Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ

Start Here | First Steps With Jesus

Ọjọ́ 10 nínú 15

h2>1 | Gbé Ayé Rẹ̀

Ẹ káàbọ̀ padà ẹ̀yin ọ̀rẹ́ - a ti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́! A ti tẹ̀lé Jésù la ìhìnrere Máàkù kọjá. Nítorínà kíni yíò tẹ̀le? Ó dára náà, ohun tí ó kàn ni pé a ó tẹ̀le Jesu. Mo mọ̀ - a ti ṣe bẹ́ẹ̀ ṣáájú. Ṣùgbọ́n nísìnyìí ó yàtọ̀. Ní ìparí Máàkù, àwọn ọmọ-ẹ̀hìn wo bí Jésù ti gòkè lọ sí Ọ̀run. Ó gbayì! Ṣùgbọ́n lẹ́hìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n tí tọ ipasẹ̀ Rẹ̀, kíni wọ́n ń ṣe báyìí?

Ó dára náà, ṣáájú kí Ó tó lọ, Jésù fún wọn ní Àṣẹ Ńlá:

< blockquote> ”Ẹ lọ kí ẹ ṣe gbogbo àwọn orilẹ̀-èdè ní ọmọlẹ́yìn...">(Mátíù 28:19).

Rántí - ọmọ-ẹ̀hìn túmọ síẹni tí ó ǹtẹ̀le ní. Nítorínáà a pe àwọn ọmọ-ẹ̀hìn àkọ́kọ́ láti mú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn míràn wá síi-gẹ́gẹ́ bí àwa náà

Nwọn sì ṣe bẹ́ẹ̀! Ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì sọ àwọn ìtàn ìyanu wọn bi wọn ti ṣe tan ìhìnrere ká ayé ìgbà wọn. Báyìí, ó wù mí láti lè sọ pé ohun gbogbo ń lọ déédé láti ìgbà náà. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Ilé ìjọsìn Krìstíẹ̀nì ti ṣe iṣẹ́ ribiribi tí ó dára ní àgbáyé, ṣùgbọ́n a tún ṣe àṣìṣe diẹ àwọn nkan míràn tí ó mú ipalara gidi wà. Àti pé pé àwọn àṣìṣe wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ ní àkókò díẹ̀ ṣéhìn - ìwà ìbàjẹ́, ọ̀kánjúwà, àgàbàgebè - Àwọn yí tètè bẹ̀rẹ̀ nínú ìjọ. Ṣùgbọ́n àwọn ohun tí ìjọ ṣe dáradára náà wà: bíi àánú, ìrètí, ati ore-ọ̀fẹ́. Nítorínáà tí a bá lè ṣe èyí, ẹ jẹ́ kí á ṣe bí ó ṣe tọ́. Jẹ́ kí á gbé ìgbé ayé rẹ̀.

Ṣugbọn bawo ni a ṣe ń gbé irú ayé yìí? Mo lè sọ pé, "Kí á dẹ́kun láti máà ṣe àwọn ohun búburú kí á ṣí bẹ̀rẹ̀ ṣí ṣe rere." Ṣugbọn ó dàbíi kí á máa ṣi ṣé láti ìta wá sínú ilé - ó sì jẹ́ ohun èlò fún àgàbàgebè. Jésù ṣe ìyípadà wá lati inu jáde sí ìta ni. Báwo ni ìyẹn ṣe jẹ́ ṣíṣe? Jẹ́ kí á lọ sí inú Bíbélì láti wádìí.

Lẹ́yìn ìwé Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì, Bíbélì ní àwọn ìwé tí a kọ sí ẹnìkọ̀ọ́kan láti ọwọ́ àwọn Àpọ́sítélì - pẹ̀lú àwọn Ìtọ́sọ́nà lóríi bí o ṣe lè tẹ̀lé Jésù ní òde òní. Ẹ̀kọ́ burúkú ti wọ inú ilé ìjọsìn ní àtètẹkọ́se, Nítorínáà a kọ àwọn ìwé wọ̀nyí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn onígbàgbọ́ làti mọ òtítọ́ yàtọ̀ sí àwọn ìrọ - àti làti gbé ìgbé ayé yìí.

