Kol 1:19-29

Kol 1:19-29 YBCV

Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀; Ati nipasẹ rẹ̀ lati bá ohun gbogbo lajà, lẹhin ti o ti fi ẹjẹ agbelebu rẹ̀ pari ija; mo ni, nipasẹ rẹ̀, nwọn iba ṣe ohun ti mbẹ li aiye, tabi ohun ti mbẹ li ọrun. Ati ẹnyin ti o ti jẹ alejò ati ọtá rí li ọkàn nyin ni iṣẹ buburu nyin, ẹnyin li o si ti bá laja nisisiyi, Ninu ara rẹ̀ nipa ikú, lati mu nyin wá iwaju rẹ̀ ni mimọ́ ati ailabawọn ati ainibawi; Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun. Nisisiyi emi nyọ̀ ninu ìya mi nitori nyin, emi si nmu ipọnju Kristi ti o kù lẹhin kún li ara mi, nitori ara rẹ̀, ti iṣe ìjọ: Eyiti a fi emi ṣe iranṣẹ fun, gẹgẹ bi iṣẹ iriju Ọlọrun ti a fifun mi fun nyin lati mu ọ̀rọ Ọlọrun ṣẹ; Ani ohun ijinlẹ ti o ti farasin lati aiyeraiye ati lati irandiran, ṣugbọn ti a ti fihàn nisisiyi fun awọn enia mimọ́ rẹ̀: Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ̀ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi hàn fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo: Ẹniti awa nwasu rẹ̀ ti a nkìlọ fun olukuluku enia, ti a si nkọ́ olukuluku enia ninu ọgbọ́n gbogbo; ki a le mu olukuluku enia wá ni ìwa pipé ninu Kristi Jesu: Eyiti emi nṣe lãlã ti mo si njijakadi fun pẹlu, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, ti nfi agbara ṣiṣẹ gidigidi ninu mi.