Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Kólósè 2 | Dúró Lórí Ẹ̀kọ́
Ẹ káàbọ̀ padà ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi. Lónìí ìkìlọ̀ nípa ẹ̀tàn ni à ń gbé yẹ̀wò. Ní Kólósè 2, ẹsẹ̀ kẹrin sọ pé,
"Èyí ni mo sì ń wí, kí ẹnikẹ́ni kì ó má báà fí ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín ṣìnà."
Mo kórìíra pé kí ènìà parọ fún mi. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ẹlẹ̀tàn wá — àwọn olùkọ́ èké tàbí àwọn akónisìnà olùkọ́ — àti àwọn àríyànjiyàn wọn lè dàbí ohun tí ó bójú mu. Ṣùgbọ́n má ṣe gba ẹ̀tàn wọn láàyè. Nítorí ẹ̀tàn lè mú ọ ṣe ohun tí kò tọ́. Ǹjẹ́ ó tí wọ́ ọkọ̀-èrò tí ó ń gbé ọ lọ ní ọ̀nà tí kò tọ́ rí? Èyí tó burú jù ú, nígbà kan ní ilé-ìwé mo yá sí ọ̀nà ti ko tọ nínú ere-ije oníbùsọ̀ marun kan mo sì sáré kúrò níbi tí ó yẹ kí eré parí sí. Ni ìkòríta yí ìjáfáfá rẹ ko ṣe pataki - ó sáà ǹlọ́ ni ọna ti ko tọ́! Ati pe ohun irufẹ èyí kanna le ṣẹlẹ nípa tí ẹ̀mí.
Bí a ṣe ńtẹle Jesu, a ni lati duro si ọ̀gangan ọna — kí a ṣí lọ ni ọna tààrà. Ati ọna ti o tọ ni pé kí a tẹle Jésù. Òun ni ọna náà. Bayi iyẹn le dabi ohun ti o han gedegbe, ṣugbọn nígbà míràn a jẹ idiwọ fún wa nípa mímú ọkàn wa lọ seyi àti sọ́hùn-ún. Tàbí èyí tí ó burú jáì — kí a tàn wá jẹ. Nítorí náà lati jẹ ki a wà ní ọ̀gangan ọ̀nà, jẹ ki a lọ sí inú Ọrọ naa. Kólósè 2, ẹsẹ̀ 6:
“Nitorina bí ẹ̀yin tí gbà Kristi Jésù Olùgbàlà wa, bẹ́ẹ̀ ní kí ẹ máà rìn nínu Rẹ̀.”
Mo ní inú dídùn sí ìyẹn. Fí Jésù ṣáájú — ki o si duro pẹlu Rẹ̀. Awọn olukọ èké a máà tàári awọn onígbàgbọ́ kuro ni ọ̀nà tí ó rọrùn nípa kí a kàn tẹ̀lé Jésù. Nitorinaa tẹsiwaju nínú rẹ, ni ẹsẹ 7,
kí ẹ fí gbòǹgbò múlẹ̀, kí á sì gbé yín rò nínú Rẹ̀". ”
Ronú sí eléyìí. Nígbàtí o bá gbin igi kan, o sì fi igi kékeré mìíràn gberó mọ lẹ́gbẹ́, igi kékeré yí ní yíò múu dúró títí yíò fí dàgbà. Díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ló mú Jésù gẹ́gẹ́bí igi kékeré yẹn. Bí wọn ṣe ńdagba, wọn kò nání Rẹ̀ mọ́. Máṣe ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù gan-an ní gbòǹgbò wá. Òun ni àjàrà, àwa ni àwọn ẹ̀ka. Àwọn gbòǹgbò ló ń pèsè oúnjẹ fún ìdàgbàsókè àti jẹ́kí a wà ní ìdúró ṣinṣin nígbàtí ìjì bádé. A “fi gbòǹgbò múlẹ̀, a sì gbé wa ró” ninu Jésù. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù tún kìlọ̀ fún wa lẹ̀ẹ́kan sí pé: má ṣe jẹ́kí a "fi ìsòfo àti ìmòye ẹ̀tàn" tí kò fí ìdí múlẹ̀ nínú Jésù mú wa ní ìgbèkùn.” Ẹsẹ̀ 9:
“Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara,”
Ẹ̀kún Ọlọrun ninu ara kan. Jesu ní a ǹ sọ nípa Rẹ̀. Kíkún - kìí ṣe diẹ kiun, ọgọrun nínú ọgọrun ni. Ati ẹsẹ 10:
“... nínú Kristi ni a ti mú wa wá sí kíkún.”
Ní àwọn ọ̀nà míràn, Jésù jẹ́ kíkún Ọlọ́run, àti pé nígbàtí o bá fìdí múlẹ̀ nínú Rẹ̀, ìwọ náà di kíkún pẹ̀lú — ènìyàn tí ó pinnu láti jẹ́.
Nítorí náà, àwọn olùkọ́ èké ń ti àwọn Kristẹni kúrò ní ọ̀nà tí ó tọ́ nipa kíkọ́ni pé Jésù jẹ́ ẹ̀yà nínú Ọlọ́run. Àti wípé dípò títẹ̀lé Jésù, wọ́n dojú kọ àwọn òfin wọ̀nyí . Wọ́n sọ pé o ní láti ṣe àwọn ǹkan wọ̀nyí láti lọ́ sí Ọ̀run. Àwọn ǹkan láti inú Májẹ̀mú láíláí, bí ìkọlà.
Ó dára náà, da ẹ̀rín èké rẹ dúró. Ìkọlà dá bi aworan ti ara pẹlu itumọ ti ẹmi. Gígé ẹran ara kuro ṣe àfihàn bi Olúwa ṣe gé - ìṣẹ̀dá ẹ̀ṣẹ̀ wa -kúrò. Ṣugbọn ikọla ti ara jẹ tí awọn Jù, kì í ṣe ohun tí a pá láṣẹ fun awọn Kristẹni. Sibẹsibẹ awọn olukọ èké tá kú pe awọn ọkunrin Kristeni ní láti kọlà dandan, wọn yipada láti tẹle Jesu sinu àdábọwọ́ ti sọ pé ṣe àti má ṣe, tí ó ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí ó dara. Síbẹ̀ náà Paulu sọ pe Jesu ṣe iṣẹ náà - O ge ẹran-ara wa - nípa tí ẹmi, kìí ṣe ti ara.
Ati ẹsẹ 12 mú Ìrìbọmi wa. Ti o ba jẹ́ tí Jesu, o pe ọ lati ṣe ìrìbọmi . Ìrìbọmi kìí ṣe iṣẹ lati gba ọ là, o jẹ ohun ti o ṣe nitori Jesu tí gba ọ là. Nípa ìrìbọmi ni, a ṣe dá wá mọ̀ pẹlu Jesu: igbesi aye mí atijọ kú pẹlu Jesu lori àgbélébù, ajinde rẹ sọ̀ igbesi aye mí di ọ̀tun. Nítorí náà ìrìbọmi je aworan isinku — ní ìsàlẹ̀ sínú omi, ati ajinde — jade sókè kuro ninu omi.
Àti pé ìgbésí ayé ọ̀tun nííṣe pẹ̀lú bí a ṣe ń tẹ̀lé Jésù nísinsìnyí. Ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. A ko ṣiṣẹ́ lati san gbogbo awọn ẹṣẹ wa. Ẹsẹ 13 sọ pe Jesu
...ti ṣe ìdáríjì gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wá."
O pá gbogbo igbèsè wa rẹ - ko si nkankan mọ́ lati sàn. Ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kò nípá mọ́ lóríi rẹ.
Àti pé ìdí nìyẹn tí ó fí jẹ́ wípé títẹ̀lé Jesu kò dá lórí awọn ofin kánkán. Ni ẹsẹ 16, kìí ṣe nipa ohun tí ò ń jẹ́ tàbí mú," tàbí nípa àwọn àjọ̀dún ẹ̀sìn" tàbí ọjọ́ ìsinmi. Àwọn ǹkan wọ̀nyẹn wà nínú Májẹ̀mú Láéláé, ati pe wọ́n ṣe pàtàkì, àmọ́ ẹsẹ̀ 17 ṣàlàyé pé gbogbo wọn ní...
"...òjìji awọn ohun ti mbọ̀. ”
Àwọn òjìjí wúlò — wọ́n fún ọ ní ìlànà ohun tí ń mbọ̀. Ṣugbọn Pọ́ọ̀lù sọ otitọ ibẹ̀- nkan náà ni a rí nínú Kristi.
Jésù jẹ́ ojúlówó. Àwọn òfin àti àṣà jẹ́ òjìji nìkan.
Nígbàtí ó bá di ohun tí a ní - láti ṣé - bí “Iwọ ní láti jọ́sìn, iwọ ní láti gbàdúrà”- a ti yí ìjọsìn padà sí ọ̀nà láti dá àwọn èèyàn l'ẹ́bi. Lẹ́hìn náà a ṣé awọn àfikún ofin diẹ si bí ẹsẹ 21,
“Má ṣe dìmú! Má ṣe tọ́ọ wò! Má ṣe fi ọwọ́ kàn án!”
Pọ́ọ̀lù sọ pé awọn ofin wọnyẹn dá bí "ìrísí ọgbọ́n" ṣugbọn wọn kò ṣiṣẹ́. O kò lè tún ara rẹ ṣe pẹ̀lú àwọn òfin tí ó le kókó àti ìjọsìn tí a fipá ṣe. Àti pé ìgbésí ayé tí kúrò ní má ṣe wọ́n.
Tẹ́tí sílẹ̀. Nígbàtí a bá tẹ̀lé Jésù, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ǹkan ní ohun tí a tì ńse tí a kò ṣe mọ́. Ṣùgbọ́n kìí ṣe nípa àwọn òfin. A ní ìyípadà nítorí a sọ wá di ọ̀tun. A ti fi gbòǹgbò múlẹ̀ nínú Jésù àti pé a kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ẹni tí ó ràn wá lọ́wọ́ láti fi ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀ àti láti gbé ìgbé ayé olódodo. Ìyẹn kìí ṣe òjìji - bíkòṣe òtítọ́.
Títẹ̀lé òfin jẹ ìrìn-àjò lọ sínú ẹ̀bi. Títẹ̀lé Jésù jẹ́ ìrìn-àjò lọ sínú ore-ọ̀fẹ́. Ka Kólósè 2, kí o sì rí dájú pé ọkọ̀ rẹ ń lọ ní ọ̀nà tó tọ́.
Fún Àṣàrò ati Ìjíròrò
- Pọ́ọ̀lù sọ fún wa wípé kí a tẹ̀síwájú nínú Jésù, gẹ́gẹ́ bí a ṣe bẹ̀rẹ̀. Àwọn ewu àti ẹ̀tàn wo ni o rí tí ó lè ṣé ìdíwọ́ fún ọ láti tẹ̀lé Jésù?
- Báwo ni títẹ̀lé Jésù ṣe yàtọ̀ sí títẹ̀lé òfin? (Ka 2:16-17)
- Ṣé ìrírí rẹ bí o ṣe ń tẹ̀lé Jésù jọ ìrìn-àjò ẹ̀bi àbí ìrìn-àjò ore-ọ̀fẹ́? Jẹ́kí a gbọ́ ìtàn rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More