Nítorínáà èyí ni ibití ó kàn tí à ń lọ: sí inú ìwé Kólóssè. Àpóstélì Pọ́ọ̀lù kọọ́ sí àwọn Krìstẹ́nì ní Kólósè. Wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ tuntun, torínáà ó pé fún wa. Lónìí ni orí Kíní, a ó ri ohun pàtàkì mẹ́ta láti ṣé ohun tí ó tọ: Ore-ọ̀fẹ́, Ẹ̀mí Mímọ́, àti mímọ Jésù.

Ìwé náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìkíni ìbánidọ́rẹ láti ọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù, bákannáà mó nífẹ bí àwọn ìwé wọ̀nyí ti ṣe fọhùn sí ẹnìkọ̀ọ́kan. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo ìwé lò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́ Ó jẹ́ ìkíni tí ó wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ìpìlẹ̀ òtítọ́. Ore-ọ̀fẹ́ jẹ́ ẹ̀bùn - a kò jogún rẹ̀, bẹ̀ẹ́ni kò sì tọ́ sí wa, Ọlọ́run kàn fẹ́ràn wa nítorí pé Ó fẹ́ wa - ore-ọ̀fẹ́. Àti pé gbígbé nínú ìgbàgbọ́ wa bẹre pẹ̀lú òye ohun tí ore-ọ̀fẹ́ jẹ́.

Nínú ìwé Kólósè yí, Pọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún iṣẹ́ ìyanu tí Ó n ṣe nínú ìgbésí ayé àwọn Krìstẹ́nì tuntun wọ̀nyí: ìgbàgbọ́ wọn, ìfẹ́ wọn, àti ìrètí wọn. Pọ́ọ̀lù sọ pé gbogbo rẹ bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ tí wọ́n gbọ́ ìhìnrere náà

"... àti pé wọ́n ní òye ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run" (Colossians 1:6)

Èyí ní ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Ní ìmòye pé Ọlọ́run gbà wá là nítorí Ó fẹ́ràn wa. Kìí ṣe nítorí a jogún rẹ̀ - a kò lè jogún rẹ̀. Kìí ṣe nítorí pé ó tọ́ sí wa- bẹ́ẹ̀ni kò tọ́ sí wa rárá. Jésù san ìdíyelé ní kíkún, a kò sì lè ṣe àfikún rẹ̀. Nínú ìwé míràn sí àwọn ará Éfésù, Pọ́ọ̀lù ṣé àgbékalẹ̀ rẹ̀ báyìí:

"Nítorí ore-ọ̀fẹ́ li a tí fí gbà yín là nípa ìgbàgbọ́ àti èyí nì kì ìṣe tí ẹ̀yin tìkára yín: ẹ̀bùn Ọlọ́run ní. Kì ìṣe nípa isẹ, kì ẹnikẹ́ni má báà ṣògo" (Efesu 2: 8).

Àgbàyanu àlàáfíà àti ògidì ominira wà nínú òdodo yí: a gbà wá là nípasẹ ore-ọ̀fẹ́. "Kìí ṣe nípasẹ̀ áwọn iṣẹ́" túmọ̀ sí pé a kò kò jo'gun ìgbàlà. Ìgbìyànjú láti jogún ìgbàlà n yọrí sí ìyangàn, ìgbéraga, ati idajọ - gẹ́gẹ́ bíi áwọn alágàbàgebè. Ìmọ̀ ore-ọ̀fẹ́ mú ìrẹ̀lẹ̀ wá. Síbẹ̀ a ǹṣe àwọn iṣẹ́ tó dára, ṣùgbọ́n a ǹṣe wọ́n pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́ kannáà tí Ọlọ́run fún wa. Pọ́ọ̀lù pèé ní "síso èso" - tí ó jẹ yọ fúnra rẹ̀ bí ìyípadà láti inú wà.

