Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Mark 16 & Luke 24 | Àjínde
Ẹkáàbọ̀ ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mì. Òní jẹ́ eléyì tí ó ṣe kókó. A kúrò níbi àgbélèbú. A ti ṣe àrídájú wípé Jésù ti kú, wọ́n wé nínú aṣo ọ̀gbọ̀, wọ́n sì gbé sínú ibojì. Wọ́n yí òkúta ńlá kan láti fi bo iwájú ibojì, wọ́n sì fi ẹ̀sọ́ Róòmù kan ṣọ́. Ọjọ́ kan kọjá. Ọjọ́ kejì kọjá. Àwọn júù ṣe ìsinmi Sábáatì, a sìbẹ̀rẹ̀ ní àárọ̀ kùtù lọ́jọ́ àìkú.
Ìwé Máàkù ẹṣẹ 16 bẹ̀rẹ̀ ìtàn yí ní yíyọ òòrùn. Àwọn obìnrin lẹ́yìn Jésù mú tùràrí lọ sí ibi ibòji láti fi bu ọlá fún òkú rẹ
“Sùgbọ́n nígbàtí wọ́n wo òkè, wọ́n rí wípé a ti yí òkúta tí ó tóbi yì kúrò ní ẹnu ibojì, Bí wọ́n ṣe wọ inú ibojì, wọ́n ri ọkùnrin kan tí ó wọ aṣọ funfun tí ó sì jókò sí apá ọ̀tún, ẹ̀rù sí bà wọ́n. ‘Ẹ máṣe bẹ̀rù, ó wí fún wọn’. ‘È̩ ńwá Jésù ti Názárẹ́tì, tí wọ́n kàn mọ́ àgbélèbú. Ó ti jíndè! Kò sí níhìń. Ẹwo ibi tí wọ́n tẹ́ sí. Ṣùgbọ́ ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ àti Pétérù, ‘Ó tí ń lọ ṣaájú yin sí Gálílèe. Níbẹ̀ ni ẹ̀yin yíò ti rí, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún yín. ’”Ẹsẹ 8 sọ fún wa wípé àwọn obìnrin yìí, “ wà ní ìwárìrì àti ìdàrúdàpọ̀.” Èyí kìí ṣe àwàdà. Wọ́n rò pé òkú làwọn ó bà nípẹ̀ ṣùgbọ́n wọ́n rí áńgẹ́lì tí ó wà láàyè! Áńgẹ̀lì ná sì sọ fún wọn wípé kí wọ́n lọ sọ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn Jésù. Kíni gbogbo eléyì túmọ̀ sí?
Àti pé ṣé gbogbo èyí jẹ́ ìyàlẹ́nu? Ẹ ṣẹ àkíyèsí gbólóhùn tí ó kẹ́yìn ẹṣẹ 7, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yin.” Jésù sọ nípa èyí – Ó ṣọ fún àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀ wípé òhun ní láti kú àti wípé òhun yíò jínde padà! Ṣùgbọ́n nígbà míràn a kìí fetísí àwọn òtítọ́ tí ó sòro láti gbàgbọ́. Rántí bí Pétérù ṣe gbìyànjú láti ṣọ fún Jésù wípé kí ó má ṣe. Kò yé wọn. Nítorí náà kíni ìdí tí Jésù ṣe ní láti kú?
Àwọn ìtàn ti àjínde ni a gbà nínú gbogbo àwọn ìhìnrere mẹ́rin, àti pé ònkọ̀wé kọ̀ọ̀kan pín àwọn ìsẹ̀lẹ̀ orísìrísí ti ọjọ́ yìí. Torí náà, ẹ jẹẹ́ ká lọ sí ìtàn Lúúkù láti ràn wá lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè yìí.
“Níbáyì ní ọjọ́ kanná àwọn méjì nínú wọn ńlọ sí abúlé tí à ńpè ní Émmaus, ní bíi máìlì méje sí Jerúsálèmù. Wọ́n ńbá ara wọn ṣọ̀rọ̀ nípa gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Bí wọ́n ṣe ńsọ̀rọ̀ tí wọ́n sì jíròrò nípa àwọn nkàn yìí pẹ̀lé ara wọn, Jésù fúnra rẹ̀ wá ó sì darapọ̀ mọ́ wọn wọ́n jọ ńrì lọ; ṣùgbọ́n wọn kò dáa mọ̀. Ó bèrè lọ́wọ́ wọn, “Kíni ẹ̀yin méjèèjì ńjíròrò nípa bí ẹ ṣé ńlọ?
Ìtàn tí ó tẹ̀le jẹ́ ìyàlẹ́nu. Àwọn ọmọ lẹ́yìn méjì jọ ńrìn papọ̀, wọ́n ní ìbànújẹ́ àti ìdàmú ọkàn nítorí Jésù kú. Kò yé wọn. Àlejò kan darapọ̀ mọ́ wọn – ó bèèrè ohun tí wọ́n sọ. Wọ́n sì sọ fún nípa Jésù, “wòlí, alágbára ní ọ̀rọ̀ àti ìṣe níwájú Ọlọ́run àti gbogbo ènìyàn.” Ṣùgbọ́n a kàn mọ́ àgbélébù. Ó kú. Ẹsẹ 21 ńsọ,
”Ṣùgbọ́n a ti ní ìrètí wípé òhun ni…”
A ti ní ìrètí. Ṣùgbọ́n wọ́n tún sọ nípa ìròyìn tí wọ́n gbọ́ láti ẹnù àwọn obìnrin kan tí wọ́n lọ sí ibojì. Níbàyí wọn ò mọ eléyì tí wọn ó gbàgbọ́. Ní gbogbo ìgbàyí wọn kò mọ̀ wípé Jésù ni wọ́n ńbá sọ̀rọ̀! Ní ẹsẹ 25:
”Ó sọ fún wọn, ‘Ẹ wò bí òmùgọ̀ yín ti pọ̀ tó, àti bí ẹ se lọ́ra láti gba gbogbo ohun tí àwọn wòólì ti sọ gbọ́! Ṣe kìí ṣe gbogbo ìjìyà tí ó yẹ kí Messiah là kọjá nìyí lẹ́yìn náà kí ó wọnú ògo rẹ̀?’ Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Mósè àto gbogbo àwọn Wòólì, ó ṣe àlàyé fún wọn gbogbo ohun tí a sọ̀ nínú ìwé mímọ́ nípa rẹ̀ fun wọn.”Èyí jẹ́ ohun tí ó rẹ̀wà. Jésù fún wọn ní ìròyìn láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ó sì fọ́ wẹ́lẹ́ láti inú ìwé mímọ́ láti fi hàn wọ́n – gbogbo re ńtọ́ka sí àgbélébù àti àjínde. Messiah ni láti kú. Kíni ìdí?
Ìbéèrè yì mú wa padà wá sí kókó ọ̀rọ̀ yì: Ìfẹ́. Ọlọ́run fẹ́ràn wa.
“Bí a ó sè mọ ohun tí ìfẹ́ jẹ́ nìyíi, Jésù Krístì fi ara rẹ̀ jìn fún wa” (Ìwé Jòhánù Kíní 3:16).
Jésù níláti kú nítorí ó fẹ́ràn wa. Ó kú kí á lè rí ìdáríjìn. Ìwé Róòmù sàlàyé rẹ̀ báyì:
“Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀” (Ìwé Róómù 6:23).
Èyí túmọ̀ sí wípé gbogbo ẹ̀sẹ̀ wa sí Ọlọ́run jáṣí ikú. Ó fún wa ní ìyè, a sì lò ní ìlòkulò, èrè tí ó tọ́ ni ikú. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fẹ́ràn wa. Ó fẹ́ wa tó bẹ̀ẹ̀ gẹ́ tí ó fi ọmọ Rẹ̀ kan soso sílè láti gbà àyè wa. Lórí igi àgbélèbú, Jésù – ẹni tí kò dá ẹ̀sẹ̀ rí – gba gbogbo ẹ̀sẹ̀ wa, ó san ìdíyelé ní kíkún, ó sì kú dípò wa.
Ṣùgbọ́n ikú kìí ṣe ìgbẹ̀yìn rẹ. Jésù wá láti borí ikú. Àti pé Ọlọ́run sì jíi dìde sáàyè. Àti pé agbára kan náà tí ó jí Jésù kúrò nínú òkú ni agbárà kan náà tí ó jí wa. Jésù sọ wá di ọ̀tun. Ohun àtijọ́ ti lọ, ohun titun ti dé.
Sì se àkíyèsi àsìkò. Jésù kú fún wa nígbàtí a jẹ́ elẹ́ṣẹ̀ (Ìwé Róómù 5:8) Kò dúró fún wa láti ṣe rere. Ó fẹ́ wa nígbàtí a burú jù – nígbà tí a jẹ́ ọ̀tá rẹ. Ìfẹ́ tí ó lágbára leléyì.
Ìfara ẹni jì tí ó yanilẹ́nu ni, Ìfẹ́ tí kò lákàwé – eléyì yí gbogbo ohun padà. Ìrètí lèyí, Ìrètí fún gbogo ènìyàn. Ìfẹ́ yì a máa ra ènìyàn padà. Àwọn tí mo ńsọ̀rọ̀ re fún yín – tí won fẹ́ràn pẹ̀lú ìfara enijì tí ara – wọn kò rí báyì tẹ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ tí ó mú Jésù dúró lórí igi àgbélébù àti agbára tí ó jí dìde wà láàyè tí ó si ńsiṣẹ́ lónì. Wọ́n sì rí ààyè gbámú – ó jẹ́ ohun ìyàlénu.
Báwo ni a ṣe lè gbé ìgé ayé yì lónì? Ka Lúùkù 24, hun ó sì wá bá o níbí fún Ìwé Kólóṣe.
Fún ìwòye àti ìjíròrò
- Kíni ìdí tí Jésù ṣe ní láti kú lórí igi àgbélébù?
- Ìwé Róómù 5:8 sọ wípé Ọlọ́run fi ìfẹ́ rẹ hàn sí wa nínú èyí: nígbà tí a sì jẹ́ elẹ́ṣè, Jésù kú fún wa. Kíni ìfẹ́ yì túmọ̀ sí sí ọ?
- Ìwé Róómù 8:11 sọ wípé È̩mí kan náà yí tí ó jí Jésù dìde kúrò nínú ikú yíò fún ọ ní ayé òtun. Ṣé o ti rí èrí yìí nínú ayé rẹ?
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More