Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Máàkù 1 | Tẹlé Mi
Ẹ ǹlẹ́ o, ẹ sì káàbọ̀ sí Bẹ̀rẹ̀. Bí ó bá jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bẹ̀rẹ̀ - tàbí bóyá o fẹ́ ṣe àtúnbẹ̀rẹ̀ - pẹ̀lú Jésù, tàbí o fẹ́ mọ̀ nípa ìgbàgbọ̀, ibi tó yẹ náà ló wà.
Níbo ni kí a ti wáá bẹ̀rẹ̀ báyìí o? Ó dáa, fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn, gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ méjì péré láti ọ̀dọ̀ Jésù, "Tẹ̀lé mi." Ìrìnàjò tó wà níwájú yíó yí ohun gbogbo padà.
Nítorí náà, ibẹ̀ gan an ni àwa náà yíó ti bẹ̀rẹ̀: títẹ̀lé Jésù. Ètò wa kò le rárá. A ó ka ìwé Bíbélì méjì. L'ákọ́kọ́, a ó tẹ̀lé ìtàn Jésù nínú Ìhìnrere Máàkù; léhìn náà a ó sọ nípa ìtàn wa nínú ìwé Kólósè. Nínú Máàkù a ó ríi ohun tí ó túmọ̀ sí láti tẹ̀lé Jésù l'áyé ìgbà yẹn, àti nínú Kólósè a ó rí ohun tí ó túmọ̀ sì láti tẹ̀lé E lónìí.
Ohun tí o ṣe pàtàkì jùlọ nínú ètò yìí ni Bíbélì kíkà, ṣùgbón màá wà pẹ̀lú rẹ níbí láti kín ọ lẹ̀hìn àti láti ṣe àlàyé bí a tí ń lọ. Ṣebí ká rìn ká pọ̀ yíyẹ níí yẹ ni. Késí ọ̀rẹ́ kan, ẹ ó sì mọ Jésù bí ẹ ṣe jọ ń mọ ara yín! O lè dáa ká fúnra rẹ, lẹ́hìn náà kí o kàn sí i láti jọ jíròrò l'ọ́jọ́kọ̀ọ̀kan tàbí - l'ọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Tàbí ó sì lè jẹ́ èmí àti ìwọ nìkan.
Óyá, jẹ́ ká bọ́ sí agbami rẹ̀. Lónìí, Máàkù 1, bẹ̀rẹ̀ láti ẹsẹ 1:
“Ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọ́run.”
Ìfáàrà àtàtà lèyí. Àkọ́kọ́, ìhìnrere ni, mo sì fẹ́ràn ìhìnrere. Ó wà nípa Jèsù, Mèsáyà náà. Mèsáyà túmọ̀ sí "ẹni àmì òróró” - gẹ́gẹ́ bí ẹni náà, àyànfẹ́ Ọlọ́run. Jésù sì ni Ọmọ Ọlọ́run.
Ẹsẹ 2 bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìsọtẹ́lẹ̀ láti àtẹ̀yìn wá:
“Mo rán ìránṣẹ́ mi ṣíwájú rẹ, ẹnití yíó tún ọ̀ná rẹ ṣe níwájú rẹ.”
Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ọkùnrin kan tí à ń pè ní Jòhánù, tí a rán láti wàásù àti láti pèsè ọkàn sílẹ̀ fún Jésù. Báwo ni ó ṣe pèsè wọn? Hẹẹn, ẹsẹ 4 sọpé ó wàásù “baptísmù ìrònúpìwàdà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.” Ìrònúpìwàdà ni kókó. Láti ronúpìwàdà ni láti pààrọ̀ ọkàn rẹ, láti pààrọ̀ ibi tí o dojúkọ. Kí o mọ̀ wípé, "Ohun tí mo ṣe kò dára,' léhìn náà kí o yípadà kúrò nínú rẹ̀ kí o sì tẹ̀lé ọ̀nà tuntun yánrányánrán. Nítorí náà, àwọn ènìyàn wá láti t'òsí àt'ọ̀nà jínjìn láti gbọ́ Jòhánù, láti ronúpìwàdà àti láti ṣe ìrìbọmi.
Kọkọ́rọ́ ibẹ̀ nìyìí. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú títẹ̀lé Jésù ní ìyípadà ibi tí a dojúkọ. Jẹ́wọ́ àṣìṣe tóo ṣe, yípadà kúrò nínú rẹ̀, kí o sì kọjú sí Jésù. Jòhánù fi omi ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bíi àmì ìrònúpìwàdà, ṣùgbọ́n ó tún sọ fún wọn pé Jésù ń bọ̀ "tí yíó baptísí yín pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.”
Léhìn náà, ní ẹsẹ 9, Jésù wá láti Násárẹ́tì, Jòhánù sì ṣe ìrìbọmi fún Un. Ṣùgbọ́n ìrìbọmi ti Jésù yàtọ̀. Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ lé E lórí bí àdàbà, áti ní ẹsẹ 11:
“Ohùn kan sì ti ọ̀run wá, wípé, Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹnití inú mi dùn sí gidigidi.’”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹkan ló wà láti rí níbí, ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí o kàá fúnra rẹ. Bí a ṣe ń ṣeé nìyẹn. Èmi á ṣe kòkáárí rẹ̀, lẹ́hìn náà, ìwọ á kàá ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Ẹsẹ 14:
“Lẹ́hìn ìgbàtí a fi Jòhánù sínú túbú tàn, Jésù lọ sí Gálílì, Ó ń wàású ìhìnrere ìjọba Ọlọ́run. Ó sì ńwípé ‘Akokò na de,’. ‘ijọba Ọlọ́run sì kù sí dẹ̀dẹ̀: ẹ ronúpìwàdà, kì ẹ sì gbà ìhìnrere gbọ́!’”
Jésù wá pẹ̀lú iṣẹ́ kan: Ìjọba Ọlọ́run - ibi tí Ọlọ́run ti ń darí bí Ọba - ti súnmọ́ tòsí. Ó ti dé tán, ó wà ní ìtòsí. Ó sì pe àwọn ènìyàn láti ronúpìwàdà - kí wọn yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ - kí wọ́n sì gba ìhìnrere gbọ́.
Ṣùgbón bí ìjọba náà bá ti súnmọ́ ìtòsí, bàwo ni wọn ó ṣe dé bẹ̀? Ẹsẹ 16:
“Bí Jésù sì ti ńrìn létí òkun Gálílì, Ó rí Símónì àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀, wọ́n ńsọ àwọ̀n sínú òkun: nítorítí wọn ṣe apẹja. Jésù wípé, ‘Ẹ wá, ẹ tẹ̀lé mi, Èmi yíó sì sọ yín di apẹja ènìyàn.’”
Ṣe àkíyèsí. Kókó ohun tí ó ń gbé ní dé Ìjọba Ọlọ́run wà nínú ọ̀rọ̀ kékeré méjì yìí: tẹ̀lé Jésù.
Ẹsẹ 18:
“Lójúkan náà wọ́n sì fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́hìn.”
Ṣ'àkíyèsí pé wọ́n ní láti fi ǹkan sílẹ̀ kí wọ́n tó lè tẹlé E. Jésù tésíwájú Ó sì rí Jákọ́bù àti Jòhánù (ọ̀tọ̀ ni Jòhánù yìí), àwọn náà fi ohun tí wọ́n ní sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀lé Jésù.
Mo máá ń wòye l'ọ́pọ̀ ìgbà bóyá àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mọ̀ pé ayé àwọn tí fẹ́ẹ́ yí padà, tábí pé gbogbo ayé ni yíó yípadà. Mi ò mọ bí ó ṣe yé wọn sí, ṣùgbọ̀n wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Jésù tó bẹ́ẹ̀ láti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́.
Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká darapọ̀ mọ́ wọn. Ka Máàkù 1. Fojú sí àṣẹ Jésù bí Ó ṣe ń lé àwọn ẹ̀mí èsù jáde. F'ara kín àánú Rẹ̀ bí Ó ṣe ń wo aláìsàn sàn. F'etí sí ọgbọ́n Rẹ̀ bí Ó ṣe ń kọ́ ni. Bí o sì ti ń kàá, ní òye pé Jésù kò pé wá láti kàn gba àwọn ọ̀rọ̀ kan lásán gbọ́ tàbí láti jíròrò lórí àwọn ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kan ṣáá. Kò sì pè wá láti wá darapọ̀ mọ́ egbẹ́. Ó pè wá láti darapọ̀ mọ̀ ìrìnàjò Òun. Ó pè wá kí a tẹ̀lé Òun.
Fún Àṣàrò àti Ìjíròrò:
- Kíni o rò pé Jésù ní l'ọ́kàn nígbàtí Ó sọ pé, “Tẹ̀lé mi”? Báwo ni èyí ṣe yàtọ̀ sí sísọ pé “t'ẹ́tí sí mi” tàbí “gbà mí gbọ́”?
- Èwo nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni o rò pé ó ṣ'àpẹẹrẹ jíjẹ́ Krìstíẹ̀nì jù: ẹ̀sìn, ìgbàgbọ́, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, òfin, ìrìnàjò, ìbájọṣepọ̀? Kíni ìdí rẹ̀?
- Báwo ni o ṣe mọ̀ nípa Jésù? Ṣe alábàápín ìtàn rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More