Bẹ̀rẹ̀ Níbí | Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Pẹ̀lú JésùÀpẹrẹ

Start Here | First Steps With Jesus

Ọjọ́ 6 nínú 15

Mark 10-11 | Iyè Àìnípẹ̀kun

Lónìí ọ̀dọ́mokùnrin kan bi Jésù ní ìbéèrè ńlá. Maaku 10, ẹsẹ̀ 17:

"Bí Jésù ti ń lọ, ọkùnrin kan sáré lọ bá a, ó sì wólẹ̀ níwájú Rẹ̀. ‘Olùkọ́ rere,’ ni ó béèrè, ‘kíni èmi gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?’”

Èyí jẹ́ ìbèérè ńlá. Bíbélì kọ́ wa pé ohun tí a bá ń ṣe nínú ìgbésí ayé kúkúrú yìí ló ń pinnu bí a ṣe lo ayérayé. Ọ̀dọ́mọkùnrin yìí sì fẹ́ mọ - kíni èmí gbọ́dọ̀ ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun? Báwo ni mo ṣe lè dé ọ̀run?

Nítorínà ó béèrè lọ́wọ́ olùkọ́ rere. Wò bí Jésù ṣe fún ní èsì. Ẹsẹ̀ 18:

" Kíni ìdí tí o fi pè mí ní rere?" Jésù dáhùn. “Kò sí ẹni rere àfi Ọlọ́run nìkan."

Ṣàkíyèsí wípé Jésù ò kàn dáhùn ìbèérè yì tààrà. Kílódé? Ìdí ni pé ó fẹ́ mú ohun tí ọkùnrin náà gbà gbọ́ tẹ́lẹ̀ kúrò kí ó tó fún ní ìtọ́sọ́nà òótọ́. Nítorínà Jésù sọ fún wípé, “Kò sí ẹni rere àfi Ọlọ́run.” È̩yí ṣe pàtàkì.

A máá ńfẹ́ pín ayé sọ́tọ̀ láàrín àwọn ènìyàn rere àti búburú. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ fún wa pé gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, kò sì sí ẹnì kan tí ó jẹ́ olódòdo lẹ́yìn Ọlọ́run fúnra Rẹ̀ (Ìwé Róòmù 3:23). Òdodo túmọ̀ sí títọ́ pẹlú Ọlọ́run, àti nínú Májẹ̀mú Àtijó, ọ̀nà kan soso sí iyè àìnípẹ̀kun ni òdodo (Ìwé Òwe 12:28).

Sì wo ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀. Ẹsẹ̀ 19:

”Ó mọ àwọn òfin…”

Ó sì ṣe àkópọ̀ rẹ̀ pé: Máṣe pànìyàn, má ṣe panṣágà, má ṣe jalè, tàbí jẹ́rìí èké, bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí. O lè dá àwọn wọ̀nyí mọ̀ láti àwọn Òfin Méwá. Ẹsẹ̀ 20:

"Olùkọ́,” ó sọ pé, “Gbogbo ìwọ̀nyí ni mo ti pa mọ́ láti ìgbà èwe mí."

Ní kedere arákùnrin yì ròpé òhun dára. Ó yé mi. Nígbàtí mi ò tíì mọ Jésù, mo lérò pé ènìyàn dáradára ni mí. Mo gbìyànjú láti má ṣe ìpalára fún ẹnikẹni, mo sì jẹ́ ọmọkùnrin kan tó dára.

Àmọ́ kíyè sí ohùn tí Jéṣù yọ ṣílẹ̀. Ó ṣe àtòkọ àwọn àṣẹ nípa ìfẹ sí àwọn ẹlọ̀míràn, ṣùgbọn kò mẹ́nu ba àwọn òfin nípa Ọlọrun: “Ìwọ kò gbọdọ ní àwọn ọlọrun míràn” àti “Ìwọ kò gbọdọ ṣe òrìṣà” dípò Ọlọrun. Kínì dí tó fi fo àwọn yẹn? Ẹsẹ̀ 21:

"Jésù wò ó sì fẹ́ràn rẹ̀.”

Dúró báyẹn. Ní ti Jésù, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yìí ju ti ìbéèrè àti ìdáhùn ẹ̀kọ́ ìmọ-jìnlẹ nípa Ọlọ́run lọ. Jéṣù fẹ́ràn rẹ̀. Ó sì sọ fún:

"Ohun kan tí ó kù,“ ó wípé. "Lọ, ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì fi fún àwọn tálákà, bẹ́ẹ̀ni ìwọ yóò ní ìṣura ní ọrun: kí o sì wá, tẹlé mi."

Ó jẹ́ Ìyánu. Ohun kan soso ní ó ṣe àìní láti ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ohun kan soso. Sùgbọ́n farabalẹ̀ kàá – Kíni ohun kan soso? Ṣé kí á fún àwọn aláìní ní gbogbo nkan ìní wa ni? Èmi ò rò bẹ́ẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kẹ́hìn gbólóhùn yí ni – àwọn ọ̀rọ̀ méjì yì: “Tẹ̀lé mi.”

Ọ̀nà kan soso ní ó wà láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun: tẹ̀lé Jésù. Ìwé Róómù Orí 3 sọ fún wa pé

" Kò sí ẹnikẹ́ni tí a óo polongo ní olódodo níwájú Ọlọrun nípa iṣẹ́ òfín” (Ìwé Róómù 3:20).

Èyí túmọ̀ sí wípé isẹ́ rere kò tó

”(Ṣùgbọ́n) òdodo ní a fi fún gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ nípasẹ ìgbàgbọ nínú Jésù Krístì” (Ìwé Róómù 3:22).

Ní ọ̀rọ̀ míràn, Jésù mú wa tọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run nígbàtí a bá tẹ̀lé pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Ó mú ẹ̀sẹ̀ wa sí orí igi àgbélèbú ó sì fún wa ní òdodo (2 Kọ́ríntì 5:21).

Kí wá ni ìdí tí Jésù ṣe sọ fún arákùnrin náà kí ó ta gbogbo ohun ìní re? Ìwọ wo ìṣeṣí rẹ̀:

"Látàrí èyí ọkùnrin náà ba ojú jẹ́. Ó lọ kúrọ̀ níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ tí ó pọ̀” (Máákù 10:22).

Nítorí ná ó jẹ́ Ọlọ́rọ̀. Ìsesí rẹ ló jẹ́ kí á mọ̀. Ó ba inú jẹ́ nítorí ó fẹ́ràn ọrọ̀ rẹ. Owó kìí se ohun tí kò dára, ṣùgbọ́n ìfẹ́ owó jẹ́ ohun tí ó léwu. Ọrọ̀ le tètè di ohun tí ènìyàn á bẹ̀rẹ̀ sí ní bọ – tí yíò wá dípò Ọlọ́run. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù ré àwọn àṣẹ àkọ́kọ́ kọjá láti fi hàn pé òun náà ń ṣe bẹ́ẹ̀, Lẹ́ẹ̀kan sí ó dàbí èmi. Mo rò pé mo dára, ṣùgbọ́n ìgbéraga ni mo fi dípò Ọlọ́run. Fún arákùnrin yìí, Owó jẹ́ ohun tí ó ńsìn. Nítorí nàà Jésù ṣo fún: Jẹ́ kí a kọ́kọ́ mú ohun tí ó dá ọdúró láti sin Ọlọ́run kúrò, lẹ́yìn ná tẹ̀lé mi.

Sì wo ọ̀rọ̀ tí ó wá láti ẹnu Jésù. Ó se àpèjúwe ọ̀run ní “wíwọ ìjọba Ọlọ́run.” Èyí yí nkan padà. Bí ọ̀run bá kàn jẹ́ ibi tí ó dára, nígbàná ni àti wọ ọ̀run yíò nílò kí á jẹ́ ẹni tó ó dára; ṣùgbọ́n ọ̀run jẹ́ ìjọba Ọlọ́run, nígbàná àti wọ̀ ó nílò kí á tọ́ pẹ̀lú Ọba ibẹ̀.

Jésù ni Ọba, àti wípé ọ̀nà kan soso sí ìjọba Ọlọ́run ni kí á tẹ̀lé Jésù. Ó dára, òhun nìkan ni ó sì lè jẹ́ kí á jẹ́ olódodo. Ṣùgbọ́n ìwọ kò lè tẹ̀lé Jésù àfi tí o bá fi àwọn nkan tó ó ńdí ọ lọ́wọ́ ṣílẹ̀. Ìwọ kò lè sin Ọlọ́run méjì, o kò sì lè tẹ̀lé ìtọ́ṣọ̀nà méjì.

Nítorí náà kíni ó sẹlẹ̀ ṣí arákùnrin yìí? Ṣé ó tẹ̀lé Jésù, tàbí ó jèrè ayé ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀? A kò mọ̀. Sùgbọ́n mo mọ̀ pé àsìkò sì wà fún ọ.

Mò ńrò bí Jésù yó se dáhùn tí ìwọ bá bi léèrè àwọn ìbéèrè kanná. Ohun tí à ńsìn yíò yàtọ̀: Owó, ìgbádùn, òògùn olóró, àseyọrí, ìgbéraga, ìfẹ́kúfẹ̀. Láti mọ ohun tí ìwọ́ ńsìn, bi ara rẹ léèrè: Nígbàtí Jésù sọ wípé “Tẹ̀lé mi,” kíni ó ń dí ọ lọ́wọ́?

Ka Máákù 10, kí o sì ro ohun tí ó yẹ kí o mú kúrò kí o lè tẹ̀lé.

Fún Àṣàrò àti Ìjíròrò:

  • Èwo nínú ìdáhùn Jésù ni ó jẹ́ ìdáhùn sí ìbéèrè arákùnrin yìí? (Ka 10:17 àti 10:21).
  • Kíni ìdí tí Jésù se sọ wípé ó sòro fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run?(Ka 10:25).
  • Nígbàtí Jésù bá pè ọ́ láti tẹ̀lé, kíni àwọn ohun tí ó ń dí ọ lọ́wọ́? Pín nínú ìrírí rẹ.

Ìwé mímọ́

Day 5Day 7

Nípa Ìpèsè yìí

Start Here | First Steps With Jesus

Bí o bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Jésù, tí Bíbélì ṣe àjòjì sí ọ tàbí ò ń ran ọ̀rẹ́ kan lọ́wọ́ tí èyí rí bẹ́ẹ̀ fún - Bẹ̀rẹ̀ Níbí. Fún bíi ọjọ́ mẹ́ẹ̀dógún, àkásílẹ̀ ohùn oníṣẹ́jú márùn-ún yìí yíó tọ́ ọ ní ṣísẹ̀-ǹ-tẹ̀lé la àwọn ìwé ìpìlẹ̀ Bíbélì méjì kọjá: Máàkù àti Kólósè. Tọ ìtàn Jésù kí o sì ṣ'àwárí ìlànà tí a fi ń tẹ̀lée, pẹ̀lú ìbéèrè ojoojúmọ́ fún àṣàrò ẹnìkọ̀ọ̀kan tàbí ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́. Tẹ̀lẹ́ wa lẹ́ẹkan láti bẹ̀rẹ̀, lẹ́hîn náà pe ọ̀rẹ́ kan kí o tún kálọ lẹ́ẹ̀kansii!

More

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Through The Word fún ìpèsè ètò yíi. Fún àlàyé síi, jọ̀wọ́ kàn sí: http://throughtheword.org