Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Máàkù 4-5 | Irúgbìn Rere & Ilẹ́ Rere
Jésù jẹ́ òǹpìtàn tó ga lọ́lá. Ní Máàkù 4 àti 5, Jésù pa òwe - ìtàn tí ń kọ́ 'ni l'ẹ́kọ̀ọ́. Òwe àkọ́kọ́ Jésù yíó ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè méjì pàtàkì: kíni Bíbélì àti pé kíni ìdí rẹ̀ tí a fi gbọ́dọ̀ kàá?
Jẹ́ kí á bẹ̀rẹ̀ ní Máàkù 4, ẹsẹ 3:
“‘Ẹ fi etí sílẹ̀; Wò ó, afúnrúgbìn kan jáde lọ fúnrúgbìn. Ó sì ṣe, bí ó ti ńfúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì ṣà á jẹ. Díẹ̀ sì bọ́ s'órí ilẹ̀ àpáta, níbití kò ní erùpẹ̀ púpọ̀. Lójúkannáà, ó sì hù jáde, nítorítí kò ní ìjìnlẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbàtí òòrùn gòkè, ó jóná; nítorítí kò ní gbòngbò, ó gbẹ. Díẹ̀ sì bọ́ sáàrín ẹ̀gún, nígbàtí ẹ̀gún sì dàgbà sókè, ó fún un pa, kò sì so èso. Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, tí ó ńdàgbà tí ó sì ńpọ̀, ó sì mú èso wá, òmíràn ọgbọgbọ̀n, òmíràn ọgọ́tọ̀ta, òmíràn ọgọrọ̀rún.’
Nígbànáà ni Jésù wí pé, 'Ẹnití ó bá l'étí láti fi gbọ́, ki o gbọ́.’”
Nítorí náà, ìtàn iṣẹ́ afúrúgbìn ni. Afúrúgbìn kan ń gbin irúgbìn; àwọn irúgbìn kan hù àwọn òmíràn kò sì hù, látàrí ilẹ̀ tí wọ́n wà. Kò fi taratara wú ni l'órí, ṣùgbọ́n Jésù fún wa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìtàn yìí ní ẹsẹ 14:
“Afúrúgbìn ńfúrúgbìn ọ̀rọ̀.”
Ní Lúùkù 8 Jésù wípé:
“Irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” (Lúùkù 8:11).
Nítorí náà Jésù fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé irúgbìn. Ronú nípa irúgbìn. Wọn kò wu ojú rí. Èso dùn ún wò ní tirẹ̀. Ṣùgbọ́n irúgbìn inú rẹ̀, kíní kékeré kínkín yẹn, ní nínú rẹ̀ gbogbo àbùdá àti ohun ìmúdàgbà tó lè di igbó kìjikìji, ohun ọ̀gbìn tàbí igi - láti gbòǹgbò dé ẹ̀ka dé èso - gbogbo rẹ̀ ti inú ilẹ̀ wá. Irúgbìn jẹ́ ohun àrà: o bò ó m'ọ́lẹ̀ ó sì mú ìyè jáde.
Jésù sì sọ fún wa: ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ irúgbìn. Ó lè má j'ọjú, ṣùgbọ́n ìlànà ìgbé-ayé wà nínú rẹ̀. Ohun tí ó níílò ni ilẹ̀ rere.
Bíbélì ju ìwé lásán lọ. Ó ní orí 66. Ṣùgbọ́n ju gbogbo ìyẹn lọ, Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tímótìu Kejì wí pé,
“Gbogbo ìwé-mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run” (2 Tim 3:16).
Èyí túmọ̀ sí pé Bíbélì pé ara rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Nítorí náà bí Ọ̀rọ̀ náà bá jẹ́ irúgbìn, kíni ilẹ̀? Èyí mú wa padà wá sí òwe náà.
Jésù ṣe àlàyé pé ilẹ̀ ni àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Ilẹ̀ ni ìwọ àti èmi. Òun ni ọkàn wa, oríṣi ilẹ̀ mẹ́rin ló sì wà - àti ọkàn mẹ́rin bí a bá ń sọ nípa gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
Àwọn ọkàn kan le koko bíi òpópónà tí ọ̀dà dùn. Ọ̀rọ̀ náà bà á ṣùgbọ́n kò wọlé. Àwọn ọkàn míràn dàbíi ilẹ̀ àpáta. Ìlẹ̀dúdíẹ̀ ló wá níbẹ̀, irúgbìn náà dàgbà díẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní gbòǹgbò. Nígbàtí wàhálà dé, wọn kọ ìgbàgbọ́ sílẹ̀. Àwọn ọkàn kan sì dàbíi ilẹ̀ ẹ̀gún àti koríko, tí afẹ́ àti àníyàn ayé ti gba ọkàn wọn kan, tí kò sí ààyè fún ìgbàgbọ́ láti dàgbà. Àmọ́ ṣá, àwọn ọkàn kan wà tó jẹ́ pé… Ọin, ṣe o ti rí ilẹ̀ tó jẹ́ àsán ìdọ̀tí tí a sọ́ dí ọgbà ri? Àrágbá yamúyamù.
Ní báyìí báwo ni o ṣe lè rí i dájú pé ọkàn rẹ jẹ́ irú èyí tí ń dàgbà? Làti ṣ'àwárí èyí, ka Máàkù 4. Rántí o, agbára ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kìí ṣe ti t'èmi. Mo wà níbí làti jẹ́ kí o bẹ̀rẹ̀ ni, ṣùgbọ́n àfojúsùn mi gan an ni kí o ṣi Bíbélì kí o sì kà á fúnraàrẹ.
Ìrètí mí fún ọ ní kí o ní ìwà kíka Bíbélì lóòrèkóòrè. Èyí kó ipa pàtàkì nínú títẹ̀lé Jésù. Ka Bíbélì lójoojúmọ́. Gbin irúgbìn rere sí ilẹ̀ rere kí o sì so èso rere.
Nítorí náà ka Máàkù 4 àti 5, kí o sì ronú nípa irú ilẹ̀ tí o fẹ́ jẹ́. Tí ààyè bá gbà ọ́, ka gbogbo orí Bíbélì náà kí o sì tẹ̀lé Jésù bí Ó ti ń sọ àwọn ìtàn àgbààyanu. Kí o sì wo bí Ó ti bá rírú omi òkun ńlá wí tí ó sì dákẹ́jẹ́, bí Ó ti ké àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, wọ aláìsàn sàn, tí Ó sì tún pe òkú wá sí ayé. Gbogbo èyí sì rèé, nípa agbára ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ni. Bí ọ̀rọ̀ Jésù bá lè ṣe gbogbo èyí, ìwọ kàn wòye ohun tí ó lè ṣe l'áyé rẹ. Ohun tí o kàn nílò - ni ilẹ̀ rere.
Fún Àṣàrò àti Ìjíròrò:
- Kíni o rò pé ó jẹ́ ìdí rẹ̀ tí Jésù ṣe fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé irúgbìn? Kíni wọ́n fi j'ọra?
- Bí ilẹ̀ bá dúró fún ọkàn rẹ, kíni o lè ṣe tí làti rí i pé a gbin Ọ̀rọ̀ náà sí ilẹ̀ rere tí ó ní ààyè làti dàgbà àti làti so èso?
- Ọ̀nà wo ní o tí rí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti bá ayé rẹ tàbí ti àwọn ènìyàn l'áyé rẹ wí? Sọ ìtàn rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More