Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Máàkù 14-15 | Àgbélébùú
Ẹ káàbọ̀ padà, ẹ̀yin ọ̀rẹ́. Lónìí ìrìn àjò wa mú wa wá sí Máàkù 14 sí arin gbùngbùn ìkòríta ìtàn àkọọ́lẹ̀. Àwọn èrò tó wà ní Jerúsálẹ́mù ń pọ̀ síi bí ọjọ́ àsè ṣe ń sún mọ́. Ìdìtẹ̀ kan rú bọ̀ láàrin àwọn olórí Júù - ọ̀tẹ̀ láti pa Jésù. Bí ọ̀tẹ̀ yii ṣe ńru sókè, Jésù kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ sápá kan láti jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú Rẹ̀ ní yàrá òkè.
Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ti jókòó jẹun níbi àsè, Jésù làá fún wọn pé ọ̀kan nínú wọn yóò dalẹ̀ Rẹ̀. Ìdàlẹ̀ jẹ́ ọgbẹ́ tó jìn, Jésù sì mọ̀ yí dájú. Níbáyìí, Júdásì jókòó pẹ̀lú Jésù bí ọ̀rẹ́. Nínú ẹsẹ̀ 22,
"Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.” Lẹ́yìn èyí ago wáìnì, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”
À ń pè ní Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, àwọn Krìstẹ́nì ma ń bu ọlá fún ìsìn yìí jákèjádò gbogbo ayé títí d'òní, àkàrà dúró fún ara Kríístì tí a lù lórí àgbélébùú, pẹ̀lú ọtí wáìnì láti rántí ẹ̀jẹ̀ Jésù. Jésù Ṣe àgbékalẹ̀ májẹ̀mú tuntun - ìbáṣepọ̀ tuntun láàrin Ọlọ́run àti ènìyàn - nínú ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀. Ìfi ohun wé tó jinlẹ̀ pẹ̀lú ìtumọ̀ ni èyí tí a rí yìí, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti tó láti rántí Jésù.
Alẹ́ náà ń tẹ̀síwájú. Júdásì jáde lọ pẹ̀lú ibi lọ́kàn rẹ̀. Wọ́n jẹun tán, Jésù gbàdúrà, Ó sì kó wọn lọ sí ọgbà kan ní tòsí tí à ń pè ní Gethsemane.
Ò ti di àárín òru báyìí, sugbon òṣùpá tó là rokoso tan ìmọ́lẹ̀ sí òkùnkùn tó ṣú. Jésù mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́ta sọ́tọ̀, Ó fi'nú hàn wọ́n,
“ọkàn mi ń káàánú gidigidi títí dé ojú ikú.”
Ó bèèrè kí wọ́n gbàdúrà, lẹ́yìn èyí Òun nìkan ní àkókò láti gbàdúrà, Ó sì bèèrè lọ́wọ́ Baba “bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré” òun kọjá.
Ó padà láti bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ́n n sùn. Ó jí wọn, Ó sì tún padà láti gbàdúrà. Ó padà wá. Wọ́n tún ti sùn. Ṣùgbọ́n báyìí àkókò tí pé, Júdásì ti padà dé pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun. Ìdàlẹ̀ yìí ti pé. Wọ́n mú Jésù lọ sí ìgbẹjọ́ níwájú Olórí Àlùfáà.
Ó ti di ọjọ́ ẹtì báyìí, ó kù dí è kí oòrùn yọ. Jésù dúró níwájú Káyáfà, olorí àlùfáà. Nínú ẹsẹ̀ 56:
“Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ́n ní kò bá ara wọn mu.”
Ẹ̀sùn ọ̀kanòjọkàn ń fò kiri, sugbon ni ese 61,
"Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́. Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?” Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni."
Fún ìdí èyí, ìdí yìí nìkan ṣoṣo, Olórí Àlùfáà dá Jésù lẹ́bi ọ̀rọ̀ òdì - fún ẹni tí Ó sọ pé Òun jẹ́.
Fún ìdí èyí àwọn olórí Júù de Jésù wọ́n sì sìn lọ sí ọ̀dọ̀ gómìnà Róòmù, Pọntù Pílátù. Máàkù 15, verse 2:
"Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?" Pílátù bèrè.
'Jesu sì dáhùn pé, “gẹ́gẹ́ bi ìwọ ti wí náà ni."
