Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ
Ìmọ̀ Tara Ẹni Nìkan
Bí a ṣe lè pa ohun tí ó ti wọ́pọ̀ nínú ayé òde òní tì ni a máa gbé yẹ̀ wò lónìí.
Ohun tí à n ṣe, nínú ìjọ àti ní gbangba, gbọ́dọ̀ jẹ́ láì sí èmí ìlépa ara tàbí ogo asán. Yálà a wà ní ibi iṣẹ́, tàbí ní ilé ìwé, tàbí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́, tàbí ará ilé, nínú ọjà, tàbí níbi tí a ti n ṣe ìṣẹ́ olórí, èròngbà wa ṣe kókó.
Ìbéèrè tí ó yẹ kí a máa bi ara wa kọ́ ni pé, “Kíni ó dára jù fún mi?” Dípò bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí a máa bi ara wa léèrè, “Kíni ó dára jù fún Ìjọba Ọlọ́run?” Ìfojúsùn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ bí a ṣe lè wá ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti ṣe ìfẹ́ pípé Ọlọ́run.
Nínú Fílíppì 2:3-4, ó sọ wí pé kí a má ṣe fi ìlépa ara tàbí ògo asán ṣe ohunkóhun. Ohunkóhun túnmọ̀ sí ohunkóhun. Báwo ni ayé wa ì bá ti yàtọ̀ tó, nígbà tí a bá n ṣe ohun gbogbo fún rere Ìjọba Ọlọ́run dípò ara wa?
1 Kọrinti 10:24 ṣ'àlàyé ìlànà yìí síwájú síi nígbà tí o sọ pé kí ẹnikẹ́ni má ṣe ronú nípa ara rẹ̀ nìkan; ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù máa wá rere ọmọnìkejì rẹ̀. Báwo ni ìjọ ì bá ti yàtọ̀ sí, tí oníkálukú bá n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rere àwọn ẹlòmíràn l'ọ́kàn? Báwo ni ayé ì bá ti rí, tí kò bá sí ẹnikẹ́ni tí ó n ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìlépa ara ṣùgbọ́n fún rere àwọn ẹlòmíràn?
Nígbà míràn, tí a bá n gbèrò láti ṣe ohunkóhun fún àwọn ẹlòmíràn, tàbí fún Olúwa, ẹ jẹ́ kí a béèrè wí pé kí Ó fi hàn wá tí èròngbà wa bá jẹ́ tí ìmọ̀ ara tẹni.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!
More