Àlàyé nípa Ètò Bíbélì

Nígbàtí Ìgbàgbọ́ Bá Kùnà: Ọjọ́ Mẹ́wàá Nípa Wíwá Ọlọ́run Nínú Òjìji IyèméjìÀpẹrẹ

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ọjọ́ 2 nínú 10

Tí Ìgbàgbọ́ Mi Bá Jẹ́ Èyí Tó Mẹ́hẹ Ńkọ́?

Àwọn mìíràn ma rí ìbéèrè yìí bíi pípe ìgbàgbọ́ níjà. Àmọ́ tí àkókò yí bá jẹ́ àǹfààní tó dára jù fún ìgbàgbọ́ ńkọ́? Bóyá a tilẹ́ nílò kí a pe ìgbàgbọ́ wa níjà kí àwọn èrò àti ǹkan tó jẹ́ ìpìlẹ̀ rẹ̀ lè ní àgbéyẹ̀wò àti àtúnṣe. Ta ló mọ̀ bóyá àwọn ìdojúkọ tí à ń bá pàdé gẹ́gẹ́bí ọmọlẹ́yìn Jésù ló ń mú kí ore-ọ̀fẹ́ dàgbà síi nínú ayé àwọn tó ń tiraka láti gbàgbọ́, àti láti pèsè ilẹ̀ ọlọ́ràá fún ìgbàgbọ́ láti dàgbà síi. 

Nínú ìtàn, a kọ ọ́ wípé àwọn ènìyàn Ọlọ́run figbe ta ní oko-ẹrú. Bí a ti kweọ púpọ̀ nínú àwọn ìwé Bíbélì nìyí. Bí ìyípadà ìjọba ti ń bẹ̀rẹ̀ kò jù báyìí lọ. Nínú ìkorò ìfọwọ́rọ́ni-sí-ẹ̀gbẹ́ ni ìdánimọ̀ ìkórajọpà àwọn ènìyàn ti máa ń ṣú yọ. Lọ́gán tí ìdánimọ̀ yí bá ti di rírí, àwọn àmúyẹ aláìlẹ́gbẹ́, àti ẹwà ìlanilọ́yẹ rẹ̀ máa mú púpọ̀ nínú àwọn tí kò gbàgbọ́ padà wá sílé.

Tí èyí bá jẹ́ òtítọ́, ìtumọ̀ rẹ̀ ni wípé a kò nílò láti bẹ̀rù nígbàtí iyèméjì bá yọ sí wa ní onírúurú ọ̀nà. A kò nílò láti bẹ̀rù. Àti wípé kò yẹ kí a bẹ̀rù nígbàtí a bá kojú irúfẹ́ iyèméjì kankan, láti ibikíbi. Bóyá láti ibi ìfipámúni àṣà, àwọn onírúurú àjálù nínú ayé, àìdúrólójúkan ìmọ̀lára ẹni, àwọn ìnira tí máa ń kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú ìdàgbàsókè nínú ẹ̀mí, tàbí àníyàn líle tó fara ṣoko. Nígbàtí iyèméjì bá dí ìrìnàjò rẹ lọ́wọ́, o ní láti mọ rírì wípé ó ṣeé ṣe kí ó padà gbé ọ débi tí o kò lérò.

Iyèméjì kọ́ ni òpin ìtàn náà, ó kàn dàbí ìjánu láàrin gbùngbùn rẹ̀ ni. Iyèméjì ni ohun àràmàǹdà tí a kò retí; ìbéèrè tí kò lésì, tàbí ní ìdáhùn. Iyèméjì dà bíi wíwo sinima tí ń dẹ́rù bani, tí a kọ̀ láti gbójú kúrò, bẹ́ẹ̀ni a kọ̀ láti dìde tàbí bọ́síta.

Iyèméjì a máa tì ọ́ láti ṣe àtúnṣe ìgbẹ́yẹ̀wò ìtàn ayé rẹ. Kíni àwọn ǹkan tó jẹ ọ́ lógún? Kí ni ǹkan tí o gbàgbọ́ gangan? Ipasẹ̀ wo ni o fẹ́ tọ̀? Bíi omi tí ń ṣàn ní ipadò méjì, iyèméjì ma ṣí àyè sílẹ̀ fún onírúurú àbájáde. O lè ṣàn lọ bá Ọlọ́run tàbí kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ̀. O lè n'ọwọ́ gán ìgbàgbọ́ tàbí àìnígbàgbọ́. Ó kù sí ọ lọ́wọ́. L'ọ́rọ̀ kan, iyèméjì kò fì s'ápákan tàbí òmíràn; ìhà tí a bá kọ síi ló máa darí àbájáde rẹ̀. 

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 1Ọjọ́ 3

Nípa Ìpèsè yìí

When Faith Fails: 10 Days Of Finding God In The Shadow Of Doubt

Ìlàkàkà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti iyèméjì jẹ́ ohun tí ó lè jẹ́kí ènìyàn fẹ́ dáwà tàbí kí ó ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwọn kàn ńdá jìyà láìjẹ́ kí enìkankan mọ̀, àwọn míràn kọ ìgbàgbọ́ sílẹ̀ lápapọ̀, wọ́n rò pé...

More

A fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ HarperCollins fún ìpèsè ètò yìí. Fún àlàyé síwájú síi, Jọ̀wọ́ lọsí: http://bit.ly/2Pn4Z0a

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa