Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ
Máàkù 12-13 | Nítorí Ìfẹ́ Ọlọ́run
Ẹ káàbọ̀ padà, gbogbo ènìyàn. Lónìí a mú kókó ọ̀rọ̀ méjì to keyin si ara won: ẹ̀sìn àgàbàgebè àti ìfẹ́ àìnígbèdéke. Ìyàtọ̀ tó wà láàrin méjèèjì yí ṣì wà gedegbe lónìí bíi ti àtẹ̀yìnwá. Àgàbàgebè máa ń lẹ́ni jìnà sí ẹ̀sìn pẹ̀lú ìkórìíra - síbẹ̀ ìfẹ́ Ọlọ́run tí kò ní gbèdéke ń pè wá padà. Ṣùgbọ́n báwo ni a ó ṣe wá ìrẹ́pọ̀ àwọn oohun tó yàtọ̀ bí èyí?
Ní agbọn yìí nínú ìwé ìhìnrere Máàkù, ìyapa yìí gan-an ló tètè mú ìtàn wa wá sí góńgó kíákíá. A ti ń tẹ̀lé ìtàn Jésù láti ọ̀sẹ̀ kan báyìí, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ọdún mẹ́ta ti kọjá, Máàkù 12 sì mú wa wá sí ọ̀sẹ̀ tó parí ìgbésí ayé Jésù. Ibi tó ti ṣẹ̀ ni Jerúsálẹ́mù, ọ̀pọ̀ ìjọ àwọn ènìyàn sì ti péjọ láti ṣe àjọyọ̀ àsè àjọ ìrékọjá.
Ìrékọjá jẹ́ ayẹyẹ, tí àwọn Júù fi ń ṣe ìrántí bí Ọlọ́run ṣe yọ wọ́n kúrò nínú oko ẹrú tó sì gbà wọ́n là lọ́wọ́ ikú nípa ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ àgùntàn. Ní báyìí, mọ̀ pé gbogbo ìlú ní ó tí kún bámú fún ayẹyẹ, gbogbo ènìyàn sì ń sọ̀rọ̀ nípa Jésù. Síbẹ̀ èrò ọkàn àwọn ènìyàn nípa Jésù ṣì wà ní ìyapa. Ọ̀pọ̀ wọn ni iṣẹ́ ìyanu àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ ṣe ní kàyéfì, ṣùgbọ́n inú ń bí àwọn adarí ẹ̀sìn. Wọ́n t'àbùkù ìk'àánú Jésù - òye ìfẹ́ Rẹ̀ sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
Báwo ló ṣe jẹ́ tí àwọn ènìyàn kan ṣe lè ní ìfarajọ ẹni tí ó fi ọkàn jìn fún Ọlọ́run ṣùgbọ́n síbẹ̀ wọn kò ní ìfẹ́? Wọ́n kọ́ ẹ̀kọ́ òfin Ọlọ́run, síbẹ̀ wọ́n kùnà gidigidi. Jésù pè wọ́n ní àgàbàgebè, wọ́n ń yín Ọlọ́run pẹ̀lú ẹnu wọn ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré síi (Máàkù 7:6). Nígbàtí Jésù dé ibè ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀, Ó ri pé wọn tún ti yí àkókò Ìrékọjá padà sí àǹfààní míràn láti tún gba owó lọ́wọ́ àwọn ènìyàn.
Fún èmi, yánpọnyánrin tó wà nílè yìí ṣe àkótán ọ̀gbun ìyapa tó wà nínú bí àwọn Kristẹni ti ń ṣe títí d'òní. A ya àwọn Kristẹni sọ́tọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́. Síbẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ìgbà ní a mọ̀ wá fún ìdánilẹ́jọ́, àgàbàgebè tí kò ní ìkáàánú. A wá jọ irúfẹ́ àwọn tí Jésù sọ̀rọ̀ báwí. Kò yẹ kọ́rí bẹ́ẹ̀.
Níti àwọn olórí ẹ̀sìn, Jésù tú àṣírí wòbìà àti ìgbéraga wọn síwájú àti síwájú, ní báyìí wọ́n wá ń wá ọ̀nà làti pa Á. Nínú Orí 12, wọ́n ṣe àtakò Jésù pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè. Wọ́n béèrè àṣẹ tí Jésù ní, wọ́n sì gbìyànjú láti gbé E ṣubú pẹ̀lú àrekérekè lóríi òfin Ọlọ́run. Oun tó dorí kodò nínú ọ̀rọ̀ yìí ni pé àwọn arákùnrin yìí tí wọ́n fi ara wọn jìn sí èyí tó kéré jù nínú òfin Ọlọ́run kùnà èyí tó ṣe kókó julo nínú òfin náà.
Síbẹ̀síbẹ̀, ọ̀kan wà nínú wọn tó yàtọ̀ sí àwọn yòókù. Wo ẹsẹ̀ 28:
"Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin wá ó sì gbọ́ wọn tí wọ́n ń jiyàn. Nígbàtí tí ó ríi pé Jésù fún wọn ní ìdáhùn tó dára, ó yẹ̀ẹ wò, "Nínú gbogbo Ìlànà, èwo ni ó ṣe kókó jùlọ?'"
Ìbéèrè tó yanrantí.
“‘Èyí tí ó ṣe kókó jùlọ,’ Jésù dáhùn, "nì'yí: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ’” (Máàkù 12:29-30 Byo).
Báyìí, òfin tí ó ṣe pàtàkì jùlọ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìránnilétí pé ọ̀kan ni Ọlọ́run. Bíbélì kọ́ wa wípé Baba jẹ́ Ọlọ́run, Jésù jẹ́ Ọlọ́run, bákan náà Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ Ọlọ́run. Síbẹ̀ àwọn mẹ́tèèta so ọwọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run kan. Síwájú sí àṣẹ nipé fẹ́ràn Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú ohun gbogbo! Jésù tẹ̀síwájú:
"Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.” (Máàkù 12:31 Byo).
A ṣe àkótán òfin nínú ìfẹ́. Ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa ju ìwé òfin lọ. Ìfẹ́ ni èyí: fẹ́ràn Ọlọ́run, fẹ́ràn àwọn aráyòókù. Verse 32:
“‘Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́…”
Kódà. Nínú ogunlọ́gọ̀ àwọn àgàbàgebè, ọkùnrin kan bèèrè ojúlówó ìbéèrè, ósì pa ìdáhùn mọ́ ní oókan-àyà rẹ̀. Ó fi ìrẹ̀lẹ̀ hàn, nígbàtí Jésù sì rí òye ọkùnrin náà, Ó sọfún un, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.”
Báyìí wo ìyàtọ̀. Àwọn alágàbàgebè sọ̀rọ̀ nípa òfin pẹ̀lú ọkàn wọn jìnà sí Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ọkùnrin yí sún mọ́ ìjọba Ọlọ́run nígbàtí tí òye yée síi pé ìfẹ́ ni ọkàn òfin. Fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn aráyòókù.
Ìfẹ́ tí Jésù pè wá sí jẹ́ ti ìyípadà. Ká fẹ́ràn aládùúgbò, Ká fẹ́ràn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, Ká fẹ́ràn àwọn ọ̀tá wa. Ìfẹ́ tí kòní gbèdéke- pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́ tí kò ṣe é túmọ̀ ati àánú tó kún àkúnwọ́sílẹ̀. Iṣẹ́ wa tó dára jù lọ fún Ọlọ́run kò jẹ́ ohùn kankan ó sì jẹ́ òfìfo tí a kò bá ní ìfẹ́ (1 Kọ́ríńtì 13:1-3).
Níbí yìí a rí agbọn míràn nínú ìtàn Krìstẹ́nì. Àwọn ènìyàn tí kò fi ti ìdájọ́ ṣe, bíkòṣe ìkáàánú. Tí wọ́n ń ṣe onígbọ̀wọ́ àwọn iṣẹ́ àrà, ìṣe ìfẹ́ t'óní ìfarajì oun gbogbo tí a lè rò lọ - ṣiṣẹ́ ìtọ́jú àwọn aláìní bàbá àti àwọn opó, fún àwọn tó gbẹ̀yìn àti àwọn tí a kò kà sí àti àwọn tí a tẹ̀ mọ́ lè - láì bìkítà ìran tàbí ìgbàgbọ́ tàbí ẹ̀sìn tàbí ìṣẹ̀dá tàbí ìfẹ́ ara tàbí ohunkóhun. Wọ́n fi ayé wọn sílẹ̀. Àwọn ènìyàn yí yà mí lẹ́nu. Wọ́n kàn… ní ìfẹ́.
Mo gbàdúrà pé o ò ní ìbùkún láti mọ̀ nínú àwọn ènìyàn náà. Mo tún gbàdúrà síi pé àwa náà yóò jẹ́ àwọn ènìyàn yẹn. Níbo ní ayé yìí ni a tún ti fẹ́ kọ́ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀? Tẹ̀síwájú láti máa tẹlé Jésù, a ó ṣàwárí ẹ̀ láì pẹ́.
Fún Àṣàrò àti Ìjíròrò
- Àwọn òfin wo ni Jésù pè ní méjì tó ṣe pàtàkì jùlọ? (v. 29-31). Kíni ìdí ẹ̀ tí o fi rò pé méjì yí ṣe pàtàkì?
- Ǹjẹ́ o ti pàdé àwọn tí ó fiyè sí òfin Ọlọ́run síbẹ̀ wọ́n pàdánù ọkàn ìfẹ́ Ọlọ́run? Báwo lo ṣe rò pé irú èyí ṣe ṣẹlẹ̀?
- Ǹjẹ́ o mọ ẹnìkan tí ó mọ ìfẹ́ Ọlọ́run tí kò ní gbèdéke ni tòótọ́ àti ní ọ̀nà tó ṣe é fojú rí? Pín ìtàn wọn.
Nípa Ìpèsè yìí
Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!
More