Sísọ̀rọ̀ nípa àtinúwá, kíni ohun gangan tí ǹṣẹlẹ nínú? Báwo ni ìyípadà yẹn ṣe ṣẹlẹ̀ àti níbo ni òye yẹn ti wá? Nínú ẹsẹ̀ 8, Pọ́ọ̀lù sọ pé ìfẹ tuntun tí ó ṣẹlẹ̀ láàrin àwọn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàgbọ́ yí jẹ “ìfẹ́ tí inú Ẹ̀mí.” Àti ní ẹsẹ̀ 9, ó gbàdúrà pé Ọlọ́run Yóò...

"...fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí."

Èyí ni ìgbésẹ̀ wa t’ókàn: Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí jẹ́ Ọlọ́run - ìpele kẹta ti Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí náà nṣiṣé nínú wa, Óún fún wa ní ìfẹ́ àti àánú, Óún ṣe ìrànwọ́ fún wa níti ìdálẹ́bi ẹsẹ, agbára láti dojúko ibi, ati itọsọna lati ipase imọ ati ọgbọn fun igbesi aye wa. Ẹ̀mí ni bi a ṣe n gbe igbe ayé naa.

Àbájáde, ní ẹsẹ̀ 10, jẹ́ "ìgbésí ayé tí ó wu Olúwa." Ìyẹn ni kọ́kọ́rọ́ àṣeyọrí naa. Kìí ṣe gbígba ìfẹ́ Rẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n gbígbé ayé ìyanu ifẹ ti Ó ti fi hàn wá tẹ́lẹ̀. Ore-ọ̀fẹ́ jẹ́ kí a mú ojú wa kúrò lórí iṣẹ́ wa o sì gbe lé tí tóbi agbára Rẹ̀, ati lori "dídàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run" (1:10).

Lẹ́yìn gbogbo ẹ̀, iyẹn ni ohun tí títẹ̀lé Jésù já sí: mí mọ̀ Ọ. Rántí - fẹ́ràn Ọlọ́run kí ó sì fẹ́ràn ọmọnìkejì pẹ̀lú. Ẹ̀yí ni ó mú wa wá sí ohun kẹta tí ó ṣe pàtàkì: ore-ọ̀fẹ́, Ẹ̀mí Mímọ́, àti mímọ Jésù. Orí ìwé náà parí pẹ̀lu ìrántí tí ó lágbára nípa ẹni tí Jésù jẹ́. Ng ó dúró lórí èyí, ṣùgbọ́n mo gbà ọ́ níyànjú láti ka Kólóssè 1, kí ó sì lo àkókò níbí pàápàá . Gbà làti mọ ẹni tí Ọmọ Ọlọ́run ìṣe. Nínú ẹsẹ̀ 15:

“Ọmọ náà (Jésù) (jẹ́ àwòrán Ọlọ́run tí a kò rí, akọbi lori gbogbo ẹda. Nitori nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: awọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ì bá ṣe ìtẹ́, tabi agbára, tabi àwọn aláṣẹ; nípa sè Rẹ̀ a dá ohun gbogbo àti fún un. Ó tí ṣáájú ohun gbogbo àti nínú rẹ̀ li ohun gbogbo dúró sọ́kàn.”

Fún Àṣàrò àti Ìjíròrò

    Ìtọ́sọ́nà wa òní sọ pé ìgbìyànjú láti yípadà làti ìta jẹ́ ohun èlò fún àgàbàgebè. Kíni ìdí tí o rò pé ó fí rí bẹ́ẹ̀?
  • Á ti sọ pé láti ṣiṣẹ́ fún ìgbàlà ń yọrí sí ẹ̀bi tàbí ìgbéraga, nígbàtí ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ̀run ń yọrí sí àlàáfíà àti ìrẹ̀lẹ̀. Ṣé o rò pé ìyẹn jẹ́ òtítọ́?
  • Kólósè1:10 pè wá làti gbé “ ìgbésí ayé tí ó yẹ fun Olúwa.” Kíní o rò pé a lè fi ìgbésí ayé wa wé?
Idagbasoke Bọtini: day_10

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 9Ọjọ́ 11

Nípa Ìpèsè yìí

Start Here | First Steps With Jesus

Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Through The Word fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://throughtheword.org