Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ

Start Here | First Steps With Jesus

Ọjọ́ 15 nínú 15

Kólóssè 4:17 | Parí Ohun tí o Bẹ̀rẹ̀

Báwo ni ẹ̀yín ọrẹ́ mi. Òní ni ọjọ tí ó kẹhin fún wà. Ẹ kú isé! O parí ohun tí o bẹ̀rẹ̀ - èyí jẹ́ àmì ìwà gidi. Ní tòótọ́. Bóyá o ti lẹ̀ jíròrò pé - Kíni ó kàn? Nítorínàà lóni a ó ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tí a ti kọ́, a ó sì gbèrò àwọn ìgbésẹ̀ láti tẹ̀lé.

Ẹsẹ̀ kan à ní oopín ìwé Kólósè tí ó báamu dáradára. Ẹsẹ̀ 17:

"Sọ fún Archippus: 'Wò ó pé o parí íṣẹ-ìránṣẹ tí o ti gbà nínú Olúwa.'"

Ìjọnilójú. A kò mọ Akiposi, àti pé a kò mọ iṣẹ-ìranṣẹ rẹ. Ṣùgbọn àwá mọ pe ó ṣe pàtàkì. Ènìyàn kan ṣe pàtàkì sí Ọlọrun, àti pé ìpè Ọlọ́run ní igbésí ayé ènìyàn kan ṣe pàtàkì sí àgbáyé wọn. Bẹ́ẹ̀ni Pọ́ọ̀lù sọ fun wí pé, "Parí íṣẹ-ìránṣẹ." Parí ohun tí o bẹrẹ.

Èyí sì ni ohun tí mo fẹ́ sọ fún yín. Mi ò mọ̀ ọ́ dáadáa, àmọ́ mo mọ̀ pé o ṣe pàtàkì lójú Ọlọ́run, mo sì mọ̀ pé íṣẹ-ìránṣẹ rẹ máa ṣe ìyípadà. A dá fún èrèdí kan àti ìpè kan - nítorínáà ṣe iṣẹ́ náà láṣe parí. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò.

Ọ̀rọ̀ méjì péré la fi bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa: "Tẹ̀lé Mi." Èyí sì ni ìtàn wa láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin - títẹ̀lé Jésù. Bí a ṣe ń lọ, a rí i tí Jésù ń wo àwọn aláìsàn sàn, tó ń mú ìjì dákẹ́ jẹ́, tó ń dárí ji àwọn òtòṣì ẹlẹ́ṣẹ̀, tó sì ń mú àwọn èèyàn padà bọ̀ sípò. Èyí kò yọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn sílẹ̀, kò yọ ìwọ náà sílẹ̀ pẹ̀lú.

Nínú Máàkù 8, Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu:

"Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn." (Máàkù 8:34).

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì tẹ̀ lé e. Àpẹẹrẹ ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ náà jẹ́ ká rí i pé tá a bá ń tẹ̀ lé Jésù, a ò ní máa fi owó àti ìgbéraga ṣe òrìṣà. A sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àṣẹ Ọlọ́run tó ga jù lọ: nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti nífẹ̀ẹ́ ẹnìkejì rẹ. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti gbà wá là.

Má sì gbàgbé pé a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i. A kì í sanwó ẹ̀ṣẹ̀ wa, a kì í sì í sọ ara wa di ẹni rere. Jésù kú láti san gbèsè ìràpadà ní kíkún, ó sì jíǹde láti fún wa ní ayé ọ̀tun. Ore-ọ̀fẹ́. Ojúṣe wa ni láti gbé ìgbésí ayé tó yẹ fún ìpè rẹ̀.

Èyí mú wa dé Kólósè. Báwo la ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa? Ọ̀rọ̀ méjì tí kò nira: Tẹ̀lé Jésù. Àmọ́ ní báyìí, dípò tí wàá fi máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Krístì nìkan Ó wà nínú rẹ. Ní báyìí, È̩mí Mímọ́ ń darí yín nínú ìgbésí ayé yín, bí ẹ ṣe ń bọ́ ògbólógbòó ìwà yín sílẹ̀, tí ẹ sì ń gbé ìwà tuntun wọ̀.

Ẹ̀mí sì fún ọ ní àwọn àṣà tuntun. - Rántí pé àwọn nǹkan yìí kì í ṣe ohun tó yẹ kó o ṣe, bí kò ṣe ibi tó yẹ kó o dé. Wọ́n sì jẹ́ ibi tó dára láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tó o máa gbé:

Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Máa wá àkókò lójoojúmọ́ láti ka Bíbélì. A ti ṣe àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan lórí ìkànnì Bíbélì yìí tó máa jẹ́ kó o lè ma tẹ̀síwájú, pàápàá jùlọ mo sì fẹ́ràn àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí ìwé Bíbélì kọ̀ọ̀kan. Tàbí kó o tún bẹ̀rẹ̀ ètò yìí láti ìbẹ̀rẹ̀. Lákòókò yìí, pe ọ̀rẹ́ rẹ kan kí ẹ jọ sẹ́. Èyí sì mú mi wá sí ìdíi…

Bẹ̀rẹ̀ àsà ìpàdé ará Máa bá àwọn onígbàgbọ́ péjọ. Ọlọ́run pè wá pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa, èyí sì gba pé kí á máa lo àkókò papọ̀. Ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì wà fún nìyẹn. Rántí pé, ṣọ́ọ̀ṣì kì í ṣe àpéjọ fún eré ìwòran, àjọṣepọ̀ ará ni. Torínáà, kó ipa nínú rẹ̀. Ẹ fi ara yín. tòótọ́ hàn láì sèké, ẹ sọ ohun tó wà lọ́kàn yín, ẹ jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ẹ jọ gbàdúrà, kẹ́ ẹ sì rí ìwòsàn. Ó sì tún jẹ́ ibi tó dára láti wà…

Máa ṣe iṣẹ́ ìsìn déédéé. Èyí ni iṣẹ́ òjíṣẹ́. Máa wá ọ̀nà láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ lọ̀nà tó rọrùn. Ọ̀nà kan tó dára jù lọ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé…

Máa gbàdúrà déédéé. Rántí pé kì í ṣe torí kó o lè rí ohun tó o fẹ́ ni o ṣe ń gbàdúrà, bí kò ṣe kí o lè sún mọ́ Ọlọ́run. Torí náà, máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ fún Ọlọ́run, kó o sì máa gbàdúrà fún àwọn mìíràn.

Àti pé àwọn àṣà tuntun yóò máa pọ̀ sí i: àṣà ìjẹ́wọ́, àṣà sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Ṣùgbọ́n tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ti di àkọsílẹ̀ àìgbọ́dọ̀máṣe, tẹ̀ jẹ́jẹ́. Rántí - kì í ṣe títẹ̀lé òfin, ṣùgbọ́n tí tẹ̀lé Jésù ni. Torí náà, mámú ọ̀rọ̀náàle rárá, máa tẹjú mọ́ Jésù, kó o sì jẹ́ kí Ẹ̀mí Mímọ́ máa darí rẹ.

Má sì gbàgbé pé kì í ṣe pé wọ́n fẹ́ sọ ẹ́ di Krìstẹ́nì tó máa ń gé kẹ́kẹ́. Ńṣe ni a ń yí ọ padà láti inú lọ sí òde - a tún ọ ṣe ní àwòrán Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí a ti dá ọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan lára àṣà tuntun rẹ ni pé kó o máa fúnni ní nǹkan. Ṣùgbọ́n o ò lè fúnni ní owó láti fi gba àmì lọ́dọ̀ Ọlọ́run. O máa ń fúnni ní nǹkan torí pé Ọlọ́run jẹ́ ọ̀làwọ́, o sì ń kọ́ láti jẹ́ ọ̀làwọ́ bíi tirẹ̀.

Nítorí náà, àkókò ti tó láti bẹ̀rẹ̀. Ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀. Àwọn ìrìn àjò wà nínú ìgbésí ayé àti ìrìn àjò nínú Bíbélì. Ọlọ́run ní iṣẹ́ kan fún ọ, nítorí náà parí ohun tó o ti bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe iṣẹ́ tìrẹ nìkan ni, iṣẹ́ Rẹ̀ ni, àti:

"Ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àtàtà nínú yín yóò parí rẹ̀" (Àwọn ará Fílípì 1:6).

Kì í kàn-án ṣe pé kí ìwọ parí iṣẹ́ rẹ, bí kò ṣe pé kí Ọlọ́run parí iṣẹ́ rẹ̀ nínú rẹ. Nítorí náà, máa tẹjú mọ́ Jésù, "olórí àti Aláṣepé" ìgbàgbọ́ rẹ.(Hébérù 12:2). Òun ló bẹ̀rẹ̀ èyí, Òun ni Yóò sì parí rẹ̀. Má sì gbàgbé pé o kò dá wà. Kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì Yóò kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láé.(Hébérù 13:5) Àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú ìwé Mátíù ni:

"Dájúdájú, èmi wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo, títí dé òpin ayé." (Mátíù 28:20).

fún Àṣàrò àti Ìjíròrò

  • Kí ni gbólóhùn yí "parí ohun tí o ti bẹ̀rẹ̀" túmọ̀ sí nínú ìgbésí ayé rẹ?
  • Fílípì 1:6 sọ fún wa pé "Ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín yóò mú un parí" Kí nìyẹn túmọ̀ sí fún ọ?
  • Àpilẹ̀kọ wa lónìí fún ọ ní áwọn àbá nípa ohun tó o lè ṣe. Kí oó ṣe báyìí?
Ọjọ́ 14

Nípa Ìpèsè yìí

Start Here | First Steps With Jesus

Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Through The Word fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://throughtheword.org