Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ

Start Here | First Steps With Jesus

Ọjọ́ 13 nínú 15

Kolose 3 | A Tún-un Ṣe Ní Àwòrán Rẹ̀

Ẹ pẹ̀lẹ́ o ẹ̀ sì káàbọ̀ padà ẹ̀yin ọ̀rẹ́. A ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè kan: ṣé títẹ̀lé Jésù dá lórí ìwà tuntun ni tàbí dídi ẹni tuntun? Ṣé nípa gbígbé ayé ọ̀tọ̀ ni tàbí dídá yàtọ̀. Ọ̀nà méjèèjì náà ni ìdáhùn sí ìbéèrè wa - ṣùgbọ́n bí wọ́n bá ṣe tẹ̀lé ara wọn ṣe pàtàkì. 

Ni Kolose 2, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé títẹ̀lé Jésù kìí ṣe nípa pípa àwọn òfin kan mọ́, ìgbésí ayé tuntun ni. Gbé ohun àtijọ́ sin kí o sì gbé ohun titun wọ̀. Lónìí, ní orí 3, ó sọ fún wa bí a ti lè gbé ayé tuntun ọ̀hún. Ẹsẹ 1: 

"Nítorí náà, bí a bá ti ji yín dìde pẹlu Kristi, ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run níbi tí Kristi wà, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun. Ẹ máa lépa àwọn ohun tí ó wà lọ́run, ẹ má lépa àwọn ohun tí ó wà láyé."

Kọ́kọ́rọ́ rẹ̀ nìyí: jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ - àti ọkàn rẹ - máa wò'kè. Máa ronú nípa Jésù. Máa ronú nípa Ọ̀run. Fi gbogbo ìsúra rẹ pamọ́ síbẹ̀. Jẹ́ kí Ọ̀run jẹ́ ibi tí o ti ní ìdókòwò t'ó pọ̀ jùlọ. Nígbà tí ìrírí ayé bá gbé ọ lulẹ̀, máa rántí láti b'ojú w'òkè. Ẹsẹ 3:

"Nítorí ẹ ti kú, ẹ̀mí yín wà ní ìpamọ́ pẹlu Kristi ninu Ọlọrun."

Mo fẹ́ràn ìyẹn. "È̩mí yín wà ní ìpamọ́.” Àwọn èèyàn á máa wòye pé kí ló mú ọ wà láàyè tó bẹ́ẹ̀ - Jésù sì ni. Òun ni ayé rẹ. 

Àwọn ẹsẹ t'ó kù dá lórí nnkan kan: di òkú sí ayé rẹ àtijọ́, máa gbé nínú ayé tuntun. Ẹsẹ 5:

"Nítorí náà, ẹ pa àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀yà ara yín ti ayé run: àwọn bíi àgbèrè, ìwà èérí, ìṣekúṣe, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ati ojúkòkòrò tíí ṣe ìbọ̀rìṣà."

Ṣàkíyèsí ọ̀nà tí eléyìí fi ṣeé ṣe. Ẹni t'ó jẹ́ Krìstẹ́nì á dẹ́kun ṣíṣe nnkan tí kò dára - kìí ṣe nípa títẹ̀lé òfin, ṣúgbọ́n nípa sísọ ibi ayé wa tó fẹ́ ṣe burúku di òkú. Nítorí náà ní ẹsẹ 8:

“…ẹ pa gbogbo àwọn nǹkan wọnyi tì: ibinu, inúfùfù, ìwà burúkú, ìsọkúsọ, ọ̀rọ̀ ìtìjú."

Ó dùnún sọ pé k'á dáwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dúró ju k'á mú u ṣe lọ. Nítorí náà, mo fẹ́ dá'bàá nnkan méjì. Èkínní, fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ka Romu 6 àti 8. Kókó tó wà níbí ni kíkún fún È̩mi Mímọ́.

Èkejì, bẹ̀rẹ̀ ìwà tó p'éye ti jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹfún Ọlọ́run àti fún ẹnìkan tí o lè f'ọkàn tán. Jakọbu 5 sọ báyìí: 

“Ẹ máa jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, ẹ máa gbadura fún ara yín kí ẹ lè ní ìwòsàn." (Jakọbu 5:16). 

Ìwòsàn kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìjẹ́wọ́ àti àdúrà.

Kí á padà sí ẹsẹ 9:

"Ẹ má purọ́ fún ara yín, nígbà tí ẹ ti bọ́ ara àtijọ́ sílẹ̀ pẹlu iṣẹ́ rẹ̀, 10tí ẹ ti gbé ẹ̀dá titun wọ̀. Èyí ni ẹ̀dá tí ó túbọ̀ ń di titun siwaju ati siwaju gẹ́gẹ́ bí àwòrán ẹni tí ó dá a, tí ó ń mú kí eniyan ní ìmọ̀ Ọlọrun."

Kókó rẹ̀ nìyẹn. Gbé ara tuntun wọ̀. Di ẹni tuntun tí Ọlọ́run ń tún dá. Ọlọ́run ń tún ọ dá síwájú síi gẹ́gẹ́ bí àwòràn Rẹ̀. Ní Jenesisi 1, Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòràn ara Rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ ba jíjọra yìí jẹ́. Lẹ́hìn náà ni Jésù wá. Jésù jẹ́ àwòrán Ọlọ́run. Ó wá bí ènìyàn láti fún wa ní ayè titun kí ó tún wa ṣe nínú Rẹ̀, kí ó baà lè mú wa padà sí àwòrán tí ó yẹ́ kí á jẹ́.

Èyí ló yí gbogbo nnkan padà. Ní ẹsẹ 11, O pa ìpínyà t'ó wà láàrin wa run -àwọn ìpínyà nípa ẹ̀yà, àwọ̀, akọ n b'ábo, àti ipò tí ó máa ń sún àwọn ènìyàn láti kórìra, jẹ gàba àti gb'ógun ti'ra wọn. Galatia 3 sọ pé,

"Kò tún sí ọ̀rọ̀ pé ẹnìkan ni Juu, ẹnìkan ni Giriki mọ́, tabi pé ẹnìkan jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ọkunrin tabi obinrin. Nítorí gbogbo yín ti di ọ̀kan ninu Kristi Jesu" (Galatia 3:28).

Ọgba ni wá, a sì jẹ́ ọ̀kan nínú Krístì. A pè wá láti wà ni ìṣọ̀kan. Eléyì tí Krìstẹ̀ní ti kùnà nínú èyí ti tó gẹ́. bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí a pè wá sí nìyí. 

Pọ́ọ̀lù fi àwòrán ìgbé ayé tuntun yìí hàn wá, ẹ wọ̀... 

“… àánú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀, ìwà pẹ̀lẹ́ ati sùúrù." 

Ní ìdà míràn, máa ṣe sí àwọn ènìyàn bí Jésù ti ṣe sí wọn. Kí o sì dárí jì gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe dárí jì wá. Ju gbogbo èyí lọ - ní ìfẹ́. Láti tẹ̀lé Jésù ni láti ní ìfẹ́. 

Àlááfíà l'a pè wá sí, nítorí náà jẹ́ kí àlááfíà Jésù jọba nínú ọkàn rẹ. A pè wá sí ìsọ̀kan, nítorí náà ẹ sin ara yín pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀. O lè sàkíyèsí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ tó ń ṣ'àpèjúwe ẹ̀dá titun tí o jẹ́ jẹmọ́ bí o ti ń hùwà sí àwọn ẹlòmíràn. Ẹni ọ̀tun tí o ti dà láti inú yóò ní ipa lóri bí o ṣe ń hùwà sí àwọn ènìyàn lóde. Nítorí náà sin àwọn ènìyàn pẹ̀lú ìfẹ́. Èyí ni ìhùwàsí titun kejì rẹ: máa sin àwọn ènìyàn.

Ní ẹsẹ 18, a sọ ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú àwọn ènìyàn nílé àti níbi iṣẹ́ di tittun. Ìyàtọ̀ ọ̀tun bá ìgbéyàwó: 

"Ẹ̀yin aya, ẹ máa bọ̀wọ̀..." and "Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn..." (3:18-19). 

Ṣàkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ yìí dáradára, k'ó sì rántí ohun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà ní Galatia: akọ àti abo dọ́gba nínú Krístì. Síbẹ̀ a pe ọkọ àtí aya níjà pé kí wọ́n tẹríba kí wọ́n sì máa fi ara jìn. Ṣùgbọ́n ìtẹríba kìí ṣe nnkan kan náà pẹ̀lú ìgbọ́ràn sí. Ìtẹríba jẹ́ ìwà ìbọ̀wọ̀ fún ara ẹni láàrin àwọn tí wọ́n jẹ́ irọ̀, ìwà tí a mọ̀ọ́mọ̀ gbéwọ̀ láti ju ọwọ́ sílẹ̀ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀. Ìtẹ́ríba jẹ́ ìwà ìrẹ̀lẹ̀ eléyíì t'ó ń fi ìbọ̀wọ̀fún àti ọlá hàn. Ó jẹ́ ìpè ńlá láti òkè fún àwọn aya t'ó jẹ́ Krìstẹ́nì.

A pe ọkọ láti ní ìfẹ́ . Kìí ṣe ní ti ìmọ̀ ara, ṣùgbọ́n ní fífi ara jìn. Ìfẹ́ bíi ti Jésù, ní fífi gbogbo ayé ẹni lélẹ̀ fún aya ẹni. Ní ìdà míràn, ìyàwó á ju ọwọ́ sílẹ̀, nígbà tí ọkọ yóò fi ohun gbogbo sílẹ́. Fún àlàyé síi, ka Efesu 5 àti 1 Peteru 3.

Fún tòní, ka Kolose 3. Bẹ̀rẹ̀ àwọn ìwà tuntun - ìwa Bíbélì, ìwa jíjẹ́wọ́, ìwa sísìn - kìí ṣe láti di ẹni tuntun, ṣùgbọ́n nítorí pé o ti di ẹni tuntun. A ti tún ọ ṣe ní àwòrán Rẹ̀.

Fún Àròjinlẹ̀ àti Ìjíròrò

  • Kíini o rò pé ó túmọ̀ sí pé kí á bọ́ ẹni ti àtijọ́ kúrò kí á sì gbé tuntun wọ̀? (Ẹsẹ 9-10).
  • Àwọn ìyàtọ̀ wo lo ti ń rí nínú ayé rẹ tó fihàn pé a ti ń sọ ọ́ di tuntun ní àwòrán Ẹlẹ́dàá rẹ? (Ẹsẹ 10).
  • Lónìí a ṣe àfikún àwọn ìwà méjì: ìjẹ́wọ́ àti ìsìn. Kí ló mú wọn ṣe pàtàkì?

Ìwé mímọ́

Ọjọ́ 12Ọjọ́ 14

Nípa Ìpèsè yìí

Start Here | First Steps With Jesus

Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Through The Word fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://throughtheword.org