Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Kólósè 1:19-2:5 | kà á
Ẹ káàbọ̀ padà gbogbo ènìyàn. Lónìí a sọ̀rọ̀ nìpa Bíbélì àti pàtàkì kìka Bíbélì lórèkórè fún ìlera pípé. Bíbélì ni ọ̀nà tí Ọlọ́run ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀, áti pé kíka Bíbélì jẹ́ bí a ṣe ń dúró ní ọ̀nà tó tọ́ tí a sì ń tẹ̀lé Jésù tòótọ́. Ó ṣeé ṣe kí o ti pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n sọ pé wọ́n kò tẹ̀lé Jésù, ṣùgbọ́n ìgbésí ayé wọn kò jọra. O ń ṣẹlẹ̀ púpọ̀. Nítorínà báwo ni a se ṣeé ní ọ̀nà tó tọ́?
Bíbélì ni kọ́kọ́rọ́. Mo mọ̀ wípé wàá ti ṣàkíyèsí pé gbogbo ìrìn-àjo yìí ní ìpìlẹ nínú Bíbélì. Bíbélì jẹ́ ìyanu. Àwọn ìtàn tó fakoyo, akọni àràọ̀tọ̀, ọgbọ́n tí ó jinlẹ̀, àti ìtọ́sọ́nà tí ó lágbára fún àti gbé inú ayé. Ó tún kù síbẹ̀. Bíbélì ná ni ó mú wa ní ìpìlẹ̀. Ó fún wa ní ìdákọ̀ró òtítọ́ nínú ayé rúdurùdu. Oríṣiríṣi iró ni ó pọ̀ ní ínú ayé, kódà kò yọ irọ nípa Jésù sílẹ̀ - àti wípé Bíbélì ni ó má mú wa rìn nínú òtítọ́ àti láti tèlé Jéṣù tó Ún ṣe òtítọ́.
Báyìí ẹ jẹ́ kí á darí padà. A parí sí inú ìwé Kólósè 1 pẹ̀lú ìrántí tí ó lágbára nípa ẹnití Jésù jẹ́. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀síwájú láti ẹsẹ 19:
"Nítorí pé inú Ọlọ́run dùn púpọ̀ láti jẹ́ kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ma gbé ínú rẹ̀ (Jésù), àti wípé nípasẹ̀ rẹ̀ ni àtúnṣe láti bá ara rẹ̀ rẹ́ nínú ohun gbogbo ìkan."
Èyí ní agbára. ẹ̀kún Ọlọ́run wá ninu Jésù. Àti wípé nípa Jésù ni a di ẹni ìlàjà. Ìlàjà túmọ̀ sí ìbásepọ̀ tí kò dára tí a mú dára. A se àtúnṣe àlááfià pẹ̀lú Ọlọ́run...
..."Nípa ẹ̀jẹ̀ tí ó taa sílè ní orí igi àgbélébùú" (1:20).
Jésù ṣe wá yẹ pẹ̀lú Ọlọ́run bákannáà Paulu fẹ́ wípé kí á dúró déédé pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí náà ó gbà wá ní yànjú...
"...Ẹ máa bá a lọ nínú ìgbàgbọ yín, ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ẹ sì dúró ṣinṣin, kí ẹ má sì ṣe kúrò nínú ìrètí tí a gbé kalẹ̀ nínú ìyìn rere" (1:23).
Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ẹ̀kọ́ èké nípa Jésù ti kọlu ìjọ Kólósè. Àwọn ẹlẹ́tàn wọlé. Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé láti mú kí ìjọ dúró nínú òtítọ́. Ni ẹsẹ 25 o sọ wipe,
"Mo ti di ìránṣẹ́ rẹ̀ nípasẹ̀ àṣẹ tí Ọlọ́run fún mi láti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀".
Ọlọ́run fún Pọ́ọ̀lù níṣẹ́ láti sin ìjọ nípa kíkọ́ni ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìyẹn túmọ sí gbogbo Bíbélì. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn olùkọ́ èké máa ń tọ́ka sí Bíbélì, àmọ́ ẹsẹ̀ kan ni wọ́n máa ń mú lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún, wọ́n sì máa ń yí wọ́n padà sẹ́yìn. Nítorínà ka Bíbélì fún arà rẹ - yíò pa ọ́ mọ nínú òtítọ́ àti kúrò nínú irọ́.
Báyì tí o bá ní ìṣòro làti mọ oun tí Bíbélì ń wí, nítorí nàa ni a fi ní àwọn olùkọ rere. Ọlọ́run fún wa ní olùkọ́ láti ṣàlàyé Bíbélì àti bí a ti lè lòó. Ṣùgbọn olùkọ kọ́ yẹ kí ó rọpò Bíbélì - kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀ nìkan ni.
Padá sí inú Kólóssè, àwọn olùkọ èké sọ pé ọ̀títọ kún fún àwọn ohun ìjìnlẹ̀ tí o kò le lòye. Nítorínáà Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run ti tú àṣírí náà payá - Ó ti sọ ọ́ di mí mọ̀ fún wa. Nínú ẹsẹ 27, ohun ìjìnlẹ yẹn ní ń
"...se Krístí nínú mi ìrètí ògo."
Àsírí gidi nìyẹn. "Bíbélì jẹ nípa Jésù. Àsírí làti gbé fún Ọlọ́run ni "Kríṣtí nínú nyìn." Ó mú wa láti inú nípasẹ agbára Ẹmí Mímọ́.Ohun gbogbo dá lórí Jésù. Nítorínà ni ẹsẹ 28, Paulu sọ pé,
"Òun ni ẹni tí à ń kéde, tí a ń gbani níyànjú, tí o sì ń kọ́ gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ọgbọ́n gbogbo..."
Ẹ̀kọ́ ṣe pàtàkì nítorí pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Bákannáà ẹ̀kọ́ Bíbélì tó dára ún kéde Jésù. Oó mọ ẹkọ tó dára bì kókó inú rẹ bá jẹ Jésù tí ìpìlẹ rẹ sì jẹ́ Ọ̀rọ̀ náà.
Lẹ́yìn náà ní orí 2, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé àfojúsùn eko naa
"Àfojúsùn mi ni pé kí wọ́n ní ìṣírí ní ọkàn, kí wọ́n sì ṣọ̀kan nínú ìfẹ́, kí wọ́n lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ọrọ̀ òye. Kí wọ́n lè mọ àṣírí Ọlọ́run, èyíinì ni, Kristi.”
Wò Pọ́ọ̀lù fẹ kí o lóye Bìbéli, nítorì nígbàtí o bá lóye ìwọ yóò mọ Jéṣù. Ní báyìí Bíbélì tún kún fún ọgbọ́n àti ìmọ̀, àmọ́ ẹsẹ 3 rán wa létí pé “gbogbo ìṣúra ọgbọ́n àti ìmọ̀” wà nínú Jésù
Nítorinà báwo ni a ṣe le dúró lóri ọnà tí o tọ? Báwo ni a ṣe ríi dájú pè a ń tẹlé Jéṣù? Ká Bíbélì kí o sì fetí sí ẹ̀kọ́ Bíbélì dáadáa.
Dí ẹ̀ nínú won ni èyí àwọn ìṣesí àìmáṣe láti tẹlé Jésù. Àkọ́kọ́ jẹ́ ìṣesí tó ní àlàáfíà nínú Bibeli lorelokore. kíka Bíbélì kìí ṣe ìgbésẹ ṣí Ọ̀run, bẹ́ẹ̀ni kìí ṣe ọ̀nà tí yóò jẹ́ kí Ó nífẹ rẹ dí ẹ̀ síi. Ó tí nífẹ rẹ d'ójú ààlà. Ṣùgbọn yiò fà ọ sún mọ́ ìfẹ yẹn, yóò sì si ràn ọ́ lọ́wọ́ làti lòye rẹ̀ àti kí o rìn nínú rẹ̀. Kì í ṣe ohun à ń gbèrò láti ṣe, ó jẹ́ ohun àá ṣe yọrí. Rántí, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ irùgbín - ó ń gbin igbésí ayé sínú ọkàn rẹ. Nítorínàà máa gbin dí ẹ̀ lójoojúmọ́!
Báwo ni a ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìṣesí Bíbélì? Tí o bá wà lórí ètò yìí, o tí wà lẹ́nu rẹ̀ nìyẹn! Torí náà, wá àkókò dí ẹ̀ síi lójoojúmọ́ láti ka Bíbélì kó o sì máa gbàdúrà. Bákannáà, ka Kólóssè báyìí, a ó sì pàdé ní orí 2.
Wo báyìí? Ìṣesí bẹrẹ nìyẹn. Kò nira rárá.
Fún Àṣàrò ati Ìjíròrò
- Ipa wo ni àwọn àṣà kó nínú ìgbésí ayé rẹ? Kí lo rí gẹ́gẹ́ bí àṣà tó jẹ́ àìmáṣe láti tẹ̀ lé Jésù?
- Oníwàásù Christ, sọ pé, “Bíbélì jẹ́ kí á rìn nínú òtítọ́ àtí láti tẹ̀lé Jésù tòótọ́.” Báwo lo ṣe rò pé Bíbélì kíkà ṣe bẹ́ẹ̀?
- Kíni ìrírí rẹ pẹ̀lú kíka Bíbélì? Ṣalábàápín ìtàn rẹ.
Ìwé mímọ́
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More