Ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀Àpẹrẹ

21 Days to Overflow

Ọjọ́ 2 nínú 21

Àwọn Ohun Tí Ó Lè Pín Ọkàn Ẹni Níyà

Lónìí, a gbájú mọ́ dídá ara wa nídè kúrò nínú àwọn ohun tó ń pín ọkàn níyà tí ayé yìí ń mú wá ní ọ̀pọ̀ yanturu. A kò lè tẹ̀lé Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ ní kíkún fún ìgbésí ayé wa, ká sì ní ìgbé ayé tí ó kún fún Ẹ̀mí bí a bá ń di ẹni tí kò lè f'ojú sùn nígbà gbogbo.

Nínú Fílípì 4:8, Pọ́ọ̀lù fún ìjọ tó wà ní Fílípì ní ìtọ́ni nípa ohun tó yẹ kí wọ́n máa ronú lé lórí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí ó fẹ́ kí ìjọ máa gbé yẹ̀ wò nínú àyọkà yìí nìkan ni àyọkà yìi m'ẹnu bà, ó tún lè jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí kò sí nínú àyọkà náà. Ìdààmú ọkàn, àníyàn, ìbẹ̀rù, àti àníyàn kò sí níbì kankan nínú àkọsílẹ̀ Pọ́ọ̀lù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé kí wọ́n máa ronú nípa àwọn ohun tó jẹ́ òótọ́, tó níye lórí, tó mọ́, tó fani mọ́ra, tó yẹ fún ìyìn àti ohun tó tọ́. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò túbọ̀ máa ronú l'ọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, a ò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà.

Nínú Jòhánù 17:17, a rí i tí Jésù ń gbàdúrà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀. Ó ní kí Ọlọ́run sọ wọ́n di mímọ́ nípasẹ̀ òtítọ́ Rẹ̀. Kí ló sì pè ní òtítọ́ Ọlọ́run? Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Èyí jẹ́ kí a l'óye ohun tí Pọ́ọ̀lù ní l'ọ́kàn nígbà tó sọ fún ìjọ tó wà ní Fílípì pé kí wọ́n máa ronú nípa ohun tó jẹ́ òótọ́.

Ó yẹ kí a máa ronú lórí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tí a bá fi èyí s'ípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa, àwọn nǹkan ayé yìí kò ní tètè pín ọkàn wa níyà. Èyí jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì nínú gbígbé ìgbésí ayé tí ó kún fún Ẹ̀mí àti àkúnwọ́sílẹ̀

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

21 Days to Overflow

Nínú ètò YouVersion ti ọjọ́ 21 ti Àkúnwọ́sílẹ̀, Jeremiah Hosford máa mú àwọn olùkà lọ ìrìn àjò ọ̀sẹ̀ mẹ́ta láti tú ara won nù, láti kún fún Èmí Mímọ́, àti láti gbé ayé èmí ti àkúnwọ́sílẹ̀. Ó tó àkókò láti dẹ́kun gbígbé ayé lásán, kí a sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ayé àkúnwọ́sílẹ̀!

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Four Rivers Media fún ìpèsè ètò ẹ̀kọ́ yìí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ lọ sí: https://www.theartofleadership.com/