Lẹ́ẹ̀kan sí a tún di ẹ̀bi lóríṣiríṣi ru Jésù, ṣùgbọ́n kò dá f'èsì. Nínú gbogbo, Ó kàn dá wọn lóhùn ìbéèrè nípa Ẹnití Ó jẹ́. Èyí ni ohun tí ó ṣe kókó jùlọ.
Àwọn ẹ̀sùn yí kò múná d'óko, Pílátù sì kọ̀ láti dá aláìṣẹ̀ lẹ́bi. Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà ń rúgbó ọ̀tẹ̀. Nínú ẹsẹ̀ 12,
“Kí ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi kí ó ṣe pẹ̀lú ẹni ti ẹ̀yin n pè ní ọba àwọn Júù?..."
"“Kàn án mọ àgbélébùú!..."
“Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?..."
Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”
Pílátù gbà sí wọn lẹ́nu. Wọ́n lu Jésù ní ìlù ki'lù, wọ́n sì sì ń lọ sí ààfin pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n fi ṣe ẹlẹ́yà pẹ̀lú adé ẹ̀gún, aṣọ àwọ̀lékè, àti lílù pẹ̀lú tí tu'tọ́ sí lára. Jésù fi hàn Ẹni tí Òun jẹ́, ó sì yé àwọn ẹ̀ṣọ́ gedegbe èrò wọn sí I.
Wọ́n parí ìfi ṣẹ̀sín irúfẹ́ àwọn aṣebiyọ̀, wọ́n mú Jésù jáde lọ sí Gọ́lgọ́tà. Ní ẹsẹ̀ 24:
"...24 Wọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù. Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú.
Kí kán mọ́ àgbélébùú je is a eri si ailojuti ninu iwa ika omo eniyan. Ó jẹ́ ìjìyà tí kò bójú mu fún ìrúfin, àwọn alákòóso Róòmù a sì ma fẹ́ kí gbogbo ènìyàn mọ̀ ní pàtó ìdí tí a fi kan ẹnikẹ́ni mọ́ àgbélébùú. Nítorínáà wọ́n fi àkọlé “ìrúfin” Rẹ̀ Ẹ̀sùn Rẹ̀ kà báyìí: “Ọba àwọn Júù.”
Wákàtí mẹ́ta kọjá nínú ìrora tí kò rọgbọ. Nínú ẹsẹ̀ 33:
“Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán."
Gbé ìgbésẹ̀ wọnú ìtàn àkọsílẹ̀ fún ìgbà dí ẹ̀, kí o sì dúró nínú òkùnkùn. Gbọ́ ìró àwọn apẹ̀gàn, àwọn obìnrin tí wọ́n ń sọkún, àti ọkàn òkú ìgboyà àwọn ẹ̀ṣọ́. Níwájú rẹ ọkùnrin tí a gbé kọ́ sórí igi. Àkọlé tí ó wà ní orí Rẹ̀ kà báyìí, “Ọba àwọn Júù.”
Tani ọkùnrin yìí?
Bí o ti dúró ti o sì ń wòye, ẹsẹ̀ 37:
“Jesu sì tún kígbe sókè ni ohùn rara, ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́. Aṣọ ìkélé tẹmpili sì fàya sí méjì láti òkè dé ìsàlẹ̀. Nígbà tí balógun ọ̀rún tí ó dúró lẹ́gbẹ̀ ọ̀dọ̀ Jesu rí i tí ó kígbe sókè báyìí, tí ó sì jọ̀wọ́ èmí rẹ̀ lọ́wọ́, ó wí pé, “Lóòótọ́ Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí í ṣe!”
Ó ti paríbáyìí. Ọ̀gágun ọrún kan ni Pílátù rán láti jẹ̀rísí wípé Ó ti kú pẹ̀lú ọkọ̀ ni egbe Rẹ̀. Ẹni yòówù kó jẹ́, Ó ti ku bayii. Bí o ti rìn kọjá, kúrọ̀ níbẹ̀, àlejò kán dá ọ dúró. “Tani ìwọ ròpé Ó jẹ́?”
Kí lẹ́yìn wí? Tani Jésù?
Fún Àṣàrò ati Ìjíròrò
- Níbí, kí ni o mú ọ ròpé Jésù Yóò fẹ́ dáhùn àwọn ìbéèrè nìpa tani Ó jẹ́? Kí ló ṣe tí ẹ lèyìí fi ṣe pàtàkí?
- Kíni ìkàn mọ́`gi Jésù túmọ̀ sí fún ọ? Se alabapín ìtàn rẹ.
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More