Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Ọjọ́ 14 | Kólósè 4
Ẹ ǹlẹ́ o ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi. Kólósè 4 lónìí, a sì padà sí ìpilẹ̀ṣẹ̀. Jésù kọ́ni ní òfin ìrọ̀rùn méjì: fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ohun tí o ní àti fẹ́ ọmọlàkejì bí ara rẹ. Àwọn kọ́kọ́rọ́ méjì yìí ni wọ́n ńtọ́ ìṣísẹ̀ kọ̀ọ̀kan bí a ti ń tẹ̀lé Jésù.
Orí 4 bẹ̀rẹ̀ níbití 3 parí sí: pẹ̀lú ìtọ́ni fún ìbájọṣepọ̀. Nítibí - àwọn ẹrú àti olúwa wọn. Ní báyìí o ní láti béèrè: ṣé Bíbélì f'ara mọ́ ìsìnrú ni? Ṣé ó gba àìdọ́gba, ẹlẹ́yàmẹ̀yà àti ìjẹgába láàyè?
Jẹ́ kí n ṣẹ́ ikàn lójú. Bẹ́ẹ̀kọ́. Bíbélì kò f'aramọ́ ìsìnrú, àti pé ẹnikẹ́ni tí ó bá fi Bíbélì gbe ìjẹgàba tàbí àìdọ́gba láàrin ènìyàn lẹ́sẹ̀ kàn ń ṣi ọ̀rọ̀ náà lò ni - sí ìtìjú ara wọn. Bíbélì bá àwọn ẹrú àti olúwa wọn wí nítorí pé òwò ẹrú wọ́pọ̀ nígbà yẹn, àti pé Pọ́ọ́lù ń fi ìlànà ìbájọgbépọ̀ nínú ayé lélẹ̀. Fún àwọn ẹrú, ó sọpé: ṣiṣẹ́ kára - bíi ìgbà wípé Ọlọ́run ní ò ń ṣiṣẹ́ fún nítorí pé Òun gan an ni olúwa rẹ nítòótọ́.
Àti ní orí 4:
“Ẹ̀yín olúwa, ẹ máa fi èyítí ó tọ́ tí ó sì dàgbà fún àwọn ẹrú yín, kí ẹ sì mọ̀ pé ẹ̀yin pẹ̀lú ní Olúwa kan ní ọ̀run.”
Níbí àti níbòmíràn Bíbélì rán ẹrú àti olúwa wọn létí pé bákannáà ni wọ́n rí ní òṣùwọ̀n ti Ọlọ́run, kò ní fi ṣe bí àwùjọ ṣe yà wọ́n s'ọ́tọ̀. Síbẹ̀, oó máa wòye ìdí rẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù kò ṣe fi àṣẹ Ọlọ́run pa ìkónilẹ́rú run.
Èyí ṣe pàtàkì. Jésú, nígbà àkọ́wá Rẹ̀ kò wá làti tún ìjọba ayé ṣe kí Ó mú u gún régé. Ó wá làti tún ọkàn wa ṣe, mú ọkàn wa gún régé pẹ̀lú Ọlọ́run. Ní ìpadàbọ̀ Rẹ̀ lékèejì, Jésù yíò fi ìdí ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀ nínú ayé, ṣùgbọ́n lákọ̀kọ́ Ó wá fi ìjọba Rẹ̀ kalẹ̀ nínú wa. Àkọ́kọ́: Ọba ọkàn rẹ. Èkejì: Ọba ayé.
Nítorí náà Pọ́ọ̀lù kọ́ wa làti ṣe ohun tó tọ́ nínú ayé tí kò tọ́. Ẹrú àti olúwa, òṣìṣẹ́ àti ọ̀gá iṣẹ́, ṣe ohun tó tọ́. Lẹ́yìnọ̀rẹyìn Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ẹrú pé kí wọ́n gba òmìnira wọn bí wọ́n bá lè ṣe, ìwé rẹ̀ sí Fílémónì sọ fún olúwa ẹrú kan pé kí ó dá ẹrú rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì pèé ní arákùnrin - gbólóhún ńlá ní àkókò yẹn.
Bí a bá wo sàkun ìtàn lọ, a ó ríi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akọni tí wọ́n jà tí wọ́n sì farajì làti pa òwò ẹrú run, a ru wọ́n sókè a sì gún wọn ní kẹ́ṣẹ́ sí èyí nípa ìgbàgbọ́ wọn nínú Bíbélì. Ọlọ́run yí ọkàn wọn padà, àwọn náà sì yí ayé wọn padà.
A padà sí Kólósè, ẹsẹ 2:
"Ẹ máa dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, kí ẹ sì máa ṣọ́ra nínú rẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́."
Èyí fún wa ní ìwà wa túntún tó kàn: àdúrà. Ka Bíbélì rẹ kí o sì gbàdúrà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Lẹ́ẹ̀kansii, kìí ṣe ohun tí a ti ṣe parí, ohun tí a ní làti máa ṣe ni. Àdúrà dàra gan an ni. A ní ààyè làti bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ - Ẹlẹ́dàá gbogbo àgbáyé - tààrà. Pọ́ọ̀lù sọ wípé "dúró ṣinṣin" nínú rẹ̀. Fí ṣe ààyò àkọ́kọ́.
Kíní o gbọ́dọ́ gbàdúrà nípa rẹ̀? Ohun gbogbo. Ohun tí o níílò, ohun tí ò ń dúpẹ́ fún, ohun tí ò ń rò tàbí tó rú ọ lójú tàbí ohun tí ò ń retí. Gbàdúrà fún àwọn ènìyàn. Gbàdúrà fún mi. Mo níílò rẹ̀. Gbàdúrà - nípa - ohun gbogbo.
