Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Nígbàtí Ìgbàgbọ́ Bá Kùnà: Ọjọ́ Mẹ́wàá Nípa Wíwá Ọlọ́run Nínú Òjìji IyèméjìÀpẹrẹ

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ọjọ́ 10 nínú 10

Bíì àwọn Ọmọ lẹ́yìn Jésù àkọ́kọ́, a ti pè ọ́ sínú ìtàn tí ó tóbi ju tìre lo. Aáyè rẹ kún fún èrèdí. A dá ọ láti mọ̀ọ́ àti láti tẹ̀lée. Ọkàn ńpògbẹ fún ìdí tí ó se dá ọ. Pẹ̀lú gbogbo wa, àti àwọn tó ń sìn ín àti àwọn tó ńsiyèméjì, a pè wọ́n láti kópa

Ó ńpe Ọmọ lẹ́yìn tí ìgbàgbọ́ rẹ kò yẹ̀. Ó dà bí wípé wọ́n ti gbàgbọ́ tipẹ́, láti inú oyún ni wọ́n ti ńkọrin ìyìn, kò sí ìyípadà láti ìgbà náà. Bẹ́ẹ̀ni ó ńpe àwọn tó siyè méjì... Àwọn tí wọn ò fẹ́ ní àsepọ̀ kankan nítorí wọn ò fẹ́ ní ìgbàgbọ́ tí kìí se tiwọn.

Jésù pe àwọn méjèèjì káàbọ̀. Àwọn méjèèjì ni a pè. Àwọn méjèèjì ni a rán. Àwọn méjèèjì ni ó se Pàtàkì fún ìsọjí tí ó ti bẹ̀rẹ̀

Ibi kíbi tí o bá wà nínú ìrìn àjò ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó ńpe Ìwọ náà

Bóyá o ti jìnà ṣílé, o kò tilẹ̀ mọ̀ bóyá o sì gbàgbọ́. Tàbí bóyá o ti kọjá àtúnse, o wá wà níbi iyèméjì, ò ń wo àwọn ìbérè tí ó sòro. Tàbí bóyá ọ̀nà ilé lo wà. Ìbásepọ̀ rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run yàtọ̀ sí bí ó ti rí tẹ́lẹ̀, sùgbọ́n ó ti dára nísìsiyì. Ó jìn. Ó wà láàyè sí.

Ibikíbi tí o wà, àti ohun kóhun tó o bá rò nípa Ọlọ́run, àwọn síse tí kò lópin wà níwájú rẹ̀. Àwọn Ọ̀rọ̀ tí Jésù kọ́kọ́ sọ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ ni wípé "Wá, kí o sì tẹ̀lé mi", àwọn Ọ̀rọ̀ ìkẹyìn rẹ jẹ́ bákannáà. Máa tẹ̀síwájú. Máa lé òtítọ́.

Ewu tí ó lágbárajù kìí se wípé a sọ ìgbàgbọ́ wa nù sùgbọ́n a wà ní agbedeméjì rẹ̀. Ojoójúmọ́ fún wa ní àànfàní láti bèèrè, wá, kan ìlẹ̀kùn. Àwọn ohun tí a lè sàwárí pọ̀. Ohun tí a lè kọ́ pọ̀. Ó pọ̀ tí a lè kọ́. Àwọn òkè tí ó lágbára pọ̀ láti gùn, àwọn ìpèníjà tí a ní láti borí, àwọn ohun tí ó rẹwà tó ye kí a mọ̀lára. Ọlórun tí ó yẹ kí á mọ̀.

O sẹ̀sẹ̀ bẹ̀rẹ̀

Àti nígbàtí ọkàn rẹ bá pòrúrù, tí oókún rẹ̀ múra sílẹ̀, àti nígbàtí o bá kùnà ìgbàgbọ́ rẹ̀, rántí wípé o ní ìrètí yìí:

Jésù ló ní ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́yìn


Njẹ́ o fẹ́ mọ̀ si? Bèèrè fún ìwé DominicNígbàtí ìgbàgbọ́ bá kùnàláti sàwárí sí nípa iyèméjì àti ìgbàgbọ́.

Ọjọ́ 9

Nípa Ìpèsè yìí

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ìlàkàkà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iyèméjì jẹ́ ohun tí ó lè jẹ́kí ènìyàn fẹ́ dáwà tàbí kí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kàn ńdá jìyà láìjẹ́ kí enìkankan mọ̀, àwọn míràn kọ ìgbàgbọ́ sílẹ̀ lápapọ̀, wọ́n rò pé...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://bit.ly/2Pn4Z0a

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa