Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 3 nínú 21

Ìtanijẹ̀

Ohun tí ó kàn fún wa láti gbá jáde nínú ayé wa fún ìgbésí ayé tó ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ẹ̀mí ni ìtànjẹ ọ̀tá.

Nínú Jòhánù 8:44, ó pe èṣù ní onírọ́. Àmọ́ kìí wá ṣe onírọ́ lásán – ó pèé ní baba gbogbo irọ́. Oyè yí fẹ́ lágbára díẹ̀ àti wípé kìí ṣe èyí tí a lè fún ẹnikẹ́ni. Ọ̀tá wa jẹ́ ọ̀gá ìtànjẹ. Níní ìmọ̀ nípa èyí gbọ́dọ̀ ru wá sókè láti gbé ìgbésẹ̀ fún ìpamọ́ kúrò nínú gbogbo ìtànjẹ tí ó dà sínú ayé.

Nínú Gálátíà 6:7-8, Pọ́ọ̀lù sọ fún ìjọ wípé kí wọ́n má ṣe fi ààyè sílẹ̀ fún ìtànjẹ. Ní àkókò yẹn, àti pàápàá nísinsìnyí, ọ̀tá ń ṣiṣẹ́ láti fọ́po-mọ́yọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí ó sì ń dàárú mọ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run l'ójú, àti ṣíṣì wọ́n lọ́nà nípa ìwà híhù. A kò lè gba ara wa láàyè láti di ẹran ìjẹ fún ìtànjẹ ńlá yìí.

Dípò èyí, a ní láti ri ara wa sínú òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nígbà tí a bá ṣe èyí, a máa borí gbogbo ìtànjẹ ọ̀tá àti wípé yóò wá rọrùn láti máa tẹ̀síwájú nínú ìfẹ́ Ọlọ́run láì kọsẹ̀.

Ọjọ́ 2Ọjọ́ 4

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/