Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Nígbàtí Ìgbàgbọ́ Bá Kùnà: Ọjọ́ Mẹ́wàá Nípa Wíwá Ọlọ́run Nínú Òjìji IyèméjìÀpẹrẹ

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ọjọ́ 8 nínú 10

Ìtàn Jákọ́bù nígbà tí ó ńja ìjàkadì pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ àfihàn tí ó rẹwà nípa bí Ìgbàgbọ́ tí ó jinlẹ̀ se rí. Ìgbàgbọ́ tí ó jinlẹ̀ jẹ́ ìpàdé tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ìpàdé tí a tẹra mọ́ láìfi sílẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí wa, nígbà míràn tí yíò la òógùn, ìtàjẹ̀sílẹ̀ tàbí àìrọrùn lọ, tí yíò sì jẹ́ ìpàdé gidi pẹ̀lú gidi pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìgbàgbọ́ kìí se ohun tí a mọ̀ọ́mọ̀ kọsílẹ̀; ó jẹ́ akete gídígbò. Ó túmọ̀ sí gbígbé gbogbo ẹ̀rù, ẹ̀sẹ̀, àìfọkànbalẹ̀, àti àìgbàgbọ́ wa lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run fún ara wa. Bẹ́ẹ̀ni, ó ṣeéṣe kí ó gba ọgbẹ́ àti kí gìràgìrà rẹ sì wálẹ̀ wọ̀ọ̀. Ṣùgbọn ó dára láti jẹ ìdọ̀tí nítòótọ́ níwájú Ọlọrun ju ènìyàn ẹlẹ́sìn irọ́ lọ.

Ìgbàgbọ́ túmọ̀ sí kí á fi gbogbo ara sínú rẹ

Tí o bá fẹ́ ìgbàgbọ́ tí ójinlẹ̀, kìí ṣe ìgbàgbọ àwọn òbí rẹ, àwọn ọ̀rẹ́, tàbí ilé ìjọsìn nìkan, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ tí yíò yí ọ padà tí yíò jẹ́ kí o wà láàyè, lẹ́hìnnà kò sí ọ̀nà mííràn.... Nínú Ìwé Galátìà 6:16, Pọ́ọ̀lù ṣọ pé “Ísírẹ́lì Ọlọ́run ni wá." Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, nítorí pé ogún tẹ̀mí wa kún fún àwọn ènìyàn tí wọ́n bá Ọlọ́run ja ìjàkadì, nígbà náà ni a pè wá láti jẹ́ oníjàkadì pẹ̀lú.

ọ̀nà kan ṣoṣo tí Jákọ́bù tí ó wà nínú wa le di Íṣráẹ̀lì, ọnà kan ṣoṣo tí ìgbàgbọ wa le dàgbà, ni tí a bá mú gbogbo ẹni tí a jẹ́ wá ṣọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ohun gbogbo. Àti pé ìyẹn pẹ̀lú iyèméjì wa. Pàápàá àwọn iyèméjì wa.

Ìgbàgbọ́ má ńdàgbà bí ó bá se ńkọjá kúrò ní ibi tí o àìléwu àti ibi tí a le sọ, lọ sí ibi tí ó sókùnkùn, àti àwọn ààyè tí ó kún fún iyèméjì. Ìgbàgbọ́ a máa kọ̀ láti dín àwọn àlá rẹ kù sí ìwọ̀n àwọn ìbẹ̀rù rẹ. Ìgbàgbọ́ kò sá pamọ́ fún àwọn ìbéèrè ṣùgbón ó fi ìtara dáhùn wọn....

Ìwé-mímọ kìí ṣe ìtàn tí àwọn ènìyàn tí ó lọra fi ààyè gba iyèméjì; ó jẹ́ nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n fi agídí ja àwọn iyèméjì wọn. Wọ́n kún fún ohun tí ó ju oréfèé lásán, tí kò wúni lórí àti ìgbàgbọ́ oníṣẹ́po méjì. Socrates sọ pé, “Ìgbésí ayé tí a kò ṣe àyẹ̀wò kò yẹ láti gbé.” Àwọn òǹkọ̀wé àti akíkanjú Bíbélì tẹnu mọ́ ọn pé ìgbàgbọ́ tí a kò ṣàyẹ̀wò kò yẹ láti gbà gbọ́.

Nítorí náà, ní Orí Bíbélì kan sí òmíràn, ẹsẹ Bíbélì kan sí òmíràn, wọ́n fi ìgboyà, ìtara, àti ìgboyà bá Ọlọ́run wọn jà. Ohùn líle wọn kígbe pé, “N kò ní jẹ́ kí ẹ lọ títí ẹ óo fi súre fún mi!” Wọ́n mọ̀ pé yóò jẹ́ líle àti ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n gbogbo àsìkò tí wọ́n lò kò sòfò

Ọjọ́ 7Ọjọ́ 9

Nípa Ìpèsè yìí

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ìlàkàkà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iyèméjì jẹ́ ohun tí ó lè jẹ́kí ènìyàn fẹ́ dáwà tàbí kí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kàn ńdá jìyà láìjẹ́ kí enìkankan mọ̀, àwọn míràn kọ ìgbàgbọ́ sílẹ̀ lápapọ̀, wọ́n rò pé...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://bit.ly/2Pn4Z0a

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa