Kol 1:19-29
Kol 1:19-29 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori didun inu Baba ni pe ki ẹkún gbogbo le mã gbé inu rẹ̀; Ati nipasẹ rẹ̀ lati bá ohun gbogbo lajà, lẹhin ti o ti fi ẹjẹ agbelebu rẹ̀ pari ija; mo ni, nipasẹ rẹ̀, nwọn iba ṣe ohun ti mbẹ li aiye, tabi ohun ti mbẹ li ọrun. Ati ẹnyin ti o ti jẹ alejò ati ọtá rí li ọkàn nyin ni iṣẹ buburu nyin, ẹnyin li o si ti bá laja nisisiyi, Ninu ara rẹ̀ nipa ikú, lati mu nyin wá iwaju rẹ̀ ni mimọ́ ati ailabawọn ati ainibawi; Bi ẹnyin ba duro ninu igbagbọ́, ti ẹ fẹsẹmulẹ ti ẹ si duro ṣinṣin, ti ẹ kò si yẹsẹ kuro ninu ireti ihinrere ti ẹnyin ti gbọ́, eyiti a si ti wasu rẹ̀ ninu gbogbo ẹda ti mbẹ labẹ ọrun, eyiti a fi emi Paulu ṣe iranṣẹ fun. Nisisiyi emi nyọ̀ ninu ìya mi nitori nyin, emi si nmu ipọnju Kristi ti o kù lẹhin kún li ara mi, nitori ara rẹ̀, ti iṣe ìjọ: Eyiti a fi emi ṣe iranṣẹ fun, gẹgẹ bi iṣẹ iriju Ọlọrun ti a fifun mi fun nyin lati mu ọ̀rọ Ọlọrun ṣẹ; Ani ohun ijinlẹ ti o ti farasin lati aiyeraiye ati lati irandiran, ṣugbọn ti a ti fihàn nisisiyi fun awọn enia mimọ́ rẹ̀: Awọn ẹniti Ọlọrun fẹ lati fi ọrọ̀ ohun ijinlẹ yi larin awọn Keferi hàn fun, ti iṣe Kristi ninu nyin, ireti ogo: Ẹniti awa nwasu rẹ̀ ti a nkìlọ fun olukuluku enia, ti a si nkọ́ olukuluku enia ninu ọgbọ́n gbogbo; ki a le mu olukuluku enia wá ni ìwa pipé ninu Kristi Jesu: Eyiti emi nṣe lãlã ti mo si njijakadi fun pẹlu, gẹgẹ bi iṣẹ agbara rẹ̀, ti nfi agbara ṣiṣẹ gidigidi ninu mi.
Kol 1:19-29 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí ó wu Ọlọrun pé kí ohun tí Ọlọrun tìkararẹ̀ jẹ́ máa gbé inú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Nípa rẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbogbo nǹkan lọ́kan pẹlu ara rẹ̀, kí alaafia lè dé nípa ikú rẹ̀ lórí agbelebu. Gbogbo nǹkan wá wà ní ìṣọ̀kan, ìbáà ṣe nǹkan ti ayé tabi àwọn nǹkan ti ọ̀run. Ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ àlejò ati ọ̀tá ninu ọkàn yín nípa iṣẹ́ burúkú yín ni Ọlọrun wá mú wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara rẹ̀ nípa ikú ọmọ rẹ̀, kí ó lè sọ yín di ẹni tí ó mọ́, tí kò ní àbùkù, tí kò sì ní ẹ̀sùn níwájú rẹ̀, tí ẹ bá dúró ninu igbagbọ, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ dúró gbọningbọnin, tí ẹ kò kúrò ninu ìrètí ìyìn rere tí ẹ ti gbọ́, tí èmi Paulu jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, tí a ti waasu rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ayé. Ní àkókò yìí, mo láyọ̀ ninu ìyà tí mò ń jẹ nítorí yín. Ìyà tí mò ń jẹ ninu ara mi yìí ni èyí tí ó kù tí Kristi ìbá jẹ fún ìjọ, tíí ṣe ara rẹ̀. Nítorí èyí ni mo ṣe di iranṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ọlọrun ti fún mi láti ṣe nítorí yín. Ìjìnlẹ̀ àṣírí nìyí, ó ti wà ní ìpamọ́ láti ìgbà àtijọ́ ati láti ìrandíran, ṣugbọn Ọlọrun fihan àwọn eniyan rẹ̀ ní àkókò yìí. Àwọn ni ó wu Ọlọrun pé kí wọ́n mọ ọlá ati ògo àṣírí yìí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Àṣírí náà ni pé, Kristi tí ó ń gbé inú yín ni ìrètí ògo. Kristi yìí ni à ń kéde fun yín, tí à ń kìlọ̀ rẹ̀ fún gbogbo eniyan, tí a fi ń kọ́ gbogbo eniyan ní gbogbo ọgbọ́n, kí á lè sọ gbogbo eniyan di pípé ninu Kristi. Ohun tí mò ń ṣiṣẹ́ fún nìyí gẹ́gẹ́ bí agbára tí Ọlọrun fún mi, tí ó ń fún mi ní okun.
Kol 1:19-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú. Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi, bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìhìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún. Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ. Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fi fún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ. Ó ti pa àṣírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́. Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fihàn láàrín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín. Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kristi. Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń ṣiṣẹ́ nínú mi.