Ronú nípa rẹ̀. Ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ṣe kókó nínú gbogbo ìbájọṣepọ̀. Nípa ọ̀rọ̀ sísọ ni bí a ṣe ń mọ ara wa. Ohun ńla nípa ìrìn-àjò àrínpapọ̀ ni àkókò láti sọ̀rọ̀, ká tú ọkàn ẹni palẹ̀, ká lọ jinlẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí a ṣe ń tẹ̀lé Jésú, à ń sọ̀rọ̀ lọ l'ọ́nà. Ọ̀rọ̀ dé ojú ọ̀gbagadì, a sọ nípa ìrètí àti ẹrù. A ṣí ìlẹ̀kún sílẹ̀ láti jẹ́ kí Jésù wọlé.
Rí àdúrà bíi bíbà ọ̀rẹ́ minú ẹni sọ̀rọ̀. Nígbàtí ó kù díẹ̀ káàtó, ó wà fún rírí ohun tí a fẹ́ gbà. Nígbàtí ó bá sì dùn, ó wà fún mímọ ara ẹni síi. Àdúrà kìí ṣe iṣẹ́ àmúrelé tàbí ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ tí a máa fún ní máàkì, nítorí náà, má ṣe àníyàn láti gbàdúrà "l'ọ́nà tó tọ́." Kàn ṣe é tọkàntọkàn. Lọ síwàjú ìtẹ́ Ọlọ́run tìrẹ̀lẹ̀ tìrẹ̀lẹ̀ àti tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ - Òun ni Ọlọ́run; ṣùgbọ́n lọ pẹ̀lú ìgboyà - Jésù ti ṣe ọ́ pé pẹ̀lú Ọlọ́run. Róòmù 12 sọ pé "dúró gangan nínú àdúrà" - bíi ìpè lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tí kìí já láilái.
Ní báyìí èyí tó kù nínú Kólósè jẹ́ ìkíni. Rántí, ìwé tí a kọ láàrin àwọn ènìyàn ẹlẹ́ran ara ni. Àwọn ènìyàn náà sì fẹ́ràn ara wọn! Nítorínáa wọn fi ìkíni ránṣẹ́. Mo fẹ́ràn èyí nípa Bíbélì. Ó wà fún olúkúlùkù. Ọlọ́run lè gbẹ́ ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tààrà s'ára òkúta, ṣùgbọ́n Ó yàn láti kọ́kọ́ kọ ọ́ sí ọkàn àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìfẹ́. Ìfẹ́ yìí sì hàn jáde lójú ewé ìwé náà.
Èyí tún mú wa wá sí ìwá kan sí i: ìdàpọ̀. Lo àsìkò pọ̀ pẹ̀lú àwọn Krìstíẹ́nì míràn. Ẹ jọ ṣàwárí ayé papọ̀. Fẹ́ Ọlọ́run and fẹ́ ọmọlàkejì. Hébérù kìlọ̀ fún wa pé kí á má kọ àpéjọpọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí Krìstíẹ́nì wa sílẹ̀ - ìyẹn ìjọ.
Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí a pè ní ìjọ nínú Bíbélì kìí ṣe ilé, àwọn ènìyàn tí wọ́n tẹ̀lé Jésù ní. Ìjọ lè pàdé nínú ilé, ṣùgbọ́n bí a kò bá ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ara wa ní ojúlówó ọ̀nà, a kùnà. Bí o tí ń ka orí 4, ṣe àkíyèsi àwọn orúkọ - àwọn tí wọ́n tara fún raawọn - Máàkù, Jústù,, Épáfrà, Lúùkù, Níḿfà, kí o sì ṣe àkíyèsi,
“...ìjọ tí ń bẹ ní ilé rẹ̀” (4:15).
Nígbà yẹn, awọn ìjọ màa ń pàdé lójúlé dé ojúlé - bíi ẹbí.
Ǹjẹ́, èyí ni kókó ibẹ̀: fẹ́ Ọlọ́run, fẹ́ ọmọlàkejì. Láti ṣe èyí, bẹ̀rẹ̀ ìwà àti gbàdúrà: mọ Ọlọ́run. Kí o sì bẹ̀rẹ̀ ìwà ìbádàpọ̀: kọ́ láti mọ àwọn ẹlòmíràn. Bóyá jí o ké sí ẹnìkan láti ibi iṣẹ́ tàbí ilé-ìwé láti ka ètò yìí pẹlú rẹ, kí ẹ jọ jíròrò lórí àwọn ìbéèrè ibẹ̀, kí ẹ sì jọ gbàdúrà papọ̀. Ìwà Bíbélí, ìwà àdúrà àti ìwà ìdàpọ̀ nì yẹn. Káàsà. Ìyén rọrùn gan an ni.
Ní báyìí bí o bá níílò ìrànlọ́wọ́ làti bẹ̀rẹ̀, a ó gbée yẹ̀wò l'ọ́la. Fún tòníi, ka Kólósè 4, má mú u le kankan: fẹ́ Ọlọ́run kí olúkúlùkù sì fẹ́ ọmọlàkejì rẹ̀.
Fún Àṣàrò & Ìjíròrò
- Kíni ìdí tí o rò pé àdúrà ṣe ṣe pàtàkì sí títẹ̀lé Jésú? Bàwo ni àdúrà ṣe ní ipa lórí ìrìn rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run?
- Kíni ìdí tí o rò pé ìdàpọ̀ ṣe ṣe pàtàkì sí títẹ̀lé Jésú? Bàwo ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú àwọn Krìstíẹ̀nì míràn ṣe ní ipa lórí ìrìn rẹ pẹ̀lú Ọlọ́run?
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More