Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Máàkù 2-3 | A d'áríjì í & A yàn án
Ẹ káàbọ̀ padà sí Bẹ̀rẹ̀. A wà ní Máàkù 2 lónìí, pẹ̀lú ọ̀kan nínú àwọn ìtàn tí mo fẹ́ràn jù. Nínú Bíbélì, Jésù lérí ọ̀rọ̀ ńlá kan - ó nínlá tóbẹ́ẹ̀ tó ohun tó lè ṣ'ekú pa Á. Ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ló lè léríléka ohun tí kò jẹ́. Ìbéèrè ibẹ̀ ni wípé - ṣé Jésù f'ẹsẹ̀ rẹ̀ múlẹ̀? Ní Máàkù 2, a rí Jésù ń kọ́ ni nínú ilé ní Kápánáómù, òkìkí sì kàn jáde. Ẹsẹ 2:
“Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì péjọ tóbẹ́ẹ̀ tí kò sí àyè fún wọn mọ́, kò sí, títí dé ẹnu-ọ̀nà: Ó sí wàásù ọ̀rọ̀ náà fún wọn.”
Nítorí náà èrò ńlá péjọ, Jésù ṣì ń wàásù Ọ̀rọ̀ náà - ìyẹn Bíbélì. Gbogbo ìgbà ni Jèsù maá ń gbá'jú mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó tún maá ń ṣiṣẹ́ ìyanu, ṣùgbọ́n Jésù pe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn ní àmì, àti ìtọ́nisọ́nà sí ohun míràn. Àpẹ̀ẹ̀rẹ̀ pípé ni ìtàn tònìí. Ẹsẹ 3:
“Àwọn ọkùnrin kan sì wá sọ́dọ̀ Rẹ̀, wọ́n gbé ẹnìkan tí ó ní àrùn ẹ̀gbà tọ̀ Ọ́ wá, ẹnitì ẹni mẹ́rin gbé. Nígbàtí wọn kò sì lè súnmọ́ Ọ nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n sì ṣí òrùlé ilé níbití Ó gbé wà: nígbàtí wọ́n sì dá a lu tán, wọ́n sọ́ àkéte náà kalẹ̀ lórí èyítí ẹlẹ́gbà náà dùbúlẹ̀. Nígbàtí Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, 'Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
Dúró ná. Tún tún un gbọ́. Ṣé ohun tó sọ ni pé, “A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́?” Ọkùnrin yìí wá fún ìmúláradá, kìí ṣe ìdáríjì. Ṣùgbọ́n Jésù mọ ǹkankan: kò sí ohun náà tó tóbi tó ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdáríjì ní ayé yìí. Wo ohun tó ṣelẹ̀ lẹ́hìn èyí. Àwọn kan nínú akọ̀wé Júù wà níbẹ̀, ẹnu sì yà wọ́n.
“Èéṣe tí ọkùnrin yìí fi sọ̀rọ̀ báyìí? Ó ńsọ ọ̀rọ̀-òdì! Taaní lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bíkòṣe ẹnìkan, àní Ọlọ́run?” (Máàkù 2:7).
Nípa ohun tí wọ́n sọ kẹ́hìn yẹn, òótọ́ ni. Ẹní bá sọ pé òun ní agbára láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni ti sọ pé òun ní àṣẹ tí Ọlọ́run ní. Bí kìí báá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀-òdì l'èyí - ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì sì ni. Jésù mọ èrò wọn, nítorí náà Ó béèrè ìbéèrè kan. Ẹsẹ 9:
“Èwo ni ó yá jù láti wí: fún ẹlẹ́gbà náà pé, A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,' tàbí láti wípé, 'Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn'?”
Mo fẹ́ràn ìbéèrè yìí. Ronú nípa rẹ̀. Èwo ni ó rọrún láti sọ?“A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ.” Ìyẹn rọrún láti sọ nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ríi. Ṣùgbọ́n ó ṣòro láti ṣe! Ọlọ́run nìkan ló lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni! Ṣùgbọ́n láti sọ fún ẹlẹ́gbà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn” - ìyẹn d'ójú sọ' ni. Gbogbo ènìyàn ló ń wò ó.Nítorí náà ní ẹsẹ 'kẹwàá Jésù tẹ̀síwájú,
“‘Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni.' Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, ‘Mo wí fún ọ, Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.’ Ó sì dìde lójúkannáà, ó sì gbé àkéte náà, ó sì jáde lọ ní ojú gbogbo wọn; tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnu fi ya gbogbo wọn.”
Ìyanu yìí wàyàmì: alárùn ẹ̀gbà rìn! Ṣùgbọ̀n máṣe f'ojú fo àmì, ó tọ́ka sí àṣẹ Jésù. Jésù ní àṣẹ Ọlọ́run láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni, Ó sì f'ìdí rẹ̀ múlẹ̀. Ó tún lòó nínú ìtàn tó tẹ̀lé e. Ní ẹsẹ 13, Jésù ń kọ́ ni l'ẹ́gbẹ̀ẹ́ adágún, Ó sì rí Léfì tí ó ń ṣe agbowó-òde. Nígbà yẹn, àwọn agbowó-òde kò já mọ́ ńkan lójú àwọn ènìyàn, àwọn jẹgúdújẹrá tí wọ́n maá ń pa owó ìjọba m'ọ́ka ni wọ́n. Olójúkòkòrò burúkú. Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Jésù lọ bá Léfì,
Jésù wí fún un pé “‘Tẹ̀lé mi,’ Léfì sì dìde, ó sì tẹ̀lé E” (2:14).
Ọ̀rọ̀ yẹn tún rèé o, ìpè kannáà. Sùgbọ́n nísìnyìí Jésù pe ẹlẹ́ṣẹ̀ - ènìyàn burúkú paraku. Léfì sì tẹ̀lé E! Nígbàtí Léfì sí pe Jèsù àti àwọn ọmọ-ẹ̀hìn sí ibi àsè, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tún pọ̀ níbẹ̀. Ní báyìí, èyí ṣòro jù fún àwọn Farisí láti f'òye gbé. Àwọn Farisí jẹ́ adarí-ẹ̀sìn - àwọn adánilẹ́jọ̀ àti olódodo-araẹni - tí òye kò yé rárá. Bí Jèsù bá jẹ́ olùkọ́ni rere,
“Kílódé tí Ó ńjẹun pẹ̀lú àwọn agbowó-òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀?” (2:16).
Ẹsẹ 17 jẹ́ gbólóhùn tó lágbára gan:
“Nígbàtí Jésù gbọ́, Ó wí fún wọn pé, 'Àwọn tí ara wọn le kìí wá oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti pè àwọn olódodo, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.’”
Má f'ojú fo èyí. Jésù yan àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀. Léfì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Bí oníṣègùn ṣe ń wá láti wo aláìsàn sàn, Jésù wá láti d'áríjì ẹlẹ́ṣẹ̀ àti láti mú wọn padà bọ̀ sípò - láti sọ wọ́n di olódodo. Òdodo túmọ̀ sí wíwà ní déédé pẹ̀lú Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ pàtàkì ni èyí. Ṣé o mọ bí ó ṣe ńrí bí àárín ẹni méjí bá gún - nígbàtí kò bá sí ìkùnsínú kankan láàrin yín? O sì tún mọ bí ó ṣe maá ń rí nígbàtí àárín ènìyàn kò bá gún - tó dàbí pé odi kan wà láàrin èyìn méjèèji nítorípé oò ṣe dáadáa. Ẹ̀h ẹ́n, bó ṣe rí láàrin àwa àti Ọlọ́run nìyẹn. Ẹ̀ṣẹ̀ yà wá nìpa. A ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n ìhìnrere - ìròyìn ayọ̀ ńlá - ni pé Jésù wá láti mú wa ṣe déédéé padà. Ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì, Ó pè wá ní olódodo. Ohun tí Ó bèèrè lọ́wọ́ wa ni ìgbàgbọ́. Òdodo nípa ìgbàgbọ́. Èyí tó tún ya'ni l'ẹ́nu jù ni pé, Jésù yan ẹlẹ́ṣẹ̀, Ó mu wọ́n wà déédéé, Ó sì rán wọn lọ láti sin Ọlọ́run. Ní orí 3, a kà bí Jésù ṣe pe àwọn méjìlá fún ara Rẹ̀, tí Ó sì yàn wọ́n láti jẹ́ àpóstélì. Ọmọ-ẹ̀hìn ń tẹ̀lé E, àpóstélì ni a rán - bíi ikọ̀ aṣojú. Nínú àwọn méjìlá yẹn ni Léfì wà, kìkìi pé orúkọ rẹ̀ yípadà sí Mátíù. Jésù yan àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, Ó dáríjì wọ́n, wò wọ́n ṣàn, yí wọn padà, Ó sì rán wọn lọ láti sọ ìròyìn ayọ̀ náà fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ míràn pé: Ọlọ́run fẹ́ràn rẹ. Ìyàlẹ́nu ńlá. Ó sì tún fẹ́ wa bẹ́ẹ̀ lónìí. Ka Máàkù 2 àti 3 lónìí. Bí ààyè rẹ̀ bá wà, f'ọwọ́ tọ́ “Ka gbogbo Orí bíbélì” láti mọ gbogbo ìtàn náà. A ó sì tún jọ pàdé ní orí 4.
Fún Àṣàrò & Ìjíròrò:
- Kíni ìdí rẹ̀ tí o rò pé ó fi ṣòro fún àwọn olórí-ẹ̀sìn láti gbà pé Jésù bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jeun pọ̀?
- Jésù pe èdè alágbára kan ní 2:17, “Àwọn tí ara wọ́n le kìí wá oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti pe àwọn olódodo, bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.” Kíni eléyìí túmọ̀ sí fún ọ?
- Ipa wo ni ìdáríjì ti kó nínú ayé rẹ? Sọ ìtàn rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More