Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Nígbàtí Ìgbàgbọ́ Bá Kùnà: Ọjọ́ Mẹ́wàá Nípa Wíwá Ọlọ́run Nínú Òjìji IyèméjìÀpẹrẹ

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ọjọ́ 1 nínú 10

Nítorí a wà nínú ayé tó ní òdiwọ̀n, a máa ń ṣiyèméjì.

Nítorí a kò ní gbogbo ìdáhùn ní àrọ́wọ́tó, àwọn ìbéèrè ma wá bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹyọ:

Kí ni a lè fi Ọlọ́run wé? Báwo ni mo tilè mọ̀ ọ́? Kí ni èrèdí ìgbésí ayé wa? Ipasẹ̀ wo ni kí n tọ̀?

Ní bíi ọrúndún mẹ́rìnlá sẹ́yìn ni ẹnìkan, tí a kò mọ orúkọ rẹ̀, sọ wípé “inú àwọsánmọ̀ àìmọ̀kanin” ni àwa èèyàn wà. Ìdí nìyí tí a fi máa ń ṣiyèméjì. Kìíṣe gbogbo ìgbà là ń rí òfurufú.

Wàyí o, ohun kàn tí a ní láti rántí ni wípé ètò Ọlọ́run ni gbogbo ǹkan wọ̀nyí. Ó mọ̀ọ́mọ̀ mú kí ǹkan rí bẹ́ẹ̀ ni. Onírúurú ìjánu ló ti fi sínú ètò rẹ̀. Ọlọ́run ò j'ayò pa. Ó ti mọ̀ wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìmọ̀kan ni á máa kojú ní ìgbésí ayé wa. Síbẹ̀ ó yàn láti mú kí ìtàn àwa ẹ̀dá ènìyàn láti rí báyìí. . . . Nígbàtí Ọlọ́run pinu láti ṣe ìṣẹ̀dá, ó ṣeé ṣe kó gbé e gba ọ̀nà ẹgbẹ̀rún ọ̀tọ̀. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yan ayé yìí. Ó yàn ẹ́. Ó yàn mit. Pẹ̀lú gbogbo kùdìẹ̀ kudiẹ wa. Síbẹ̀, ó pe gbogbo rẹ̀ ní “dáradára.”

Ìtumọ̀ gbogbo èyí ni wípé iyèméjì kìíṣe ǹkan àjèjì.

Wọ́n jẹ́ àbájáde gbígbé nínú ayé yìí.

Iyèméjì tí ò ńṣe kìíṣe nítorí o jẹ́ ènìyàn búburú tàbí nítorí o kò kíyèsí àwọn ǹkan t'ẹ̀mí bíi àwọn ẹlòmíràn. Ó máa ńṣe iyèméjì nítorí o jẹ́ ẹlẹ́ran-ara.

Èyí ṣe pàtàkì, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Krìstẹ́nì rí iyèméjì bíi ẹsẹ̀ tó ní ìrírí tí a kò gbudọ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. . . .

Ọlọ́run ò ṣẹ̀dá Ádámù àti Éfà pẹ̀lú ojútùú sí àwọn ìdojúkọ tó nípọn nínú ayé. Dípò èyí, ó gbà wọ́n láàyè láti tọ pinpin, ṣe ìwádìí, àti láti kẹ́kọ̀ọ́. Ó gbin ọgbà àjàrà kan níbi tí àwọn ǹkan àràmàndà ti wà ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Èyí túmọ̀ sí wípé nígbàkigbà tí a bá ṣe iyèméjì, kìíṣe nítorí a já Ọlọ́run kulẹ̀; ìdí rẹ̀ ni wípé iyèméjì jẹ́ èsì àdáyébá sí àwọn ìdiwọ̀n òye wa. . . .

Ìgbàgbọ́ kìíṣe nípa ìkánilọ́wọ́kò, bíkòṣe nípa àwọn ǹkan tí a lè gbé ṣe. Ìgbàgbọ́ jẹ́ ìsúnmọ́ni nípa ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ àti ìbáṣepọ̀. Àmọ́ láti dé ipele yìí, nígbà mìíràn a ní láti wó àwọn ìdánilójú wa palẹ̀. Àwọn ìlànà tí a mọ̀ ma di èyí tó ní ìdádúró. Àwọn ìbéèrè wa ma ṣàìní èsì. Àmọ́ ní ipele yìí kan náà, ni a ti máa ní àbápàdé pẹ̀lú Ẹnìkan. Báyìí ni ìrẹ́pọ̀ ṣe máa wá sáyé.

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 2

Nípa Ìpèsè yìí

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ìlàkàkà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iyèméjì jẹ́ ohun tí ó lè jẹ́kí ènìyàn fẹ́ dáwà tàbí kí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kàn ńdá jìyà láìjẹ́ kí enìkankan mọ̀, àwọn míràn kọ ìgbàgbọ́ sílẹ̀ lápapọ̀, wọ́n rò pé...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://bit.ly/2Pn4Z0a

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa