọ́n ní kúkúrú, ọ́jẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn ṣẹ̀ wá dé ibi tí yíò mú wa ní ìkorò sí wọn nínú ọkàn wa.
Máṣe jẹ́ kí ìkọ̀sẹ̀ ta gbòǹgbò nínú ọkàn rẹ. Yàrá láti dáríjì bákannáà yára láti tọrọ fún ìdáríjì láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Tí a bá fẹ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ ti Ẹ̀mí, a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ikose jẹ́ bárakú nínú ayé wa!
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More