Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Nígbàtí Ìgbàgbọ́ Bá Kùnà: Ọjọ́ Mẹ́wàá Nípa Wíwá Ọlọ́run Nínú Òjìji IyèméjìÀpẹrẹ

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ọjọ́ 6 nínú 10

Ìpohùnréré jẹ́ igbe láti ọkàn tí ó fọn káàkiri, tó tútù, àti tí ó ńi egbò tí kò jinná. Ó ún yọjú wo ìjìyà, a ṣáa ní ọgbẹ́, a gbáa si ọ̀tún s ósì, ósọ kún, ó sì kígbe tantan fún ìdájọ́. Ìpohùnréré tako ìdáhùn ṣákálá tí kò jinlè, tí a kàn pọn léwé. Ó pè fún ìdánilójú tó yanrantí tí kò sì bẹ̀rù ìbéèrè tí kò ní ìdáhùn. 

Ìpohùnréré jẹ́ orin ọkàn tó ń ṣiyèméjì.

Àkókò tí à ń gbé jẹ́ èyítí ìpohùnréré ti ṣubú lu ìgbà tí kò rọrùn. A ò mọ bí a ti ṣe lè dojú kọ ẹ̀dùn ọkàn. A fẹ́ràn láti kọ oun tí à ń là kọjá. A jẹ́ olórí nínú àwọn ìlú tó ń kó oògùn lò fún oun kan tàbí òmíràn. Àfara jọ àti ìtàn ìpọ́njú ma ún da ọkàn wa rú. Eré a mára yá àti idán orí ẹ̀rọ a ma kúni lọ́kàn. Ìtura a máa pa ni bí ọtí. Lẹ́yìn náà, nígbàtí ìpọ́njú bá gbé ìbéèrè líle dé nípa Ọlọ́run àti ìgbé ayé, a máa ń kìí mọ́lẹ̀ tàbí ká dée pa. Ṣùgbọ́n fún ìgbà dí ẹ̀ ló mọ. Bíi odò tí ó ń bì ní èbúté, a lè dá'gunlá, tàbí ká tiraka láti ká ọwọ́ àgbàrá tó ń bọ̀, tàbí kí á kọ́ bí a ti ṣe ń gbé inú omi ńlá.

Ìwé Mímọ́ ṣe àkàwé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Wọ́n rí oun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká wọn, wọn ò panumọ́ lóríi àìṣòdodo, wọ́n sì ń ké pe Ọlọ́run kí Ó ṣàlàyé ara Rẹ̀. Dáfídì ké lóhùn rara, “Yíò ti pé tó, Olúwa?” (Orin-Dáfídì 13:1). Jeremáyà, nígbàtí ó rí ìpọ́njú, be Ọlọ́run kí Ó dá síi. Jóòbù sọ ìrètí nù. Jákọ́bù ja ìjàkadì. Mósè gba ìpè níjà. Ábúráhámù ṣeiyèméjì. Màríà bèrè ìbéèrè. Jésù sọ kún.

Ìpohùnréré kìí ṣe ìdàkejì ìgbàgbó; ó jẹ́ ohun tí ìgbàgbó dà nígbà tí ó ti fara ro ìpọ́njú. Ìwọ̀n bí ìgbóná ọkàn wa bá ṣe jinlẹ̀ sí ní ìgbàgbó pé Ọlọ́run dára, bẹẹ̀ni ìgbóná ọkàn wa tí a fi ń ẹ̀hónú hàn nígbàtí dídára Ọlọ́run bá fara pamọ́.

Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ kún ní ibojì ọ̀rẹ́ Rẹ̀.

Kò burú kí á sọ àìlárá wa síta. Kò burú kí kígbe jáde oun tí kò tẹ wa lọ́rùn. Kò burú kí á bínú.

Kò burú tí a kò bá ní ìdáhùn sí ohun gbogbo.

Ọlọ́run ṣì ún sáré tọ wá wá, Ó ún dì mọ́ wa, Ó ún báwa sọkún pẹ̀lú. Lẹ́yìn èyí, pẹ̀lú omijé, a ríi wípé Ẹni ti Ó ún sọkún ní ọwọ́ tó ní àpá. Ara Rẹ̀ kún fún ọgbé. Ojú Rẹ̀ kò ṣeé wò mọ́.

Ó hàn sí wa pé òun náà jẹ́ ìyà. 

Ọjọ́ 5Ọjọ́ 7

Nípa Ìpèsè yìí

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ìlàkàkà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iyèméjì jẹ́ ohun tí ó lè jẹ́kí ènìyàn fẹ́ dáwà tàbí kí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kàn ńdá jìyà láìjẹ́ kí enìkankan mọ̀, àwọn míràn kọ ìgbàgbọ́ sílẹ̀ lápapọ̀, wọ́n rò pé...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://bit.ly/2Pn4Z0a

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa